settings icon
share icon
Ibeere

Kínni a gba/a kò gba tọkọtaya Kristiẹni láàyé láti lè ṣe, nípa ìbálòpọ?

Idahun


Bíbélì sọ wípé "Ki igbeyawo ki o li ọla larin gbogbo èniyàn, ki àkéte si jẹ aláìléèéri: nitori awọn àgbèrè ati panṣaga li Ọlọ́run yóò dá lẹjọ" (Heberu 13:4). Ìwé Mímọ́ kò sọ ohun tí ọkọ àti ìyàwó kan lè ṣe tàbí lè máṣe nípa ìbálópọ̀. Àwọn ọkọ àti ìyàwó ní a fún ní ìtọ́ni wípé, "Ẹ maṣe fà sẹhin kuro lọdọ ara yin, bikoṣe nipa ifimọsọkan (1 Kọrinti 7:5a). Ó jọ wípé ẹsẹ yìí ńla ìlànà kalẹ̀ fún àwọn ìbáṣepọ̀ nípa ti ìbálòpọ̀ nínú ìgbeyàwó. Ohunkóhun tí a bá ṣe, gbọ́dọ̀ jẹ́ èyí tí a jìjọ fìmọ̀ sọ̀kan lé lórí papọ̀. Kò gbọ́dọ̀ sí ẹnikẹ́ni tí à ngbà níyànjú tàbí fi ipá mú láti ṣe ohun kan tí kò bá òun lára mu tàbí tí ó lérò wípé ó lòdì. Bí ọkọ àti ìyàwó bá jùmọ̀ gbà látí gbìdànwò ohun kan (fún àpẹẹrẹ, ìbálòpọ̀ fífẹnuṣe, àwọn ipò tí ó yàtọ̀, àwọn nǹkàn ìṣeré fún ìbálòpọ̀, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.), nígbànáà Bíbélì kò sọ ìdí kankan tí wọn kò lè fi ṣe.

Àwọn ohun díẹ̀ kan ńbẹ, bí ó tilẹ̀ jẹ́ wípé, tí a kò fí ààyè gbà rárá nípa ìbálòpọ̀ fún tọkọtaya kan tí ó ti ṣe ìgbéyáwò. Ìṣe bíi "pípàrọ̀" tàbí "mímú ẹlòmíràn kún ra" (ìbálòpọ̀ láàrín ẹni mẹ́ta, ìbálòpọ̀ láàrìn ẹni mẹ́rin, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.) jẹ́ panṣágá pọnbele (Galatia 5:19; Efesu 5:3; Kolosse 3:5; 1Tẹsalonika 4:3). Panságà jẹ ẹ̀ṣẹ̀, kódà bí ìyàwó tàbí ọkọ rẹ bá fi ààyé gbàá, fí ọwọ́ síi, tàbí kódà kópa nínú rẹ̀. Wíwo àwòrán ènìyàn ní ìhòhò a máa wu "ìfẹ́kúfẹ̀ tí ẹran ara àti ìfẹ́kúfẹ̀ ti ojú" (1 Johannu 2:16) nítorí náà Ọlọ́run sì tún ṣe ìdálẹ́bi rẹ̀ pẹ̀lù. Ọkọ àti ìyàwó kan kò gbọdọ̀ mú wíwo àwòrán ènìyàn ní ìhòhò wọ inú ìbálòpọ̀ wọn. Yàtọ̀ sì àwọn ohun méjì wọ̀nyìí, kò sí ohunkóhun tí Ìwé Mímọ́ dá ọkọ̀ àti ìyàwó lẹ́kun láti ṣe pẹ̀lú ara wọn nìwọ̀n ìgbà tí ó tí jẹ́ èyítí wọn jùmọ̀ fọwọ́sí.

English



Pada si oju ewe Yorùbá

Kínni a gba/a kò gba tọkọtaya Kristiẹni láàyé láti lè ṣe, nípa ìbálòpọ?
Pin oju-iwe yii: Facebook icon Twitter icon Pinterest icon Email icon
© Copyright Got Questions Ministries