settings icon
share icon
Ibeere

Kínni ètò ìgbàlà?

Idahun


Ìgbàlà jẹ́ ìdáǹdè. Gbogbo ẹ̀sìn àgbáyé kọ́ wa wípé a nílò láti dá wa nídè, ṣùgbọ́n ẹnìkọ̀ọ̀kan ní òye ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ nípa ohun tí a nílò ìdáǹdè kúrò lọ́wọ́ rẹ̀, ìdí tí a nílò láti dá wa nídè, àti bí a ti le gbà tàbí ní ìdáǹdè. Bíbélì fihàn kedere púpọ̀, ẹ̀wẹ̀, wípé ọ̀na ètò ìgbàlà kan ló wà.

Ohun tí o ṣe pàtàkì jù láti mọ̀ nípa ètò ìgbàlà ni wípé ètò Ọlọ́run ni, kìí ṣe ètò ènìyàn. Ètò ìgbàlà ènìyàn yóò ma ṣe ètùtù ẹ̀sìn tàbí pa àwọn òfin kan mọ́ tàbí níní àwọn ìpele ìlanilójú ẹ̀mí kọ̀ọ̀kan. Ṣùgbọ́n kò sí ọ̀kan nínú àwọn nǹkan wọ̀nyìí tí ó jẹ́ ara ètò ìgbàlà Ọlọ́run.

Ètò ìgbàlà Ọlọ́run – Ìdí
Nínú ètò ìgbàlà Ọlọ́run, a gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ ní òye ìdí tí a fi nílò láti là.

Ní kúkúrú, a nílò láti di ẹni ìgbàlà nítorí a ti ṣẹ̀. Bíbélì sọ wípé gbogbo ènìyàn ló ti ṣẹ̀ (Oniwaasu 7:20; Romu 3:23; 1 Johanu 1:8). Ẹ̀ṣẹ̀ jẹ́ ìsọ̀tẹ̀ sí Ọlọ́run. Gbogbo wa la yàn láti ṣe àwọn ohun tí kò dára. Ẹ̀ṣẹ̀ máa ńpa ẹlòmíràn lára, pa wá run, àti pàtàkì jùlo, kẹ́gàn Ọlọ́run. Bíbélì tún kọ́ni wípé, nítorí Ọlọ́run jẹ́ mímọ́ àti olódodo, Òun kò lè gbà kí ẹ̀ṣẹ̀ lọ láì jìyà. Ikú ni èrè ẹ̀ṣẹ̀ (Romu 6:23) àti ìyapa ayérayé kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run (Ifihan 29:11-15). Láì sí ètò ìgbàlà Ọlọ́run, ikú ayérayé ni àyànmọ́ gbogbo ènìyàn.

Ètò ìgbàlà Ọlọ́run – Kínni
Nínú ètò ìgbàlà Ọlọ́run, Ọlọ́run tìkararẹ̀ nìkan ni ẹni tí Ó le pèsè ìgbàla wa.

A kò lè gba ara wa là nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wa àti àtunbọ̀tán rẹ̀. Ọlọ́run wá di Ènìyàn tíí ṣe Jésù Kristi (Johanu 1:1, 14). Jésù gbé ìgbe-ayé tí kò l'ẹ́ṣẹ̀ (2 Kọrinti 5:21; Heberu 4:15; 1 Johannu 3:5) Òun sì pèsè ara Rẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi ètùtù pípé ní ipò wa (1 Kọrinti 15:3; Kolosse 1:22; Heberu 10:10). Níwọ̀n bí Jésù ti jẹ́ Ọlọ́run, ikú Rẹ̀ jẹ́ ti iye àìlópin àti ayérayé. Ikú Jésù Kristi lórí àgbélèbú ti san gbèsè ẹ̀ṣẹ̀ gbogbo àgbáyé ní kíkún (1 Jo-hannu 2:2). Àjíǹde Rẹ̀ kúrò nínú òkú fihàn wípé ètùtù Rẹ̀ péye dáradára àti wípé ìgbàlà ti wà ní àrọ́wọ́tó.

Ètò ìgbàlà Ọlọ́run – Báwo
Nínú Iṣe àwọn Apọsteli 16:31, ọkùnrin kan béèrè lọ́wọ́ apọsteli Pọ́lù bí a ti le di ẹni ìgbàlà.

Ìdáhùn Pọ́lù ni, "Gba Jésù Kristi Olúwa gbọ́, a ó sì gbà ọ́ là." Ọ̀nà láti tẹ̀lé ètò ìgbàlà Ọlọ́run ni láti gbàgbọ́. Èyí nìkan ni ohun tí a nílò (Johannu 3:16; Efesu 2:8-9). Ọlọ́run ti pèsè ìgbàlà fún wa nípasẹ̀ Jésù Kristi. Ohun kansoso tí a nílò ni láti gbàá, nípa ìgbàgbọ́, ati níní ìgbẹkẹ̀lé kíkún nínú Jésù nìkan gẹ́gẹ́ bíi Olùgbàlà (Johannu 14:6; Iṣe àwọn Apọsteli 4:12). Ìyẹn ni ètò ìgbàlà Ọlọ́run.

Ètò ìgbàlà Ọlọ́run – Ṣe ìwọ yóò gbàá?
Bí o bá setán láti tẹ̀le ètò ìgbàlà Ọlọ́run, fi ìgbàgbọ́ rẹ sínú Jésù gẹ́gẹ́ bíi Olùgbàlà rẹ. Yí ọkàn rẹ padà kúrò nínu dídá ẹ̀ṣẹ̀ àti kíkọ Ọlọ́run sí kíko ẹ̀ṣẹ̀ àti gbígba Ọlọ́run nípasẹ̀ Jésù Kristi. Ní ìgbàgbọ́ kíkún nínú ètùtù Jésù gẹ́gẹ́ bíi ìsan gbèsè ẹ̀ṣẹ̀ rẹ ní pípé àti ní kíkún. Bí o bá ṣe èyí, àwọn ìlérí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run wpé á ó gbà ọ́ là, a ó dàrí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jìn, àti wípé o ó lo ayérayé rẹ ní ọ́run rere. Kò sí ìpinnu pàtàkì kankan mọ́. Fi ìgbàgbọ́ rẹ sínú Jésù Kristi gẹ́gẹ́ bí Olúwa rẹ lónìí!

Ti o ba fe gba jesu Kristi gbo gege bi olugbala re nikan, so awon oro won yi si Oluwa. Ranti wipe, gbigba adura yi tabi adura mi ran ko le gba o o la. O ni lati ni ireti ninu Jesu Kristi wipe o le dariji ese re ji o. Adura yi je eyi ti o file so fun Oluwa nipa igbagbo re ninu re, ki o si dupe fun idariji re.“ Oluwa, mo wipe elese ni mi. mo si mo wipe iya ayeraye to si mi fun ese mi.” Sugbon, mo ni ireti ninu Jesu Kristi gege bi olugbala. Mo mo n wipe iku ati ajinde re lo fun mi ni idariji ese. Mo ni ireti ninu Jesu, Jesu ni kan gege bi Olorun ni nikan ati olugbala mi. E se fun ore- ofe ati idariji ese mi- ebun ayeraye! Ami!

Nje o ti se ipinu fun Kristi nitoripe ohun ti o ti ka ninu oju ewe yi. To ba jebe, jowo te “Mo ti gba Kristi ni oni” ni abe.



English



Pada si oju ewe Yorùbá

Kínni ètò ìgbàlà?
Pin oju-iwe yii: Facebook icon Twitter icon Pinterest icon Email icon
© Copyright Got Questions Ministries