settings icon
share icon
Ibeere

Kínni Bíbélì sọ nípa gbígbéni lọ sí ilé-ẹjọ́?

Idahun


Àpọ́stélì Pọ́ọ̀lù sọ fún àwọn onígbàgbọ́ ní Kọ́ríntì lati má gbé ara wọn lọ sí ilé-ẹjọ́ (1 Kọrinti 6:1-8). Ó jẹ́ ìṣubú ẹ̀mí fún Kristiẹni láti má dáríjì ara wọn àti wípé kí wọ́n má sì parí gbólóhùn asọ̀ tí ó wà láàrin wọn. Kíló lè mú ènìyàn láti fẹ́ di Kristiẹni, nígbàtí àwọn Kristiẹni bá ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìṣòro, tí wọn kò sì ní agbára láti yanjú wọn? Ṣùgbọ́n, ìgbà míìrán wà tí ó jẹ́ wípé ilé-ẹjọ́ ló yẹ láti lọ. Bí ó bá jẹ́ wípé a tẹ̀lé ìlànà Bíbélì fún ìbálàjà (Matteu 18:15-17), tí ẹni tí ó ṣẹ̀ ṣì tún ńṣe àṣìṣe síbẹ̀, nígbà míìrán lílo ilé-ẹjọ́ ṣeé dáláre. A lè ṣe èyí lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ àdúrà fún ọgbọ́n (Jakọbu 1:5), àti ìbẹ̀lọwẹ̀ àwọn adarí nínú ẹ̀mí.

Gbogbo àṣàyàn Kọrinti Kínní 6:1-6 sọ nípa ìjà nínú ìjọ, ṣùgbọ́n Pọ́ọ̀lù kò ṣe àyọkà ètò ilé-ẹjọ́, nígbàtí ó sọ nípa ìdájọ́ nípa nǹkan tí ó kan ayé yí. Ohun tí Pọ́ọ̀lù ńsọ ni wípé ilé-ẹjọ́ wà fún ọ̀ràn nípa ayé tí ó yàtọ̀ sí ti ìjọ. A kò gbọ́dọ̀ gbé ìṣòro ìjọ lọ sí ilé-ẹjọ́, ṣùgbọ́n kí á ṣe ìdájọ́ nínú ìjọ.

Ìṣe àwọn Àpọ́stélì orí 21-22 sọ nípa bí a ti mú Pọ́ọ̀lù tí wọ́n sì ro ẹ̀ṣẹ̀ tí kòdá síi lẹ́sẹ̀. Àwọn ará Romu múu, wọ́n sì " Balógun ọrún sì pàṣẹ pé kí á mú Pọ́ọ̀lù wọlé, ó pàṣẹ pé kí á nàá ní ẹgba láti jẹ́ kí ó jẹ́wọ́ ọ̀ràn rẹ̀. Òun fẹ̀ wá ìdí tí àwọn èrò ṣe ńbínú fùfù. Bí wọ́n ṣe so Pọ́ọ́lù mọ́lẹ̀ láti nàá, Pọ́ọ́lù sọ fún ọmọ ogun wípé, ó ha tọ́ fún nyín láti na ẹnití íṣe ará Rómù lí àìjẹ̀bi?" Pọ́ọ̀lù lo òfin Rómù àti jíjẹ́ ọmọ-ìlú rẹ̀ láti dáàbòbo ara rẹ̀. Kò sí ohun tí ó burú nínú lílo ètò ilé-ẹjọ́, níwọ̀n ìgbà tí a bá ṣeé pẹ̀lú èròńgbà ọkàn tí ó tọ̀nà, àti pẹ̀lú ọkàn mímọ́.

Pọ́ọ̀lù tẹ̀síwájú láti sọ wípé, "Ǹjẹ́ nísinsìnyí, àbùkù ni fún nyín pátápátá pé ẹ̀nyin nbá ara yín ṣe ẹjọ́. È éṣe tí ẹ̀nyin kò kúkú gbà ìyà? È éṣe tí ẹ̀nyin kò kúkú jẹ́ kí á rẹ́ nyin jẹ?" (1 Kọrinti 6:7). Ohun tí ó jẹ Pọ́ọ̀lù lógún níbí ni ẹ̀rí àwọn onígbàgbọ́. Yóo dára fún wa kí wọ́n rẹ́ wa jẹ, tàbí kí wọ́n ti ẹ̀ ṣe àṣìlò wa, ju bí ó ti lè rí fún wa kí á ti ènìyàn lọ síwájú jìnà kúrò lọ́dọ̀ Kristi nípa gbígbé irú ènìyàn bẹ́ẹ̀ lọ́kùnrin tàbí l'óbìnrin lọ sí ilé-ẹjọ́. Èwo ni ó ṣe pàtàkì jùlọ—ogun ti òfin tàbí ogun fún ọkàn ènìyàn ní ayéráyé?

Ní àkótán, ṣé ó yẹ kí àwọn Kristiẹni máa gbé ara wọn lọ sí ilé-ẹjọ́ lórí ọ̀rọ̀ ìjọ? Rárá kò yẹ! Ṣé ó yẹ kí àwọn Kristiẹni máa gbé ara wọn lọ sí ilé-ẹjọ́ lórí ọ̀rọ̀ ìlú? Bí ọ̀nà tí a fi lè yẹra fún un báwà, rárá. Ṣé ó yẹ kí àwọn Kristiẹni máa gbé aláìgbàgbọ́ lọ sí ilé-ẹjọ́ lórí ọ̀rọ̀ ìlú? Lẹ́kansi, bí ó bá ṣeé yẹra fún un, rárá. Ṣùgbọ́n, ní ìgbà míìrán, bíí ti ìdábòbo ẹ̀tọ́ wa (gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ ti àpọ́stélì Pọ́ọ̀lù), ó lè tọ̀nà láti máa lépa ọ̀nà àbáyọ ní ìlànà òfin.

English



Pada si oju ewe Yorùbá

Kínni Bíbélì sọ nípa gbígbéni lọ sí ilé-ẹjọ́?
Pin oju-iwe yii: Facebook icon Twitter icon Pinterest icon Email icon
© Copyright Got Questions Ministries