settings icon
share icon
Ibeere

Ǹjẹ́ ìdáàbòbò ayérayé jẹ́ "ìwé-àṣẹ" láti dẹ́ṣẹ̀ bí?

Idahun


Àtakò tó gbajúgbajà jù sí ẹ̀kọ́ ìdáàbòbò ayérayé ni wípé ó ńfí àyè gba àwọn ènìyàn láti gbé ìgbe ayé tí ó wù wọ́n, kí wọ́n sì tún jẹ́ ẹni ìgbàlà. Nígbàtí èyí le "fẹ́ fi ara pẹ́" òtítọ́, kìí ṣe òtítọ́ dájúdájú. Ẹni tí Jésù Kristi bá ti ràpadà ní òtítọ́ kò ní máa gbé ìgbé ayé ẹ̀ṣẹ̀ àmọ̀ọ́mọ̀ dá lemọ́lemọ́. A gbọ́dọ̀ fi ìyàtọ̀ hàn gedegbe láàrin bí Kristiẹni ṣe gbọ́dọ̀ gbé ìgbé ayé rẹ̀ àti ohun tí ènìyàn gbọ́dọ̀ ṣe láti le gba ìgbàlà.

Bíbélì fihàn kedere wípé ìgbàlà wá nípa ore-ọ̀fẹ́ nìkan, nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ nìkan, nínú Jésù Kristi nìkan (Johannu 3:16; Efesu 2:8-9; Johannu 14:6). Lọ́gán tí ènìyàn bá gba Jésù Kristi gbọ́ ní tòótọ́, òun ti di ẹni ìgbàlà, ó sì ní ààbò nínú ìgbàlà náà. A kò lè gba Ìgbàlà nípa ìgbàgbọ́ kí áwá fi iṣẹ́ gbéeró. Àpọ́stélì Pọ́ọ̀lù s'ọ̀rọ̀ yìí nínú ìwé Galatia 3:3 nígbà tí òun bèrè "Ṣe báyìí li ẹyin ṣe aláìronú tó? Ẹ̀yin tí ó bẹ̀rẹ̀ nípa Ẹ̀mí, a ha ṣe yin pé nisisiyin nípa ti ara?". Bí a bá gbà wá là nípasẹ̀ ìgbàgbọ́, ìgbàlà wa náà ni a o tún mú dúró sinsin tí a ó si dáàbòbò nípasẹ̀ ìgbàgbọ́. A kò lè gba ara wa là. Fún ìdí èyí, àwa kò ní ipa láti pa ìgbàlà wa mọ́. Ọlọ́run ni ó ńpa ìgbàlà wa mọ́ (Juda 24). Ọwọ́ Ọlọ́run ni ó ńdìwá mú sinsin (Johannu 10:28-29). Ìfẹ́ Ọlọ́run ni wípé kí ohunkóhun má le yà wá yà kúrò ninú ifẹ́ Ọlọ́run tí ó wà ninú Kristi Jésù Olúwa wa (Romu 8:38-39).

Kíkọ ìdáàbòbò ayérayé, ní tirẹ̀, jẹ́ ìgbàgbọ́ wípé àwa yóò máa pa ìgbàlà wa mọ́ nípa iṣẹ́ rere àti akitiyan wa. Èyí ṣe lòdì pátápátá sí ìgbàlà nípa ore-ọ̀fẹ́. A gbà wá là nítorí yíyẹ Kristi, kìí ṣe nípa ti ara wa (Rómù 4:3-8). Láti jẹ́wọ́ wípé a gbọdọ̀ gbọ́ràn sí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tàbí gbé ìgbé-ayé mímọ́ láti lè pa ìgbàlà wa mọ́ ńsọ wípé ikú Jésù kò tó láti san ìjìyà fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa. Ikú Jésù kúkú tó láti san gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ wa—tí àtẹ̀yìnwá, ìsinsìnsín yìí, àti ọjọ́ iwájú, ṣáájú kí á tó gba ìgbàlà àti lẹ́yìn tí a gba ìgbàlà (Romu 5:8; 1 Kọrinti 15:3; 2 Kọrinti 5:21)

Ǹjẹ́ èyí túmọ̀ sí wípé Kristiẹni le gbé ìgbé-ayé tó bá wùú, kí ó sì tún jẹ́ ẹni ìgbàlà? Èyí jẹ́ ìbéèrè àlùfàǹsá, nítorí Bíbélì fi yé wa pé Kristiẹni tòótọ́ kò lè gbé ìgbé-ayé "bí ó bá ṣe wùú." Àwọn Kristiẹni jẹ́ ẹ̀dá tuntun (2 Kọrinti 5:17). Àwọn Kristiẹni á máa fi èso ẹ̀mí hàn (Galatia 5: 22-23, kìí ṣe iṣẹ́ ẹran ara (Galatia 5: 19-21). Ìwé Jòhánnù kínní 3;6-9 fi yé wa kedere pe Kristiẹni tòótọ́ kò ní máa gbé nínú ẹ̀ṣẹ̀ lemọ́lemọ́. Ní ìdáhùn sí àtakò pé ore-ọ̀fẹ́ fi àyè gba ẹ̀ṣẹ̀, Àpọ́stélì Pọ́ọ̀lù sọ wípé, "Ǹjẹ́ àwa o ha ti wi? Kí àwa kí ó ha jókò nínú ẹ̀ṣẹ̀, kí ore-ọ̀fẹ́ kí ó lè ma pọ̀ síi? Kí á ma ri! Àwa ẹnití o ti kú sí ẹ̀ṣẹ̀, àwa o ha ṣe wà láàyè nínú rẹ̀ mọ́?" (Romu 6:1-2).

Ìdáàbòbò ayérayé kìí ṣe òmìnira láti dẹ́ṣẹ̀. Dípò èyí, ó jẹ́ ààbò láti inú imọ̀ wípé ìfẹ̀ Ọlọ́run dájú fún àwọn tó ní ìgbẹ̀kẹ̀lé nínú Kristi. Mímọ̀ àti níní òye ẹ̀bùn ìgbàlà ńlá ṣe ìdàkejì fífi àyè gba ẹ̀ṣẹ̀. Báwo ni ẹnikẹ́ni tí ó mọ iye tí Jésù Kristi san fún wa, ṣe lè máa tẹ̀síwájú láti gbé ìgbé-ayé ẹ̀ṣẹ̀ (Romu 6:15-23)? Báwo ni ẹnikẹ́ni tí òye ìfẹ́ Ọlọ́run tí kò ní gbèdéke tí ó sì dájú fún àwọn tí ó gbàgbọ́ bá yé, yóò ṣe tún máa fi ojú Ọlọ́run gún igi? Irú ènìyàn bẹ́ẹ̀ kò fi fífún ìdáàbòbò ayérayé ní òmìnira láti dẹ́ṣẹ̀ hàn, sùgbọ́n ó fihàn wípé kò tíì ní ìrírí ìgbàlà nípa Jésù Kríístì. "Ẹnikẹni tí ó bá ńgbé inú rẹ̀, ki i dẹ́ṣẹ̀. Ẹnití ó bá ńdẹ́ṣẹ̀ kò rí i, kò mọ̀ ọ (1 Johannu 3:6).

English



Pada si oju ewe Yorùbá

Ǹjẹ́ ìdáàbòbò ayérayé jẹ́ "ìwé-àṣẹ" láti dẹ́ṣẹ̀ bí?
Pin oju-iwe yii: Facebook icon Twitter icon Pinterest icon Email icon
© Copyright Got Questions Ministries