settings icon
share icon
Ibeere

Ṣé ẹ̀kọ́ nípa ìgbàlà gbogbo àgbáyé/ìgbàlà ti gbogbo àgbáye bá Bíbélì mu?

Idahun


Ẹ̀kọ́ nípa ìgbàlà gbogbo àgbáyé jẹ ìgbàgbọ wípé gbogbo ènìyàn ni yóò di ẹni ìgbàlà. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn lóde òní ló di ẹ̀kọ́ mú wípé gbogbo àgbáye yóò di ẹni ìgbàlà ti wọn si gbàgbọ́ wípé gbogbo ènìyàn ni yóò gúnlẹ sí Ọrun ní ìgbẹ̀hìn. Síbẹ èrò wípé àwọn ọkùnrin àti àwọn obìnrin tí yóò gbé ìgbé-ayé ti ìpọnnílojú ayérayé ní inú ọ̀run-àpáàdì ni ó ṣe òkùnfà àwọn elòmíràn láti kọ àwọn ìkọni tí Ìwé Mímọ lórí ọrọ yìí. Fún àwọn kan ó jẹ àwítúnwí lórí ìfẹ àti ìkánùú Ọlọrun—àti àìkàsí òdodo àti ìdájọ Ọlọrun—tí ó ńdarí wọn láti gbàgbọ wípé Ọlọrun yóò ṣàánú fún gbogbo alààyè ọkàn. Ṣùgbọn àwọn Ìwé Mímọ ńkọni wípé àwọn ènìyàn kan yóò lo ayérayé nínú ọ̀run-àpáàdì.

Ní àkọkọ ná, Bíbélì fihàn kedere wípé àwọn ẹni tí a kò ràpadà yóò máa gbé inú ọ̀run-àpáàdì títí láí. Ọ̀rọ̀ Jésù tìkalára rẹ jẹ́rìsí wípé àkókò tí àwọn ẹni ìràpadà yóò lò ní ọrun yóò pẹ́ bíi iye ìgbà tí àwọn ẹni tí a kò ràpadà yóò fi gbé ní ọ̀run-àpáàdì. Matteu 25:46, sọ wípé "Lẹ́hìn náà àwọn [ẹni tí kò di ẹni ìgbàlà] wọn ó lọ sí ìjìyà ayérayé, ṣùgbọ́n olódodo sí ìyè ayérayé." Gẹ́gẹ́ bíí ẹsẹ̀ yìí, ìjìyà ẹni tí a kò gbàlà yóò jẹ fún ayérayé bí ìgbé-ayé tí olódodo. Àwọn kan gbàgbọ wípé àwọn tí ó wà nínú ọ̀run-àpáàdí náà ní kò ní sí mọ́, ṣùgbọn Olúwa tìkalára rẹ jẹ́rì si wípé yóò wà fún títí láíláí. Matteu 25:41 àti Marku 9:44 ṣe àpéjúwe ''iná ayérayé'' àti ''íná tí kò lè kú."

Báwo ni ènìyàn ṣe lè yẹra fún íná tí kò lè kú yìí? Ọpọlọpọ ènìyàn ni ó gbàgbọ́ wípé gbogbo àwọn ọ̀nà—gbogbo ẹsìn àti ìgbàgbọ́—ní o darí sí ọrun, tàbí kí wọn lérò wípé síbẹ Ọlọ́run kún fún ìfẹ̀ àti àánú àti wípé yóò jẹ́ kí gbogbo ènìyàn wọ ọ̀run. Ní òtítọ́ Ọlọrun kún fún ìfẹ àti àánú; àti wípé àwọn àmúyẹ wọ̀nyìí ní ó mú kí Òun rán Ọmọ Rẹ Ọkùnrin, Jésù Krístì, wá sí ayé láti kú lórí àgbélébùú fún wa. Jésù Kristi jẹ àpaapọ ìlẹkùn tí ó já sí ayérayé ní ọrun. Ìṣe àwọn àpọstélì 4:12 sọ wípé, "Ìgbàlà ni a kò lè rí nínú elòmíràn, nítorí kò sí orúkọ kan lábẹ ọrun tí a fi fún àwọn èniyàn nípa èyí tí a lè fi ní ìgbalà." "Ọlọrun kan àti olùbálàjà kan ló wà láàrín Ọlọrun àti ènìyàn, ọkùnrin náà Krístì Jésù" (1 Timoteu 2:5). Nínú Johannu 14:6, Jésù sọ wípé, "Èmi ni ọnà òtítọ àti ìyè náà. Kò sí ẹni tí ó lè wá sọdọ Baba bíkòṣe nípasẹ mi." Johannu 3:16 "Nítorí Ọlọ́run fẹ́ aráyé tó bẹ́ẹ̀ gẹ́, tí ó fi Ọmọ bíbí Rẹ̀ kansọsọ fúnni, kí ẹnikẹ́ni tí ó ba gbàá gbọ́ má ba ṣègbé, ṣùgbọ́n kí ó lè ní ìyè àínìpẹkun." Bí a bá yan láti kọ Ọmọ Ọlọrun, a kò ní lè bá àwọn àmúyẹ fún ìgbàlà pàdé (Johannu 3:16, 18, 36).

Pẹlú irú àwọn ẹsẹ̀ wọ̀nyìí, ó hàn kedere wípé ẹ̀kọ́ nípa ìgbàlà gbogbo àgbáyé àti ìgbàlà ti gbogbo àgbáye jẹ àwọn ìgbàgbọ tí kò bá bíbélì mu. Ẹ̀kọ́ nípa ìgbàlà gbogbo àgbáyé takò ní tààrà ohun tí Ìwé mímọ ńkọni. Nígbàtí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ńfẹ̀sùn kan àwọn Kristiẹni wípé wọn jẹ àláìní-ìpamọ́ra àti ''àkótán,'' ó ṣe pàtàkì láti rántí wípé àwọn wọ̀nyìí jẹ ọrọ ti Kristi Tìkalárarẹ. Àwọn Kristiẹni wọn kò ṣe àgbékalẹ àwọn èrò wọ̀nyìí fún ara wọn; Àwọn Kristiẹni kàn ńsọ ní kúkurú ohun tí Olúwa ti sọ tẹ́lẹ̀. Àwọn ènìyàn yàn láti kọ ọ̀rọ̀ náà nítorí wọn kò fẹ fí ojú gba ẹ̀ṣẹ̀ wọn kí wọn gbà wípé àwọn nílò Olúwa láti gbà wọn là. Láti sọ wípé àwọn tí ó kọ ìpèsè ìgbàlà Ọlọrun nípasẹ̀ ti Ọmọ Rẹ ní a ó gbàlà jẹ láti yẹpẹrẹ ìwà mímọ àti ìdájọ òdodo Ọlọrun kí a si ṣe lòdì sí ìnílò ti ìrúbọ ti Jésù ní orúkọ wa.

EnglishPada si oju ewe Yorùbá

Ṣé ẹ̀kọ́ nípa ìgbàlà gbogbo àgbáyé/ìgbàlà ti gbogbo àgbáye bá Bíbélì mu?
Pin oju-iwe yii: Facebook icon Twitter icon Pinterest icon Email icon
© Copyright Got Questions Ministries