settings icon
share icon
Ibeere

Kínni ìwò ẹni ti ó gbàgbọ́ wípé a ti mú àwọn àkọsílẹ̀ nípa òpin ayé ṣẹ?

Idahun


Gẹ́gẹ́ bíi ìwò ẹni ti ó gbàgbọ́ wípé a ti mú àwọn àkọsílẹ̀ nípa òpin ayé ṣẹ, gbogbo àsọtẹlẹ nínú Bíbélì ti lẹ̀ jẹ́ ìtàn. Ìwò ẹni ti ó gbàgbọ́ wípé a ti mú àwọn àkọsílẹ̀ nípa òpin ayé ṣẹ túmọ̀ Ìwé Mímọ tí ó ní fi ṣe pẹlú ìwe Ìfihàn bíi àwọn àmì àwòrán àìgbọra ẹni yé tí ọgọ́rùn-ún ọdún àkọ́kọ́, kìí ṣe àpèjúwe ohun tí yóò ṣẹlẹ ní òpin ayé. Ọrọ preterism wá láti inú ède Látìnì praeter, tí ó túmọ̀ sí "ti kọjá." Nítorí náà, preterism jẹ́ ìwò wípé àwọn àsọtẹ́lẹ̀ ti bíbélì nípa ti "òpin ayé" ti wá sí ìmúṣẹ—ní àtì ẹ̀hìn wá. Ìwò ẹni ti ó gbàgbọ́ wípé a ti mú àwọn àkọsílẹ̀ nípa òpin ayé ṣẹ ní tààrà tako wíwo ọjọ iwájú, èyítí ó rí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ òpin ayé bíi èyí tí yóò ṣẹ ní ọjọ́ iwájú tí ó dúró tiiri.

Ìwò ẹni ti ó gbàgbọ́ wípé a ti mú àwọn àkọsílẹ̀ nípa òpin ayé ṣẹ ni a pín sí ọnà méjì: Àyọkà yìí yóò tẹpẹlẹmọ́ ìjíròrò nípa ìwò ẹni ti ó gbàgbọ́ wípé a ti mú àwọn àkọsílẹ̀ nípa òpin ayé ṣẹ ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ (tàbí ìwò ẹni ti ó gbàgbọ́ wípé a ti mú àwọn àkọsílẹ̀ nípa òpin ayé ṣẹ tí ó ga, ní bí àwọn kan ṣe ńpèé).

Ẹ̀kọ́ ìwò wípé a ti mú àwọn àkọsílẹ̀ nípa òpin ayé ṣẹ sẹ́ àsọtẹlẹ ọjọ́ iwájú ti ìwé Ìfihàn tí ó jẹ́ ojúlówó. Ẹ̀kọ́ ìwò wípé a ti mú àwọn àkọsílẹ̀ nípa òpin ayé ṣẹ ńkọ́ni wípé gbogbo àsọtẹlẹ òpin ayé nínú Májẹmú Titun ti di mímúsẹ ní AD 70 nígbàtí àwọn ará Róòmù kọlu Jerúsálẹmù tí wọn sì run ún. Ẹ̀kọ́ ìwò wípé a ti mú àwọn àkọsílẹ̀ nípa òpin ayé ṣẹ ńkọ́ni wípé gbogbo ìṣẹ̀lẹ̀ tí a má ńsopọmọ àwọn òpin ayé—ìpadàbọ̀ Kristi lẹ́ẹ̀kejì , ìpọnjú náà, àjíǹde kúrò nínú òkú, ìdájọ́ tí ó kẹ́hìn—tí ṣẹlẹ̀ náà. (Ní ti ọ̀rọ̀ ti ìdájọ́ tí ó kẹhìn, ó ṣì wà ní ọ̀nà láti wá sí ìmúṣẹ.) Ìpadàbọ̀ Jésù sí ayé jẹ́ ti ''ẹ̀mí'', kìí ṣe ti àfojúrí kan.

Ẹ̀kọ́ ìwò wípé a ti mú àwọn àkọsílẹ̀ nípa òpin ayé ṣẹ ńkọ́ni wípé a ti mú Òfin ṣẹ ní AD 70 ti májẹmú Ọlọ́run pẹlú Isrẹli sì ti dópin. "Ọrun titun àti ayé titun" tí à ńsọ nípa rẹ nínú Ìfihàn 21:1, fún àwọn ẹni ti ó gbàgbọ́ wípé a ti mú àwọn àkọsílẹ̀ nípa òpin ayé ṣẹ, jẹ́ àpèjúwe ti ayé yìí lábẹ Májẹmú Titun. Gẹ́gẹ́ bíi a ṣe sọ Kristiẹni di ''ẹ̀dá titun'' (2 Kọrinti 5:17), bẹ́ẹ̀ ni ayé ní abẹ́ Májẹmú Titun di "ayé titun." Igun tí ẹni ti ó gbàgbọ́ wípé a ti mú àwọn àkọsílẹ̀ nípa òpin ayé ṣẹ lè darí ìgbàgbọ ní ìrọrun láti dípò ẹ̀kọ́ nípa Ọlọ́run.

Àwọn ẹni ti ó gbàgbọ́ wípé a ti mú àwọn àkọsílẹ̀ nípa òpin ayé ṣẹ máa n ńsábà tọ́kasí ẹsẹ̀ kan nínú tí Àkọsílẹ Olivet ti Jésù láti fí àríyànjiyàn wọn múlẹ̀. Lẹhìn tí Jésù ṣe àpejúwe díẹ nínú àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ òpin ayé, Òun wípé, ''Lóòtọ ni mo wí fún yin, ìran yìí kò ní kọjá lọ tí tí gbogbo àwọn ohun wọnyìí yóò fi ṣẹlẹ'' (Matteu 24:34). Àwọn ẹni ti ó gbàgbọ́ wípé a ti mú àwọn àkọsílẹ̀ nípa òpin ayé ṣẹ náà mú eléyìí kí ó túmọ sí wípé gbogbo nǹkan ti Jésù sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ nínú Matteu 24 tí nílò láti ṣẹlẹ̀ láàrín ìran kan tí Òun fi sọ̀rọ̀—ti ìparun ti Jerúsálẹmù ní AD 70 nítorí ná fi jẹ́ "Ọjọ́ Ìdájọ́."

Àwọn ìṣòro tí ó wà pẹ̀lú ẹni ti ó gbàgbọ́ wípé a ti mú àwọn àkọsílẹ̀ nípa òpin ayé ṣẹ pọ̀ púpọ̀. Fún ohun kan, Májẹmú Ọlọ́run pẹ̀lú Isrẹlì jẹ́ títí láíláí (Jeremiah 31:33-36), ti ọjọ́ iwájú ìmúpadàbọsípò ti Isrẹlì yóò wà (Isaiah 11:12). Àpọstelì Pọ́ọ̀lù kìlọ lòdì sí àwọn ẹni tí ó ńkọ́ni, bíi Híménéù àti Fílétù, lọ́nà èké "wípé àjínde náà ti ṣẹlẹ ná, àti tí wọn sì ba ìgbàgbọ àwọn díẹ kan jẹ" (2 Timoteu 2:17-18). Àti ìmẹnubà Jésù nípa "ìran yìí" ni a gbọ́dọ̀ gbà láti tumọ̀ sí ìran tí ó wà láàyè láti rí ìbẹ̀rẹ̀ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí a ṣe àpèjúwe rẹ̀ ní Matteu 24.

Àwọn ẹ̀ka ẹ̀kọ́ ẹsìn tí ó ní fi ṣe pẹ̀lú òpin ayé jẹ́ èyítí ó jinlẹ̀, àti àmúlò àwọn àwòrán Bíbélì láti ṣe ìfìhàn àwọn àsọtẹlẹ ti yọrí sí onírúurú ìtumọ̀ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ òpin ayé. Àyè wà fún àigbà fún ara ẹni díẹ kan láàrín ẹsin Kristiẹni nípa àwọn ohun wọ̀nyìí. Ṣùgbọ́n, ẹni ti ó gbàgbọ́ wípé a ti mú àwọn àkọsílẹ̀ nípa òpin ayé ṣe ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ní àwọn kùdìẹ kudiẹ kan tí ó ṣe kókó ní wípé ó sẹ àfojúrí ìwasáyé tí ìpadàbọ ti Kristi lẹ́ẹ̀kejì tí ó yẹpẹrẹ àbùdá tí o bani lẹrù ti ìpọnjú nípa dídí lọ́wọ́ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó fa ìṣubú Jerusálẹmù.

EnglishPada si oju ewe Yorùbá

Kínni ìwò ẹni ti ó gbàgbọ́ wípé a ti mú àwọn àkọsílẹ̀ nípa òpin ayé ṣẹ?
Pin oju-iwe yii: Facebook icon Twitter icon Pinterest icon Email icon
© Copyright Got Questions Ministries