settings icon
share icon
Ibeere

Dáríji àwọn ẹlòmíràn ìdáríjì?

Idahun


Gbogbo ènìyàn ni a ti ṣẹ̀ sí, ṣe àiṣédédé sí, tí a sì ti ṣe lòdì sí ní ìgbà kan. Báwo ni ó ṣe yẹ kí àwọn Kristiẹni ṣe nígbàtí a bá ṣe àiṣédédé lòdì sí wọn? Gẹ́gẹ́ bíi Bíbélì, àwa gbọ́dọ̀ dáríji àwọn ẹlòmíràn. Ìwé Efesu 4:32 sọ wípé, "Ẹ máa ṣore fun ọmọnikeji yin, ẹ ni ìyọ́nú, ẹ máa dariji ara yin, gẹgẹ bi Ọlọ́run ninu Kristi ti dariji yin." Bákànnáà, Kolosse 3:13 wípé, ""Ẹ máa farada a fun ara yin, ẹ si máa daraji ara yin bi ẹnikẹni bá ni ẹ̀sùn si ẹnikan: bi Kristi ti dariji ara yin, gẹgẹ bẹ́ẹ̀ni ki ẹyin ki o máa ṣe pẹ̀lú. Kókó nínú àwọn Ìwé Mímọ́ méjèèjí náà ni wípé àwa ní láti dáríji àwọn onígbàgbọ́ wa bí Ọlọ́run ti dáríjì wá. Kínni ìdí tí a fi ńdáríjì? Nítorí a ti dáríjì wá! Ìdáríjì àwọn ẹlòmíràn wa gbọ́dọ̀ fi ìdáríjì Ọlọ́run fún wa hàn.

Fún wa láti dáríji àwọn tí ó ṣe sí wa, àwa gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ ní òye ìdáríjì ti Ọlọ́run. Ọlọ́run kìí dédé dáríjì gbogbo ènìyàn láìṣe ohun kankan láìní àwọn àmúye kan—bí Òun ba ṣe bẹ́ẹ̀, kò ní sí adágún iná ni Ifihan 20:14-15. Ìdáríjì, bí a bá ní òye rẹ̀ dáradára, ní ìrònúpìwàdà bíi ìpín ti ẹlẹ́ṣẹ́ẹ̀ àti ìfẹ́ àti ore-ọ̀fẹ́ ní ìpín ti Ọlọ́run. Ìfẹ́ àti ore-ọ̀fẹ́ wà níbẹ̀, ṣùgbọ́n ìrònípìwàdà ní ọ̀pọ̀ ìgbà kìí sí. Nítorí náà, àṣẹ Bíbélì fún wa láti dáríji àwọn ẹlòmíràn kò túmọ sí wípé kí a fo ẹ̀ṣẹ̀ ru. Ó túmọ̀ sí wípé kí a na ọwọ́ ìdáríjì sí àwọn tí ó ronúpìwàdà tayọ̀tayọ̀, pẹ̀lú ore-ọ̀fẹ́, àti tìfẹ́tìfẹ́. Àwa máa ńṣetán láti dáríjì nígbàgbogbo bí a bá ní ànfààní. Kìí kan ṣe ìgbà méje, ṣùgbọ́n "àádọ́rin méje" (Matteu 18:22) Kíkọ̀ láti dáríji ẹnìkan tí ó bèrè fun ńfi ìkórira, àrankàn, àti ìbínú hàn, èyí tí kìí ṣe àwọn àmúyẹ Kristiẹni tòótọ́.

Láti dáríji àwọn tí ó ṣe wá nílò sùúrù àti ìpamọ́ra. Ìjọ ní àṣẹ láti "ẹ máa mú sùúrù fún gbogbo enia"(1 Tẹssalonika 5:14). Ó yẹ kí a le fojú fò àwọn àṣiṣe ti ara ẹni díẹ̀ tàbí tí kò tó nǹkan dá. Jésù wípé, "Ṣugbọn ẹnikẹni ti o ba gbá ọ li ẹ̀rẹ̀kẹ́ ọ̀tun, yi ti òsì si i pẹlu" (Matteu 5:39). Kìí ṣe gbogbo "ìgbájú" ni o nílò èsì.

Láti dáríji àwọn tí ó ṣẹ̀ wá nílò agbára Ọlọ́run tí ó ńyínipadà nínú ayé wa. Nǹkankan wà nínú àbùdá ènìyàn tí ó ti ṣubú tí ó ńpòǹgbẹ fún ẹ̀san tí ó sì tini láti gbẹ̀san. Àwa máa ńfẹ́ fi irú ibi kańnàá fún àwọn ti o ṣe wá níbi—ojú fún ojú jọ ohun tí ó tọ́. Ṣùgbọ́n, nínú Kristi, a ti fún wa ni agbára láti nífẹ̀ẹ́ àwọn ọ̀tá wa, ṣe rere fún àwọn oní-ìkórira, bùkún àwọn tí ó ṣe èpè, kí a si gbàdúrà fún àwọn tí ó ńlò ni ní ìlòkulò (wo Luku 6:27-28). Jésù fún wa ní ọkàn tí ó ńfẹ́ láti dáríjì tí yóò si ṣiṣẹ́ láti rí èyí.

Dídáríji àwọn tí ó ṣẹ̀ wá ni a mú rọrùn nígbàtí a bá wo ìpele bí Ọlọ́run ti ṣe dárí àwọn àìṣedédé wa jì wá. Àwa tí a ti fún ni ore-ọ̀fẹ́ kò ní ẹ̀tọ́ láti ma fi ore-ọ̀fẹ́ hàn fún àwọn ẹlòmíràn. Àwa ti ṣẹ̀ sí Ọlọ́run láìlópin ju bí ẹnikẹ́ni ṣe lè ṣẹ sí wa lọ. Òwe Jésù ni Matteu 18:23-35 jẹ́ àpẹẹrẹ òtítọ́ yìí.

Ọlọ́run ṣe ìlérí wípé, nígbàtí àwa ba tọ Òun wa fún ìdáríjì, Òun ńfún wa lọ́fẹ̀ẹ́ (1 Johannu 1:9). Ìpele ore-ọ̀fẹ́ tí a ba nà sí àwọn tí ó ńwá ìdáríjì wa náà yóò wà fún wa (Luku 17:3-4).

English



Pada si oju ewe Yorùbá

Dáríji àwọn ẹlòmíràn ìdáríjì?
Pin oju-iwe yii: Facebook icon Twitter icon Pinterest icon Email icon
© Copyright Got Questions Ministries