settings icon
share icon
Ibeere

Ǹjẹ́ ó lòdì fún tọkọtaya kan láti gbé papọ̀ ṣáájú ìgbéyáwó?

Idahun


Ìdáhùn sí ìbéèrè yìí dálé lórí àwọn ohun tí "gbígbe papọ̀" túmọ̀ sì. Bí ó bá túmọ̀ sí níní àwọn ìbáṣepọ̀ ìbálòpọ̀, ó jẹ́ àṣìṣe tí ó dájú. Ìbálòpọ̀ lóde ìgbeyàwó jẹ èyí tí a dá lẹ́bi léraléra nínú Ìwé Mímọ́, pẹ̀lú gbogbo ìbálòpọ̀ àìmọ̀ (Iṣe awọn Apọsteli 15:20; Romu 1:29; 1 Kọrinti 5:1; 6:13, 18; 7:2; 10:8; 2 Kọrinti 12:21; Galatia 5:19; Efesu 5:3; Kolosse 3:5; 1Tẹsalonika 4:3; Juda 7). Bíbélì ṣe ìgbélárugẹ ìsẹ́ra ẹni pátápátá ní òde (àti ṣájúú) ìgbéyàwó. Ìbálòpọ̀ ṣáájú ìgbéyàwó jẹ́ ohun tí kò tọ́ gẹ́gẹ́ bíi panṣágà àti èyíkéyì ìbálòpọ̀ àìmọ́, nítorí wípé gbogbo wọn ní wọn ńní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú ẹni tí o kò ṣe ìgbéyàwó pẹ̀lú.

Bí "gbígbé papọ̀" bá túmọ̀ sí gbígbé nínú ilé kan náà, bóyá ìyẹ́n jẹ́ ọ̀rọ̀ míìrán. Ní ìkẹhìn, kò sí ohun tí o burú pẹ̀lú kí ọkùnrin kan àti obìnrin kan máa gbé nínú ilé kan náà —bí kò bá sí ohun àìmọ́ kan tí ó ńṣẹlẹ̀. Ṣùgbọ́n, ìṣòro tí ó ńdìde nínú èyí ṣì ni ìfarahàn ìwà àìmọ́ (1 Tẹsalonika 5:22; Efesu 5:3), tí ó sì lè jẹ́ ìdánwò nlá fún ìwà àìmọ́. Bíbélì sọ fún wa láti sá fún ìwà àìmọ́, kí a má ṣe fi ara wa fún ìdánwò ìwà àìmọ́ ìgbà gbogbo (1 Kọrinti 6:18). Lẹ́yìn èyí ni ìṣòro àwọn ìfarahàn. Tọkọtaya kan tí wọ́n ńgbé papọ̀ ni a lérò wípé wọ́n ńsùn papọ̀—wípé bí nǹkan ṣe máa ńrì nìyẹn. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wípé gbígbé papọ̀ nínú ilé kan náà lè má jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ kan nínú ara tirẹ̀, ìfarahàn ẹ̀ṣẹ̀ ńbẹ níbẹ̀. Bíbélì sọ fún wa láti yẹra fún ìfarahàn tí ńṣe ibi (1 Tẹsalonika 5:22; Efesu 5:3), láti sá fún ìwà àìmọ́, àti láti má ṣe mú ẹnikẹ́ni kọsẹ̀ tàbí dẹ́ṣẹ̀. Fún ìdí èyí, kò jẹ́ ohun tí ó bú ọlá fún Ọlọ́run kí okùnrin kan àti obìnrin kan jọ gbé papọ̀ lóde tí ìgbéyàwó.

English



Pada si oju ewe Yorùbá

Ǹjẹ́ ó lòdì fún tọkọtaya kan láti gbé papọ̀ ṣáájú ìgbéyáwó?
Pin oju-iwe yii: Facebook icon Twitter icon Pinterest icon Email icon
© Copyright Got Questions Ministries