settings icon
share icon
Ibeere

Kínni ìdàgbà ti ẹ̀mí?

Idahun


Ìdàgbà ti ẹ̀mí ní ọ̀nà láti dàábi Jésù Kristi síwájú àti síwájú síi. Nígbàtí a fi ìgbàgbọ́ wa sínú Jésù, Ẹ̀mí Mímọ́ bẹ̀rẹ̀ ọ̀nà láti jẹ́ kí àwa kí ó dàábi Òun, kí àwa kí ó di àwòrán Rẹ̀. Ìdàgbà ti ẹ̀mí ni a ṣe àpèjúwe ní ọ̀nà tí ó dára jùlọ ní Peteru keji 1:3-8, èyí tí ó sọ fún wa wípe nípa agbára ti Ọlọ́run àwa ní "ohun gbogbo tí àwa nílò" láti gbé ìgbe-ayé ìwà-bí-Ọlọ́run, èyítí ó jẹ́ ìlépa ìdàgbà ti ẹ̀mí. Kíyèsi wípé ohun tí àwa nílò wá "nípasẹ̀ ìmọ̀ wa nínú Òun," èyí tí ó jẹ́ kókó láti gba ohun gbogbo tí a nílò. Ìmọ̀ wa nínú Òun wá láti inú Ọ̀rọ̀ Rẹ̀, èyítí a fi fún ìmúgbèrú àti ìdàgbà wa.

Àkójọpọ̀ méji ni o wà ní Galatia 5:19-23. Àwọn ẹsẹ̀ 19-21 ṣe àkójọ "àwọn iṣẹ́ ti ara." Àwọn nǹkan wọ̀nyìí ni a mọ̀ mọ́ ayé wa ṣáájú wíwá wa sí ọ̀dọ̀ Jésù fún ìgbàlà. Àwọn iṣẹ́ ti ara ni àwa nílò láti jẹ́wọ́, ronúpìwàdà nípa rẹ̀, kí a sì, pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Ọlọ́run, borí. Bí àwa ṣe ńni ìrírí ìdàgbà ẹ̀mí, díẹ̀ àti díẹ̀ "àwọn iṣẹ́ ti ara" ni yóò farahàn nńú ayé wa. Àkójọ kejì ni "eso ti Ẹ̀mí" (àwọn ẹsẹ̀ 22-23). Àwọn nǹkan wọ̀nyìí ni ó yẹ kí ó kún ayé wa nísìnyí tí àwa ti ní ìrírí ìgbàlà nínú Jésù Kristi. Ìdàgbà ti ẹ̀mí ni atọ́kasí nípa èso ti Ẹ̀mí tí ìrí rẹ̀ ńpọ̀si nínú ayé ti àwọn onígbàgbọ́.

Nígbàtí àyípadà ti ìgbàlà bá ti wáyé, ìdàgbà ti ẹ̀mí ti bẹ̀rẹ̀. Ẹ̀mí Mímọ́ ńgbé nínú wa (Johannu 14:16-17). Àwa jẹ́ ẹ̀dá titun nínú Kristi (2 Kọrinti 5:17). Àbùdá àtijọ, ẹ̀ṣẹ̀ yóò bẹ̀rẹ̀ sí ní fi ààyè sílẹ̀ fún àbùdá ti dídà bíi Kristi, titun (Romu 6-7). Ìdàgbà ti ẹ̀mí jẹ́ fún gbogbo ọjọ́-ayé ènìyàn èyí tí ó dá lé lórí ẹ̀kọ́ àti ìmúlò ti ọ̀rọ̀ Ọlọ́run wa (2 Timoteu 3:16-17) àti ìrìn wa nínú Ẹ̀mí (Galatia 5:16-26). Bí a ṣe ńwá ìdàgbà ti ẹ̀mí, àwa gbọ́dọ̀ gbàdúrà sí Ọlọ́run kí a sì bèrè fún ọgbọ́n nípa àwọn ìpele tí Òun fẹ́ kí àwa dàgbà nínú rẹ̀. Àwa lè bèrè kí Ọlọ́run mú ìgbàgbọ́ àti ìmọ̀ wa nínú Òun pọ̀si. Ọlọ́run ńfẹ́ kí àwa dàgbà ni ẹ̀mí, tí Òun sì ti fún wa ní ohun gbogbo tí a nílò láti ní ìrírí ìdàgbà ti ẹ̀mí. Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ ti Ẹ̀mí Mímọ́, àwa lè borí ẹ̀ṣẹ̀ kí a si máa fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ dàábi Olùgbàlà, Jésù Kristi Olúwa.

EnglishPada si oju ewe Yorùbá

Kínni ìdàgbà ti ẹ̀mí?
Pin oju-iwe yii: Facebook icon Twitter icon Pinterest icon Email icon
© Copyright Got Questions Ministries