settings icon
share icon
Ibeere

Kínni o túmọ̀ sí láti gbàdúrà l’órúkọ Jésù?

Idahun


Àdúrà ni orúkọ Jésù ni a kẹ́kọ̀ọ́ rẹ ni Johannu 14:13-14, “Ohunkohun ti ẹyin ba si bere li orukọ mi, oun na li emi o ṣe, ki a le yin Baba logo ninu Ọmọ. Bi ẹyin ba si bere li orukọ mi, emi o ṣe e.” Àwọn kan ńṣi ẹsẹ yìí múlò, tí wọn ro wípé sísọ wípé “ní orúkọ Jésù” ní òpin àdúrà máa ńjẹ́ kí Ọlọ́run dáhùn nígbàgbogbo ohun ti a bèrè. Èyí dàbí kí a fi àwọn ọ̀rọ̀ náà “ní orúkọ Jésù” pe ajẹ́ bíi idán kan. Èyí kò bá bíbélì mu pátápátá.

Gbígbàdúrà ní orúkọ Jésù túmọ̀ sí gbígbàdúrà pẹ̀lú àṣẹ Rẹ̀ àti bíbèérè lọ́wọ́ Ọlọ́run Baba láti ṣiṣẹ́ lórí àwọn àdúrà wa nítorí a wá ní orúkọ Ọmọ Rẹ̀, Jésù. “Eyi si ni igboya ti awa ni niwaju rẹ̀, pe bi awa ba bere ohunkohun gẹgẹ bi ifẹ rẹ̀, o ngbọ ti wa. Bi awa ba si mọ̀ pe o ngbọ ti wa, ohunkohun ti awa ba bere, awa mọ̀ pe awa ri ibere ti awa ti bere lọdọ rẹ̀ gbà” (1 Johannu 5:14-15). Gbígbàdúrà ní orúkọ Jésù ni gbígbàdúrà fún àwọn nǹkan tí yóò bu ọlá àti ògo fún Jésù.

Sísọ wípé “ní orúkọ Jésù” ní òpin àdúrà kìí ṣe ajẹ́ bíi idán kan. Bí ohun tí a bèrè tàbí sọ nínú àdúrà kìí bá ṣe fún ògo Ọlọ́run àti gẹ́gẹ́ bíi ìfẹ́ Rẹ̀, sísọ wípé “ní orúkọ Jésù” kò túmọ̀ sí nǹkankan. Gbígbàdúrà ní tòótọ́ ní orúkọ Jésù àti fún ògo Rẹ̀ ni o ṣe pàtàkì, kìí ṣe síso àwọn ọ̀rọ̀ kan pọ̀ mọ́ òpin àdúrà. Kìí ṣe àwọn ọ̀rọ̀ inú àdúrà náà ni o ṣe kókó, ṣùgbọ́n ète tí ó wà lẹ́yìn àdúrà náà. Gbígbàdúrà fún nǹkan tí ó wà ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́ Ọlọ́run ni nǹkan pàtàkì nípa gbígbàdúrà ní orúkọ Jésù.

EnglishPada si oju ewe Yorùbá

Kínni o túmọ̀ sí láti gbàdúrà l’órúkọ Jésù?
Pin oju-iwe yii: Facebook icon Twitter icon Pinterest icon Email icon
© Copyright Got Questions Ministries