settings icon
share icon
Ibeere

Ṣé gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ dọ́gba sí Ọlọ́run?

Idahun


Nínú Matteu 5:21-28, Jésù ṣe ìdọ́gba ṣíse àgbèrè pẹ̀lú ìgbèrò ìfẹ́kùfẹ́ nínú ọkàn rẹ àti ìpànìyàn pẹ̀lú ìgbèrò ìkà l'ọ́kàn rẹ. Ṣùgbọ́n, èyí kò túmọ̀ sí wípé àwọn ẹ̀ṣẹ̀ náà dọ́gba. Ohun tí Jésù ńgbìyànjú láti sọ fún àwọn Farisí ni wípé ẹ̀ṣẹ̀ ṣì jẹ̀ ẹ̀ṣẹ̀ kódà tí o bá gbèrò láti ṣeé nìkan, láì tíì ṣé rárá. Àwọn adarí ẹ̀sìn ni àkókò Jésù kọ́ni wípé ó dára láti gbèrò ohunkóhun tí o bá fẹ́, níwọ̀n ìgbà tí o kò bá ti ṣe wọ́n. Jésù ńfi ipá mú wọn láti mọ̀ wípé Ọlọ́run ńse ìdájọ́ èrò ènìyàn àti iṣẹ́ rẹ̀ pẹ̀lú. Jésù kéde wípé àwọn iṣẹ́ wa jẹ́ àyọrísí ohun tó ńbẹ nínú ọkàn wa (Matteu 12:34).

Nítorínáà, bí ó tilẹ̀ jẹ́ wípé Jésù sọ wípé ìfẹ́kùfẹ́ àti àgbèrè jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀, ìyẹn kò túmọ̀ sí wípé wọ́n dọ́gba. Ó burú gidigidi láti pànìyàn ju kí á kórìíra ènìyàn lọ, bí ó tilẹ̀ jẹ́ wípé àwọn méjèèjì jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ ní ojú Ọlọ́run. Ìpèlè ẹ̀ṣẹ̀ wà. Àwọn ẹ̀ṣẹ̀ míìrán burú ju àwọn yòókù lọ. Bákannáà, ní ìbámu pẹ̀lú ìjìyà ayérayé àti ìgbàlà, bákannáà ní gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ rí. Gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ ni yóò yọrí sí ìparun ayérayé (Romu 6:23). Gbogbo ẹ̀ṣẹ̀, bí ó tilè wù kí ó "kéré" tó, lòdì sí Ọlọ́run ayérayé àti àìlópin, ó sì yẹ fún ìjìyà ayéraré àti àìlópin. Síwájú síí, kò sí ẹ̀ṣẹ̀ tó "tóbi" jù tí Ọlọ́run kò le dárí rẹ̀ jì. Jésù kú láti san gbèsè ìjìyà ẹ̀ṣẹ̀ wa (1 Johannu 2:2). Jésù kú fún gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ wa (2 Kọrinti kejì 5:21). Ṣé gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ dọ́gba sí Ọlọ́run? Bẹ́ẹ̀ni tàbí bẹ́ẹ̀kọ́. Ṣé ó ní ìdibàjẹ́? Bẹ́ẹ̀kọ́. Ṣé ó ní ìjìyà? Bẹ́ẹ̀ni. Ṣé ó ní ìdáríjìn? Bẹ́ẹ̀ni.

English



Pada si oju ewe Yorùbá

Ṣé gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ dọ́gba sí Ọlọ́run?
Pin oju-iwe yii: Facebook icon Twitter icon Pinterest icon Email icon
© Copyright Got Questions Ministries