settings icon
share icon
Ibeere

Kínni ẹ̀kọ́ nípa bíi Ọlọ́run ṣe ńfi ara Rẹ̀ hàn ní sáà kọ̀ọ̀kan àti wípé ṣé ó bá Bíbélì mu?

Idahun


Ẹ̀kọ́ nípa bíi Ọlọ́run ṣe ńfi ara Rẹ̀ hàn ní sáà kọ̀ọ̀kan ni ọ̀nà tí a fi lè to nǹkan—ìṣàkóso, ètò tàbí ṣíṣàkóso. Nínú ẹ̀kọ́ nípa Ọlọ́run, sáà kọ̀ọ̀kan ni ìṣàkóso láti òkè wá fún ìgbà kan; sáà kọ̀ọ̀kan jẹ́ àkókò tí a ti yan láti òkè wá. Ẹ̀kọ́ nípa bíi Ọlọ́run ṣe ńfi ara Rẹ̀ hàn ní sáà kọ̀ọ̀kan jẹ́ ètò ẹ̀kọ́ nípa Ọlọ́run tí ó dá àwọn ìgbà tí Ọlọ́run ti yàn láti ṣe àkóso ayé mọ̀. Ẹ̀kọ́ nípa bíi Ọlọ́run ṣe ńfi ara Rẹ̀ hàn ní sáà kọ̀ọ̀kan ní ìyàtọ̀ méjì tó gbilẹ̀: 1) ìtumọ̀ ìwé mímọ́ lọ́nà tó wà lẹ́sẹẹsẹ, ní pàtàkì àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì, àti 2) àfojúsùn pé Isrẹli yàtọ̀ sí ìjọ nínú ètò Ọlọ́run. Ẹ̀kọ́ nípa bíi Ọlọ́run ṣe ńfi ara Rẹ̀ hàn ní sáà kọ̀ọ̀kan ti ìgbàlódé tọ́ka sí wípé sáà méje ló wà nínú ètò Ọlọ́run fún ènìyàn.

Àwọn tí ó gbàgbọ́ nínú ẹ̀kọ́ nípa bíi Ọlọ́run ṣe ńfi ara Rẹ̀ hàn ní sáà kọ̀ọ̀kan rọ̀mọ́ ìtumọ̀ Bíbélì ní ọ̀nà aminiọ́tìkì tí ó dára jù. Ìtumọ̀ fún ọ̀rọ̀ kọ̀ọ̀kan ní ìtumọ̀ tí ó ní, ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà, ìtumọ̀ tí yóò ní gẹ́gẹ́ bí a tí ńlòó l'ójojúmọ́. Bẹ́ẹ̀ sì ni a fi ààyè sílẹ̀ fún àmìn, àkànlò èdè, àti àfiwé. Ó yé wa wípé àmìn àti àkànlò èdè ní ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ fún ọ̀rọ̀ tí ó so mọ́ wọn. Nítorí náà, fún àpẹẹrẹ, ní ìgbà tí Bíbélì bá sọ nípa "ẹgbẹ̀rún ọdún" nínú ìwé Ifihan 20, àwọn tí ó gbàgbọ́ nínú ẹ̀kọ́ nípa bíi Ọlọ́run ṣe fi ara Rẹ̀ hàn ní sáà kọ̀ọ̀kan túmọ̀ rẹ̀ sí ẹgbẹ̀rún ọdún ní pàtó (àkókò ìjọba náà), nítorí wípé kò sí idí tí ó ṣe kókó tí a gbọ́dọ̀ fi túmọ̀ rẹ̀ l'ọ́nà míràn.

Ó kéré jù, àwọn ìdí méji tí títúmọ̀ lóréfèé fi jẹ́ ọ̀nà tí ó dára jù láti fi wo Ìwé Mímọ́. Àkọ́kọ́, èrèdí èdè tìkalára rẹ̀ nílò wípé kí á ṣe ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ l'ọ́nà tí ìtumọ̀ rẹ̀ kò ní yàtọ̀ sí bí a ṣe ńlòó l'ójojúmọ́. Ọlọ́run fún wa ní èdè fún ète ìbáraẹnisọ̀rọ̀. Ọ̀rọ̀ jẹ́ ohun-èlò fún ìtumọ̀. Ìdí kejì bá Bíbélì mu. Gbogbo àsọtẹ́lẹ̀ nípa Jésù Kristi nínú Májẹ̀mú Láíláí wá sí ìmúṣẹ gẹ́lẹ́ bẹ́ẹ̀. Bíbí Jésù, iṣẹ́ ìránṣẹ́ rẹ̀, ikú àti àjíǹde Jésù ṣẹlẹ̀ gẹ́gẹ́ gẹ́lẹ́ bí Májẹ̀mú Láíláí ti sọ tẹ́lẹ̀. Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ náà jẹ́ ọ̀rọ̀ tí ó rí bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́. Kò sí ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ nípa Mesiah ninú Májẹ̀mú Titun tí kìí ṣe gẹ́gẹ́ bí a ṣe kọ́ sílẹ̀ gẹ́lẹ́. Èyí kín ọ̀nà ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ fún ọ̀rọ̀ lẹ́yìn gan-an. Bí a kò bá máa ṣe ítumọ̀ Ìwé Mímọ́ pẹ̀lú ọ̀rọ̀ fún ọ̀rọ̀, kò lè sí ìpìlẹ̀ tí ó péye láti ní òye Bíbélì. Oníkálùkù ènìyàn yóò le túmọ̀ Bíbélì bí ó ṣe ri wípé ó yẹ. Ìtumọ̀ Bíbélì yóò di "ohun tí àyọkà yìí sọ fún mi" dípò "Bíbélì sọ wípé". Ó ṣe ni láàánú wípé, èyí ni àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí à ńrí nínú ohun tí à ńpè ní ẹ̀kọ́ Bíbélì lónìí.

Ẹ̀kọ́ nípa Ọlọ́run ni ẹ̀kọ́ nípa bíi Ọlọ́run ṣe ńfi ara Rẹ̀ hàn ní sáà kọ̀ọ̀kan kọ́ wa wípé àwọn ènìyàn Ọlọ́run tí ó yàtọ̀ méjì ló wà: Isrẹli àti Ìjọ. Àwọn oní ẹ̀kọ́ nípa bíi Ọlọ́run ṣe ńfi ara Rẹ̀ hàn ní sáà kọ̀ọ̀kan gbàgbọ́ wípé ìgbàla nígbà gbogbo jẹ́ nípa ore-ọ̀fẹ́ nípasẹ̀ ìgbàgbọ́—nínú Ọlọ́run ní Májẹ̀mú Láíláí àti ní pàtó nínú Ọlọ́run ọmọ ní Májẹ̀mú Titun. Àwọn oní ẹ̀kọ́ nípa bíi Ọlọ́run ṣe fi ara Rẹ̀ hàn ní sáà kọ̀ọ̀kan gbà wípé ìjọ kò tíì rọ́pò Isrẹli nínú ètò Ọlọ́run, àti wípé a kò tíì kó àwọn ìlérí májẹ̀mú Láíláí fún Ìjọ. Ẹ̀kọ́ nípa bíi Ọlọ́run ṣe ńfi ara Rẹ̀ hàn ní sáà kọ̀ọ̀kan kọ́ wa wípé ìlérí tí Ọlọ́run ṣe fún Isrẹli nínú Májẹ̀mú Láíláí (ilẹ̀, ọmọ púpọ àti ìbùkún) yóo wá sí ìmuṣe nígbẹ̀yìn ní ẹgbẹ̀rún ọdún tí Ifihan 20 sọ nípa. Àwọn oní ẹ̀kọ́ nípa bíi Ọlọ́run ṣe fi ara Rẹ̀ hàn ní sáà kọ̀ọ̀kan gbàgbọ́ wípé, gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run ṣe ntẹjú mọ́ ìjọ ní òní, yóo sì tún tẹjú mọ́ Isrẹli ní ọjọ́-ọ̀la (wo Romu 9-11 àti Daniẹli 9:24).

Àwọn oní ẹ̀kọ́ nípa bíi Ọlọ́run ṣe ńfi ara Rẹ̀ hàn ní sáà kọ̀ọ̀kan ní òyè pé a to Bíbélì sí méje: Àìlẹ́ṣẹ̀ (Jẹnẹsisi 1:1—3:7), Ẹ̀rí ọkàn (Jẹnẹsisi 3:8—8:22), Ìjọba Ènìyàn (Jẹnẹsisi 9:1—11:32), Ìlérí (Jẹnẹsisi 12:1— Ẹksodu 19:25), Òfin (Ẹksodu 20:1— Iṣe àwọn Apọsteli 2:4 2:4), Ore-ọ̀fẹ́ (Iṣe àwọn Apọsteli 2:4—Ìfihàn 20:3), àti ìjọba Ẹgbẹ̀rún ọdún (Ifihan20:4–6). Lẹ́ẹ̀kansi, àwọn ẹ̀kọ́ nípa bíi Ọlọ́run ṣe ńfi ara Rẹ̀ hàn ní sáà kọ̀ọ̀kan yìí kìí ṣe ipasẹ̀ sí ìgbàlà, ṣùgbọ́n ọ̀nà tí Ọlọ́run fi bá ènìyàn ṣe pọ̀. Sáà kọ̀ọ̀kan nííṣe pẹ̀lú dídá àgbékalẹ̀ bí Ọlọ́run tí ńṣiṣẹ́ pẹ́lú àwọn ènìyàn tí ńgbé nínú sáà náà mọ̀. Àgbékalẹ̀ náà jẹ́ 1) ojúṣe, 2) ìkùnà, 3) ìdájọ́, àti 4) ore-ọ̀fẹ́ láti tẹ̀síwájú.

Ẹ̀kọ́ nípa bíi Ọlọ́run ṣe ńfi ara Rẹ̀ hàn ní sáà kọ̀ọ̀kan, gẹ́gẹ́ bí ètò, já sì ìtumọ̀ àkókò tí ó ṣíwájú ẹgbẹ̀rún ọdún ti ìpadàbọ́ Jésù Kristi kejì àti ti ìtumọ̀ àkókò tí ó ṣíwájú ìgbà ìpọ́njú ti ìgbàsókè. Ní akótán, ẹ̀kọ́ nípa bíi Ọlọ́run ṣe ńfi ara Rẹ̀ hàn ní sáà kọ̀ọ̀kan jẹ́ ètò ẹ̀ka nípa Ọlọ́run tí ó tẹnumọ́ wípé ìtumọ̀ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì jẹ́ ọ̀rọ̀ fún ọ̀rọ, tí ó dá ìyàtọ̀ tó wà láàrin Ísírẹ́lì àti Ìjọ mọ̀, àti tí ó to Bíbélì sí sáà tàbí ètò ìṣàkóso ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀.

EnglishPada si oju ewe Yorùbá

Kínni ẹ̀kọ́ nípa bíi Ọlọ́run ṣe ńfi ara Rẹ̀ hàn ní sáà kọ̀ọ̀kan àti wípé ṣé ó bá Bíbélì mu?
Pin oju-iwe yii: Facebook icon Twitter icon Pinterest icon Email icon
© Copyright Got Questions Ministries