settings icon
share icon
Ibeere

Báwo ni mo ṣe lè mọ ẹ̀bùn ẹ̀mí mi?

Idahun


Kò sí idán tàbí àyẹ̀wò kan gbòógì tí ó lè sọ ohun tí ẹ̀bùn ẹ̀mí wa jẹ́ ní pàtó. Ẹ̀mí Mímọ́ ló ńpín ẹ̀bùn bí Òun bá ti pinnu (1 Kọrinti 12:7-11). Ìṣòro kan tí ó wọ́pọ̀ pẹ̀lú àwa Kristiẹni ni ìdánwò láti rò wípé iṣẹ́ ẹ̀sìn wa sí Ọlọ́run gbọ́dọ̀ wà ní ìlànà pẹ̀lú ẹ̀bùn ẹ̀mí tí a rò wípé a ní. Ìyẹn kìí ṣe ọ̀nà tí ẹ̀bùn ẹ̀mí ńgbà ṣiṣẹ́. Ọlọ́run ńpè wá láti jọ́sìn sí Òun nínú ohun gbogbo pẹ̀lú ìgbọràn. Òun yóò ró wa l'ágbára pẹ̀lú ẹ̀bùn èyíkéyìí tí a nílò láti ṣe àṣeyọrí nínú iṣẹ́ tí Òun pè wá sí.

Dídá ẹ̀bùn ẹ̀mí wa mọ̀ ṣeé ṣe ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀nà. Dídán ẹ̀bùn tàbí awọn àkójọ ẹ̀bùn wò, bí ó tilẹ̀ jẹ́ wípé kò ṣée gbé gbogbo ara lé, ó sì lè rànwálọ́wọ́ láti ní òye ibi ti ẹ̀bùn wa lè wà. Ìjẹ́rísí àwọn ẹlòmíìràn nàá le tan ìmọ́lẹ̀ sí ohun tí ẹ̀bùn ẹ̀mí wa jẹ́. Àwọn ẹlòmìràn tí wọ́n ńrí wa bí a tí ńsin Olúwa ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà le dá ẹ̀bùn ẹ̀mí tí a ńlò mọ̀, èyí tí a lè má mọ̀ tàbí kọ bi ara sí. Àdúrà nàá ṣe pàtàkì. Ẹnìkan tí ó mọ ní pàtó gẹ́gẹ́ bí a ṣe ní ẹ̀bùn ẹ̀mí sí ni Olùfi-ẹ̀bùn fúnni tìkalárarẹ̀—à ní Ẹ̀mí Mímọ́. A lè béèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run kí ó fi irú ẹ̀bùn tí a ní hàn wá, kí àwa ba lè lo ẹ̀bùn ẹ̀mí wa dáradára fún ògo Rẹ̀.

Bẹ́ẹ̀ni, Ọlọ́run pe àwọn kan láti jẹ́ olùkọ́, tí ó sì fún wọn ní ẹ̀bùn ìkọ́ni. Ọlọ́run pe àwọn kan láti jẹ́ ìráńṣẹ́, ó sì bùkún wọn pẹ̀lú ẹ̀bùn ìranilọ́wọ́. Àmọ́, mímọ ẹ̀bùn ẹ̀mí wa, kò yọ wá sílẹ̀ láti má ṣe sin Ọlọ́run ní àwọn ọ̀nà tí ó yàtọ̀ si ẹ̀bùn wa. Ǹjẹ́ ó ṣe ni l'áńfààní láti mọ (àwọn) ẹ̀bùn ẹ̀mí tí Ọlọ́run fún wa? Bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́ ni ó rí. Ṣé ó burú láti gbájúmọ́ ẹ̀bùn ẹ̀mí tó bẹ́ẹ̀ tí a pàdánù ore-ọ̀fẹ́ míìrán láti sin Ọlọ́run? Bẹ́ẹ̀ni. Bí a bá fi ara wa jìn fún lìlò Ọlọ́run, Òun yóò ró wa l'ágbára pẹ̀lú ẹ̀bùn ẹ̀mí tí a nílò.

English



Pada si oju ewe Yorùbá

Báwo ni mo ṣe lè mọ ẹ̀bùn ẹ̀mí mi?
Pin oju-iwe yii: Facebook icon Twitter icon Pinterest icon Email icon
© Copyright Got Questions Ministries