settings icon
share icon
Ibeere

Kínni ẹ̀sìn tòótọ́?

Idahun


A lè tumọ̀ "ẹ̀sìn" gẹ́gẹ́ bíi "ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run tàbí àwọn ọlọ́run tí a ńjọ́sìn fún, tí ó ńfarahàn nínú ìṣe àti ìrúbọ" tàbí "èyíkéyì ní pàtó ètò ìgbàgbọ́, ìjọ́sìn, abbl., èyítí ó ní nínú òfin ìṣesí." Ìdá àádọ́rin (90) nínú ọgọ́ọ̀rún àwọn ènìyàn l'ágbàyé lo ńṣe ẹ̀sìn kan tàbí òmíràn. Ìṣòro náà ni wípé ọ̀pọ̀lọpọ̀ oríṣiríṣi ẹ̀sìn ló wà. Kínni ẹ̀sìn tí ó tọ́? Kínni ẹ̀sìn tòótọ́?

Àwọn èròǹjà tí ó wọ́pọ̀ nínú ẹ̀sìn ni òfin àti ètùtù. Àwọn ẹ̀sìn kan kò jámọ́ nǹkankan ju àkójọ àwọn òfin, àwọn ohun ṣíṣe àti àìgbọdọ̀ ṣe, tí ènìyàn gbọ́dọ̀ ṣe kí á lè pèé ní onígbàgbọ́ tòótọ́ sí ẹ̀sìn, kí ó sì, wà ní ìbámu pẹ̀lú Ọlọ́run ẹ̀sìn yẹn. Àpẹẹrẹ òfin ẹ̀sìn méjì ni Ìmàle àti Judaisimu. Ẹ̀sìn Ìmàle ní òpó márùn-ún ti a gbọ́dọ̀ ṣe. Ẹ̀sìn Judaisimu ní àwọn ọgọọgọ́run òfin àti ìṣẹ̀ṣe tí a ní láti ṣe. Àwọn ẹ̀sìn méjèèjì, títí dé ìwọ̀n kan, gbà wípé nípa ìgbọ́ràn sí àwọn òfin ẹ̀sìn náà, ènìyàn ti di pípé pẹ̀lú Ọlọ́run.

Àwọn ẹ̀sín yòókù ṣe àfojúsùn jù lórí ètùtù ṣíṣe dípò ṣíṣe àwọn àkójọ òfin kan. Nípa pípèsè ètùtù yìí, ṣíṣe iṣẹ́ yìí, kíkópa nínú iṣẹ́ yìí, jíjẹ oúnjẹ yìí, abbl., ènìyàn ti di pípé pẹ̀lú Ọlọ́run. Àpẹẹrẹ ẹ̀sín ìbọ̀rìsà tó hàn gbangba jù ni ẹ̀sín Kátólíkì. Ẹ̀sín Kátólíkì gbà wípé nípa ìrìbọmi gẹ́gẹ́ bíi ìkókó, nípa ìkópa nínú Ìjọ́sín, nípa ìjẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ fún àlúfà, nípa gbígba àdúrà sí àwọn ènìyàn mímọ́ ní ọ̀run, nípa gbígba àmì òróró àlúfà ṣaájú ikú, abbl., Ọlọ́run yóò gba irú ẹni bẹ́ẹ̀ sínú ọ̀run lẹ́yìn ikú. Àwọn Ẹ̀sín Buddhi àti Hindu jẹ́ ẹ̀sín ìbọ̀rìsà pẹ̀lú, ṣùgbọ́n ní ìwọ̀n kúkúrú, a lè kà wọ́n sí wípé wọ́n jẹ́ àwọn tí a ńtipa àwọn òfin kan ńdarí.

Ẹ̀sìn tòótọ́ kìí ṣe ẹ̀sìn olófin tàbí ìbọ̀rìsà. Ẹ̀sìn tòótọ́ jẹ́ ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run. Ohun méjì tí gbogbo ẹ̀sìn gbà ni wípé ìran ọmọ ènìyàn ti yapa bákan kúrò l'ọ́dọ̀ Ọlọ́run wọ́n sì nílò láti báa làjà. Ẹ̀sìn èké ńwá láti yanjú ìṣòro yìí nípa ṣíṣe àwọn òfin àti ètùtù. Ẹ̀sìn tòótọ́ ńyanjú ìṣòro náà nípa mímọ̀ wípé Ọlọ́run nìkan ló lè yanjú ìyapa náà, àti pé Òun ti ṣe bẹ́ẹ̀. Ẹ̀sìn tòótọ́ mọ àwọn nǹkan wọ̀nyìí:

• Gbogbo wa lati ṣẹ̀ a sì ti yapa kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run (Romu 3:23).

• Bí kò bá yanjú, ìjìyà tó tọ́ fún ẹ̀ṣẹ̀ ni ikú àti ìyapa ayérayé kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run lẹ́yín ikú (Romu 6:23).

• Ọlọ́run tọ̀ wá wá ni àwòran Jésù Kristi Òun sì kú ní ipò wa, Òun gba ìyà tí a tọ́ sí jẹ, Òun sì jí dìde kúrò nínú òkú láti jẹ́ kí á mọ̀ wípé ikú Òun jẹ́ ètutù pípé (Romu 5:8; 1 Kọrinti 15:3-4; 2 Kọrinti 5:21).

• Bí a bá gba Jésù gẹ́gẹ́ bíi Olùgbàlà wa, tí à ńgbàgbọ́ nínú ikú Rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìsan gbèsè kíkún fún ẹ̀ṣẹ̀ wa, a ti dáríjì wá, gbà wá là, rà wá padà, bá wa làjà, àti dá wa láre pẹ̀lú Ọlọ́run (Johannu 3:16; Romu 10:9-10; Efesu 2:8-9).

Ẹ̀sìn tòótọ́ má ń ní àwọn òfin àti ètùtù, ṣugbọ́n ìyàtọ̀ pàtàkì kan wà. Nínú Ẹ̀sìn tòótọ́, a máa ńṣe àwọn òfin àti ètùtù pẹ̀lú ìmoore fún ìgbàlà tí Ọlọ́run ti pèsè – KÌÍ ṢE nínú ipá láti ní ìgbàlà. Ẹ̀sìn tòótọ́, èyí tíí ṣe Ẹ̀sìn Kristiẹni gẹ́gẹ́ bíi Ìwé-Mímọ́, ní àwọn òfin láti tẹ̀lé (máṣe pànìyàn, máṣe ṣe àgbèrè, máṣe parọ́, abbl.) àti ètùtù láti ṣe (ìrìbọmi pẹ̀lú omi nípa rírì bọ'nú àti oúnjẹ alẹ́ olúwa/Ìdàpọ̀). Ṣíṣe àwọn òfin àti ètùtù yìí kìí ṣe ohun tí ó mú ènìyàn wà ní ìbámu pẹ̀lú Ọlọ́run. Dípò bẹ́ẹ̀, àwọn òfin àti ètùtù jẹ́ ÀYỌRÍSÍ ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run, nípa ore-ọ̀fẹ́ nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ nínú Jésù Kristi nìkan gẹ́gẹ́ bíi Olùgbàlà. Ẹ̀sìn èké ni ṣíṣe àwọn nǹkankan (àwọn òfin àti ètùtù) ní ọ̀nà àti ní ojúrere Ọlọ́run. Ẹ̀sìn tòótọ́ ni gbígba Jésù Kristi gẹ́gẹ́ bíi Olùgbàlà kí á sì ni ìbáṣepọ̀ títọ́ pẹ̀lú Ọlọ́run – lẹ́yìn náà kí á ṣe àwọn nǹkankan (àwọn òfin àti ètùtù) nínú ìfẹ́ fún Ọlọ́run àti wípé kí a gbìyànjú láti súnmọ́-ọn.

Ti o ba fe gba jesu Kristi gbo gege bi olugbala re nikan, so awon oro won yi si Oluwa. Ranti wipe, gbigba adura yi tabi adura mi ran ko le gba o o la. O ni lati ni ireti ninu Jesu Kristi wipe o le dariji ese re ji o. Adura yi je eyi ti o file so fun Oluwa nipa igbagbo re ninu re, ki o si dupe fun idariji re.“ Oluwa, mo wipe elese ni mi. mo si mo wipe iya ayeraye to si mi fun ese mi.” Sugbon, mo ni ireti ninu Jesu Kristi gege bi olugbala. Mo mo n wipe iku ati ajinde re lo fun mi ni idariji ese. Mo ni ireti ninu Jesu, Jesu ni kan gege bi Olorun ni nikan ati olugbala mi. E se fun ore- ofe ati idariji ese mi- ebun ayeraye! Ami!

Nje o ti se ipinu fun Kristi nitoripe ohun ti o ti ka ninu oju ewe yi. To ba jebe, jowo te “Mo ti gba Kristi ni oni” ni abe.YorùbáPada si oju ewe Yorùbá

Kínni ẹ̀sìn tòótọ́?
Pin oju-iwe yii: Facebook icon Twitter icon Pinterest icon Email icon
© Copyright Got Questions Ministries