settings icon
share icon
Ibeere

Kílódé tí Ìbí Wúndíá ṣe ṣe pàtàkì?

Idahun


Ẹ̀kọ́ ìbí wúndíá ṣe pàtàkì gidigidi (Isaiah 7:14; Matteu 1:23; Luku 1:27, 34). Àkọ́kọ́, ẹ jẹ́ kí á wo bí Ìwé Mímọ́ ṣe ṣ'àlàye ìṣẹ̀lẹ̀ náà. Ní ìdáhùn sí ìbéèrè Màríà, "Èyí ó ha ti ṣe rí bẹ̀?" (Luku 1;34), Gébríẹ̀lì wípé, "Ẹ̀mí Mímọ́ yíò tọ̀ ọ́ wá, àti agbára Ọ̀gá ògo yíò síji bò ọ́" (Luku 1:35). Áńgẹ́lì náà rọ Jósẹ̀fù kó máse bẹ̀rù láti fẹ́ Màríà pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyìí: "Èyí tí ó yún nínú rẹ̀, láti ọwọ́ Ẹ̀mí Mímọ́ ni" (Matteu 1:20). Mateu sọ wípé wúndíá náà "wà pẹ̀lu ọmọ nípasẹ̀ Ẹ̀mí Mímọ́" (Matteu 1:18). Galatia 4:4 náà kọ nípa ìbí wúńdíá: "Ọlọ́run rán ọmọ rẹ̀, a bí i nípasẹ̀ obìnrin."

Láti inú ẹsẹ̀ wọ̀nyìí, ó hàn dájúdájú wípé ìbí Jésù wáyé nípasẹ̀ iṣẹ́ Ẹ̀mí Mímọ́ nínú ara Màríà. Ohun àìrí (Ẹ̀mí) àti ohun rírí (inú Màríà) ló kópa. Màríà kò ṣáà lè fún ara rẹ̀ lóyún, ní èrò yìí, ó jẹ́ "ohun èlò." Ọlọ́run nìkan l'óle ṣe iṣẹ́ ìyanu Ìṣẹ̀dá.

Ẹ̀wẹ̀, kíkọ́ láti gba ìsopọ̀ ara tí ó wà láàrin Màríà àti Jésù yóò túmọ̀ sí wípé Jésù kìí ṣe ènìyàn nítòótọ́. Ìwé Mímọ́ kọ́ wa wípé Jésù jẹ́ ènìyàn, pẹ̀lu ara bíi ti àwa. Èyí ni ó gbà lọ́dọ̀ Màríà. Bákannáà, Jésù jẹ́ Ọlọ́run, pẹ̀lú ìyè ayérayé, àbùdá àìdẹ́sẹ̀ (Johannu 1:14; 1 Timoteu 3;16; Heberu 2:14-17.)

A kò bí Jésù nínú ẹ̀sẹ̀; èyí ni wípé, kò ní àbùdá ẹ̀sẹ̀ (Heberu 7:26). Yóò wá rí bíi wípé àbùdá ẹ̀ṣẹ ńti ìran kan bọ́ sí ìran míìrán nípasẹ̀ bàbá (Romu 5:12, 17. 19). Ìbí Wúńdíá dènà ìtànkálẹ̀ àbùdá ẹ̀ṣẹ̀, ó sì gba Ọlọ́run ayérayé láti di ènìyàn pípé.

English



Pada si oju ewe Yorùbá

Kílódé tí Ìbí Wúndíá ṣe ṣe pàtàkì?
Pin oju-iwe yii: Facebook icon Twitter icon Pinterest icon Email icon
© Copyright Got Questions Ministries