Ibeere
Kínni Bíbélì sọ nípa bí a ṣe lè wá èrèdí ìgbé-ayé?
Idahun
Bíbélì fihàn kedere ohun tí èrèdí ìgbé-ayé yẹ kí ó jẹ́. Àwọn ènìyàn tí ó wà nínú Májẹ̀mú Láíláí àti Májẹ̀mú Titun wá èrèdí ìgbé-ayé, wọ́n sì ríi. Sólómọ́nì, ọkùnrin tí ó gbọ́njù tí ó gbé ilé ayé, rí ìmúlẹ̀mófo ayé nígbàtí a bá lòó fún ayé yí nìkan. O sọ àwọn ọ̀rọ̀ ìkásẹ̀ńlẹ̀ yìí nínú ìwé Oníwàásù: "Òpin gbogbo ọ̀rọ̀ náà tí a gbọ́ ni pé: Bẹ̀rù Ọlọ́run kí o sì pa òfin rẹ̀ mọ́: nítorí èyí ni fún gbogbo ènìyàn. Nítorípé Ọlọ́run yóò mú olúkúlùkù iṣẹ́ wá sínú ìdájọ́, àti olúkúlùkù ohun ìkọ̀kọ̀, ìbá ṣe rere, ìbá ṣe búburú." (Oníwàásù 12:13-14). Sólómọ́nì sọ wípé ìgbé-ayé wà nípa fífi ọ̀wọ̀ fún Ọlọ́run nínú èrò àti ìgbé-ayé wa, kí á sì pa àwọn òfin Rẹ̀ mọ́, nítorí ní ọjọ́ kan, àwa yóò dúró níwájú Rẹ̀ ní ìdájọ́. Ara èrèdí ìgbé-ayé wa ni láti bẹ̀rù Ọlọ́run, kí á sì gbọ́ràn sí I.
Òmíràn nínú ara èrèdí ìgbé-ayé wa ni láti rí ayé yí pẹ̀lú àfojúsùn. Yàtọ̀ sí àwọn tí àfojúsùn wọn wà lórí ayé, Ọba Dáfídì wá ìtẹ́lọ́rùn rẹ̀ ní ayé tí ó ń bọ̀. Òun sọ wípé, " Bí ó ṣe ti èmi ni èmi ó ma wo ojú rẹ lí òdodo: àwòrán rẹ yío tẹ́ mi lọ́rùn nígbàtí mo bá jí. (Orin Dafidi 17:15). Fún Dáfídì, ìtẹ́lọ́rùn kíkún yóò wà ní ọjọ́ tí ó bá dìde (ní ayé tí ó ń bọ̀) tí ó sì máa wo ojú Ọlọ́run (ìfarakínra pẹ̀lú Rẹ̀) , tí ó sì dàbí Rẹ̀ (1 Johannu 3:2).
Nínú Orin Dáfídì 73, Ásáfù sọ nípa bí a ṣe dán an wò láti ṣe ìlara àwọn ènìyàn búburú tí ó dàbí ẹni wípé wọn kò ní àníyàn, tí wọ́n sì kó ọrọ̀ wọn jọ lára àwọn tí wọ́n jèrè lára wọn, ṣùgbọ́n lẹ́yìn náà ó wo àtubọ̀tán wọn. Yàtọ̀ sí ohun tí wọ́n lépa òun sọ ní ẹsẹ kẹẹdọ́gbọ̀n ohun tí ó jọ òhun lójú: "Tani mo ní lí ọ̀run bíkòṣe ìwọ? Kò sí sí ohun tí mo fẹ́ lí ayé pẹ̀lú rẹ." Fún Ásáfù, ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run ṣe pàtàkì ju ohun gbogbo lọ ní ayé. Láìsí ìbáṣepọ̀ yẹn, ayé kò ní ìtumọ̀ tí ó ṣe kókó.
Àpọ́stélì Pọ́ọ̀lù sọ nípa ohun gbogbo tí ó tí ní nípa ẹ̀sìn kí ó tó di wípé Kristi tí ó jíǹde kòó lójú, ó sì pinnu rẹ̀ wípé gbogbo rẹ̀ dàbí ìgbẹ́ ní àfiwé pẹ̀lú ìtayọ ìmọ̀ Kristi Jésù. Nínú Fílíppi 3:9-10, Pọ́ọ̀lù sọ wípé òun kò fẹ́ ohunkóhun yàtọ̀ sí láti mọ Krísti, "kí á sì le ri nínú Rẹ̀", kí ó ní òdodo Rẹ̀ , kí ó sì gbé nípa ìgbàgbọ́ nínú Rẹ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ ìjìyà àti ikú. Èrèdí Pọ́ọ̀lù ni láti mọ Kristi, kí ó ní òdodo tí ó ti inú ìgbàgbọ́ wá nínú Rẹ̀, kí ó sì máa gbé ni ìdàpọ̀ pẹ̀lú Rẹ̀, bí ó tilẹ̀ lè fa ìjìyà (2 Timoteu 3:12). Lákótán, ó ń wo ìgbà tí ó lè jẹ́ alábápín nínú "àjíǹde kúrò nínú òkú"
Èrèdí ìgbé-ayé wa, gẹ́gẹ́ bíi Ọlọ́run ti ṣe dá ènìyàn lákọ́kọ́, ni 1) láti f'ògo fún Ọlọ́run, kí á sì gbádùn ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú Rẹ̀, 2) kí á ní ìbádọ́rẹ́ pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn, 3) iṣẹ́, àti 4) kí á ní ìṣàkóso lórí ayé. Ṣùgbọ́n nígbà tí ènìyàn ṣubú sínú ẹ̀ṣẹ̀, ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run bàjẹ́, ìbádọ́rẹ́ pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn fà sẹ́yìn, iṣẹ́ dàbi ẹni wípé ó ńsú enìyàn nígbà gbogbo, enìyàn sì ńtiraka láti pa ohunkóhun tí ó jọ ìṣàkóso mọ́ lórí ìṣẹ̀dá. Ìgbà tí a dá ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run padà bọ̀ sípò, nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ nínú Jésù Kristi, ni a tún lè rí èrèdí ìgbé-ayé.
Èrèdí ìgbé-ayé ènìyàn ni láti f'ògo fún Ọlọ́run kí á sì gbádùn Rẹ̀ láíláí. A f'ògo fún Ọlọ́run nípa bí bẹ̀rù Ọlọ́run àti ìgbọràn sí I, fífi ojú wa sí ilé ọjọ́ iwájú ní ọ̀run, kí á sì mọ Ọ́ tímọ́tímọ́ ní ìkẹhìn. A gbádùn Ọlọ́run nípa títẹ̀lé èrèdí Rẹ̀ fún ayé wa, tí ó jẹ́ kí á ní ìrírí ayọ̀ tí ó jẹ́ òtítọ́, tí ó sì pẹ́—ayé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ tí Òun fẹ́ fún wa.
English
Kínni Bíbélì sọ nípa bí a ṣe lè wá èrèdí ìgbé-ayé?