settings icon
share icon
Ibeere

Kínni àwọn ẹ̀ṣẹ̀ aṣekúpani mẹ́je?

Idahun


Gẹ́gẹ́ bí èròngàa àwọn ìjọ Àgùdà, àwọn ẹ̀ṣẹ̀ aṣekúpani méje ni ìwà ibi méje tàbí àwọn àbùdá ìwà òdí, èyítí a kò bá yẹ̀ẹ́wò, yóò yọrí sí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ míìrán àti wípé yóò padà pa ọkàn ẹni. Àwọn ẹ̀ṣẹ̀ "aṣekúpani" méje ni ìgbéraga, owú, wọ̀bìa, ìfẹ́kùfẹ́, ìbínú, ojúkòkòrò, àti ọ̀lẹ. Ẹni ńlá Popu Gregory ni ó kọ́kọ́ ṣe ìmúdúró àkójọ náà ní ọgọ́ọ̀rún ọdún kẹfà. Lẹ́yìn náà ni Thomas Aquinas ṣe àsọyé lórí àbá náà. Ní ẹgbẹ̀rún ọdún kẹrìnlá, Dante kọ ewì àdáyébá Inferno nínú èyítí ó ṣe àwòrán Ipò Ìjìyà tí ó ní ìpele méje ní ìbáámu sí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ aṣekúpani méje.

À tún ńpe àwọn ẹ̀ṣẹ̀ aṣekúpani méje ní àwọn olú ẹ̀ṣẹ̀ méje tàbí àwọn kókó ẹ̀ṣẹ̀ méje—koko nínú èrò yìí túmọ̀ sí, "ìpìlẹ̀ pàtàkì" tàbí "jinlẹ̀ gidigidi." Àwọn ẹ̀ṣẹ̀ aṣekúpani méje ní a pè ní ẹ̀ṣẹ ìpìlẹ̀ tó ńṣe àkóbá fún ìran ènìyàn àti àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ṣeé ṣe láti dì mọ́ wa jùlọ. Ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ẹ̀ṣẹ̀ aṣekúpani méje wọ̀nyìí ńyọrísí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ míìrán; fún àpẹẹrẹ, ìbínú le yọrí sí ọ̀rọ̀ búburú, ìrúkèrudò, tàbí ìpànìyàn.

Èyí ni àpèjúwe ráńpẹ́ nípa ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ẹ̀ṣẹ̀ aṣekúpani méje náà:
Ìgbéraga — Ìmú ga èrò tí kò bójúmu nípa ìwọ̀n ara ẹni.
Owú — Ìmọ̀lára pé ó lẹ̀tọ́ sí dúkìá, oríire, ìwà rere, tàbí ẹ̀bùn ẹlòmíràn.
Wọ̀bìà — Ìfẹ́ àníjù fún ìgbádùn jíjẹ àti mímu.
Ìfẹ́kùfẹ́ — Àfojúsùn ìmọtaraẹni lórí ìbálòpọ̀ tàbí ìfẹ́ sí ìbálòpọ̀ pẹ̀lú ẹlòmíràn yàtọ̀ sí ọkọ tàbí aya rẹ.
Ìbínú — Ìfẹ́ àníjù , sí ìgbẹ̀san tí kò bójúmu.
Ìmọ tara ẹni nìkan — Ìfẹ́ líle fún dúkìá, pàápàá jùlọ fún dúkìá tó jẹ́ ti ẹlòmíràn.
Ọ̀lẹ — Àìní akitiyan láti dojúkọ iṣẹ́ pàtàkì, tí ó ń fa àìṣe rẹ̀ (tàbí se rádaràda).

Èrò àìtọ́ tí ó wọ́pọ̀ nípa àwọn ẹ̀ṣẹ̀ aṣekúpani méje náà ni wípé wọ́n jẹ́ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tí Ọlọ́run kò ní dáríjìn. Ìjọ Àgùdà kò kọ́ni wípé ẹ̀sẹ̀ kò ní ìdáríjìn; ní ẹ̀sìn àgùdà, àwọn ẹ̀ṣẹ̀ aṣekúpani méje náà lè yọrí sí ẹ̀ṣẹ̀ ara, èyítí yóò ran ènìyàn sí ọ̀run-àpáàdì kété lẹ́yìn ikú, àyààfi tí a bá ronúpìwàdà irú ẹ̀ṣẹ̀ bẹ́ẹ̀ ṣáájú ikú. Ẹ̀sìn Àgùdà tún ńkọ́ni wípé a lè borí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ aṣekúpani méje náà pẹ̀lú ìwà rere méje (ìrẹ̀lẹ̀, ìmoore, ìfẹ́, ìwà tútù, ìpamọ́ra, sùúrù, àti àìsọ̀lẹ).

Ṣé èrò àwọn ẹ̀ṣẹ̀ aṣekúpani méje bá Bíbélì mu? Bẹ́ẹ̀ni tàbí bẹ́ẹ̀kọ́. Owe 6:16-19 ṣe àkójọ ohun méje tí o ṣe ìríra fún Ọlọ́run: 1)Ojú ìgbéraga, 2) ètè èké, 3) ọwọ́ tí ń ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀, 4) àyà tí ńhùmọ̀ búburú, 5) ẹsẹ̀ tí ó yára sí eré sísá sí ìwà-ìkà, 6) ẹlẹ́rìí èké, àti 7) ẹnití ń dá ìjà sílẹ̀ láàrin àwọn arákùnrin. Bẹ́ẹ̀ni, àkójọ yìí kìí ṣe ohun tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn mọ̀ sí "àwọn ẹ̀ṣẹ̀ aṣekúpani méje."

Bẹ́ẹ̀ni, ìgbéraga, owú, abbl., jẹ́ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tí Bíbélì dá l'ẹ́bi; ṣùgbọ́n, a kọ́ wípè wọ́n ní "àwọn ẹ̀ṣẹ̀ aṣekúpani méje" nínú Bíbélì. Àkójọ àbáláyé tí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ aṣekúpani méje lè ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà láti to ọ̀pọ̀lọpọ̀ oríṣi ẹ̀ṣẹ̀ tí ó wà sí ìṣòrí. Gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ ni a fẹ́rẹ̀ le fi sínú ọ̀kan lára àwọn ẹka méje wọ̀nyìí.

Ní àlàyé ìparí, kò sí ẹ̀ṣẹ̀ tó tún "ṣekúpani " ju ẹ̀ṣẹ̀ míìrán lọ. Gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ ló ńyọrí sí ikú (Romu 6:23). Kódà ikú kan ńdá ènìyàn l'ẹ́bi gẹ́gẹ́ bíi arúfin ni (Jakọbu 2:10). Ọpẹ́ ni fún Ọlọ́run wípé Jésù Kristi ti mú ìjìyà fún gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ wa kúrò, pẹ̀lú "àwọn ẹ̀ṣẹ̀ aṣekúpani méje." Pẹ̀lú ore-ọ̀fẹ́ Ólọ́run, nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ nínú Kristi, a le dáríjì wá (Matteu 26:28; Iṣe Apọsteli 10:43; Efesu 1:7).

EnglishPada si oju ewe Yorùbá

Kínni àwọn ẹ̀ṣẹ̀ aṣekúpani mẹ́je?
Pin oju-iwe yii: Facebook icon Twitter icon Pinterest icon Email icon
© Copyright Got Questions Ministries