settings icon
share icon
Ibeere

Kínni ìdí tí mo fi gbọ́dọ̀ gbàgbọ́ nínú ẹ̀sìn elétò?

Idahun


Ìtumọ̀ "ẹ̀sìn" nínú ìwé ìtumọ̀-ọ̀rọ̀ yóò f'ara jọ "ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run tàbí àwọn ọlọ́run tí à ńsìn, tó ńfarahàn nínú ìṣe àti ìrúbọ; èyíkéyì ní pàtó ètò ìgbàgbọ́, ìjọ́sìn, abbl., èyítí ó ní òfin ìṣesí." Pẹ̀lú òye ìtumọ̀ yìí, Bíbélì sọ nípa ẹ̀sìn elétò, ṣùgbọ́n ní ọ̀pọ̀ ìgbà ìdí àti ipa "ẹ̀sìn elétò" kìí ṣe ohun tí inú Ọlọ́run dùn sí.

Nínú Jẹnẹsisi orí 11, yóò fẹ́ jẹ́ ìgbà ẹ̀sìn elétò àkọ́kọ́, àwọn àrọ́mọdọ́mọ Noah ṣ'ètò ara wọn láti orí òkè Bábélì dípò kí wọ́n gbọ́ràn sí àṣẹ Ọlọ́run láti kún gbogbo ayé. Wọ́n gbàgbọ́ wípé ìtẹ́lọ́rùn wọn jẹ́ pàtàkì ju ìbáṣepọ̀ wọn pẹ̀lú Ọlọ́run lọ. Ọlọ́run dásíi ó sì da èdè wọn rú, èyí sì fọ́ ètò ẹ̀sìn wọn.

Ní Ẹksodu orí 6 àti èyítí ó tẹ̀lée, Ọlọ́run "ṣ'ètò" ẹ̀sìn fún orílẹ̀-èdè Isrẹli. Ọlọ́run ni Ó pilẹ̀ Àwọn òfin Mẹ́wàá, àwọn òfin tó nííṣe pẹ̀lú gbọ̀ngàn ìjọ́sìn, àti ètò ìrúbọ èyítí àwọn ọmọ Isrẹli ńní láti tẹ̀le. Ìkẹ̀kọ̀ọ́ síwájú síi lórí Májẹ̀mú Titun fihàn wípé ìdí ẹ̀sìn yìí ni láti tọ́ka sí ìwúlò fún Olùgbàlà-Mesiah (Galatia 3; Romu 7). Ṣùgbọ́n, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ti ṣi èyí túmọ̀ wọ́n sì ti ńjọ́sìn fún àwọn òfin àti ìrúbọ dípò Ọlọ́run.

Fún gbogbo ìtàn Isrẹli, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìrírí ìjà àwọn ọmọ Isrẹli jẹ́ pẹ̀lú àwọn ẹ̀sìn elétò. Àwọn àpẹẹrẹ ni ìforíbalẹ̀ fún Báálì (Onidajọ 6; 1 Awọn Ọba 18), Drágónì (1 Samueli 5), ati Mólèsì (2 Awọn Ọba 23:10). Ọlọ́run ṣẹ́gun àwọn olùtẹ̀lé ẹ̀sìn wọ̀nyìí, ó sì fi Títóbí jùlọ àti Agbára Rẹ̀ hàn.

Nínú àwọn Ìwé Ìhìnrere, a ṣe àfihàn àwọn Farisí àti Sadusí bíi aṣojú ẹ̀sìn elétò ní àkókò Kristì. Jésù máa ńkojú wọn ní gbogbo ìgbà nípa ẹ̀kọ́ èké àti ìgbé-ayé àgàbàgabè. Nínú àwọn Ẹpistili, àwọn ẹgbẹ́ elétò kan wà tó ńda ìhìnrere pọ̀ mọ́ iṣẹ́ àti ìrúbọ kan tí a nílò. Wọ́n tún fẹ́ ríi pé àwọn dúró lé àwọn onígbàgbọ́ lọ́rùn láti yípadà kí wọ́n síì gba ẹ̀sìn "Àfikún ìgbàgbọ́" wọ̀nyìí. Galatia ati Kolosse kìlọ̀ nípa irú àwọn ẹ̀sìn bẹ́ẹ̀. Nínú ìwé Ìfihàn, ẹ̀sìn elétò yóò ní ipa lórí ayé bíi asòdì sí Kristi ṣe ńṣètò ẹ̀sìn ayé kan.

Ní ọ̀pọ̀ ìgbà, àyọrísí ẹ̀sìn elétò jẹ́ ìdíwọ́ fún ètò Ọlọ́run. Ṣùgbọ́n, Bíbélì sọ nípa àwọn onígbàgbọ́ elétò tí wọ́n wà nínú ètò Rẹ̀. Ọlọ́run pe àwọn ẹgbẹ́ onígbàgbọ́ elétò yìí ní "àwọn ìjọ." Àpèjúwe láti inú ìwé Iṣe Apọsteli àti Ẹ̀pístélì tọ́kasí wípé ìjọ gbọ́dọ̀ jẹ́ elétò kí wọ́n sì lè dádúró. Àjọ náà yọrí sí ààbò, àbájáde gidi, àti ìjáde (Iṣe àwọn Apọsteli 2:41-47). Ní ti ìjọ, yóò dára jù kí á pèé ní "ìbáṣepọ̀ elétò."

Ẹ̀sìn jẹ́ ìgbìyànjú ènìyàn láti ní ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run. Ẹ̀sìn Ìgbàgbọ́ jẹ́ ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run nítorí ohun tí o ti ṣe fún wa nípasẹ̀ ìrúbọ Jésù Kristi. Kò sí ètò láti rí Ọlọ́run (Òun ti kàn sí wa —Romu 5:8). Kò sí ìgbéraga kankan (a gba gbogbo rẹ̀ nípa ore-ọ̀fẹ́—Efesu 2:8-9). Kò gbọ́dọ̀ sí ìjà lórí ṣíṣe olórí (Kristi ni olórí — Kolosse 1:18). Kò gbọdọ̀ sí ìkóríra (ọ̀kan ni gbogbo wá nínú Kristi—Galatia 3:28). Ṣíṣe ètò kọ́ ni ìṣòro. Ìfojúsí òfin àti ìrúbọ ẹ̀sìn ní ìsòro.

EnglishPada si oju ewe Yorùbá

Kínni ìdí tí mo fi gbọ́dọ̀ gbàgbọ́ nínú ẹ̀sìn elétò?
Pin oju-iwe yii: Facebook icon Twitter icon Pinterest icon Email icon
© Copyright Got Questions Ministries