settings icon
share icon
Ibeere

Báwo ni mo ṣe lè mọ̀ bí nǹkan bá jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀?

Idahun


Nǹkan méjì ló wà nínú ìbéèrè yìí, ohun tí Bíbélì mẹ́nubà ní pàtó tí ó si pé ní ẹ̀ṣẹ̀ àti ohun tí Bíbélì kò sọ tààrà. Àkójọ oríṣi ẹ̀ṣẹ̀ nínú Ìwé Mímọ́ ni ìwọ̀nyìí Owe 6:16-19, Galatia 5:19-21, àti Kọrinti kínní 6:9-10. Kò lè sí iyèméjì wípé àwọn ẹsẹ̀ àyọkà yìí ṣe àfihàn àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ náà gẹ́gẹ́ bí ẹ̀ṣẹ̀, àwọn ohun tí Ọlọ́run kò f'ọwọ́ sí. Ìpànìyàn, àgbèrè, irọ́, olè jíjà, abbl.—kò sí iyèméjì, Bíbélì ṣe àfihàn àwọn nǹkan wọ̀nyìí gẹ́gẹ́ bí ẹ̀ṣẹ̀. Ohun tí ó le jù ni mímọ ohun tí ó jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ ní àwọn ibi tí Bíbélì kò ti sọ tààrà. Nígbàtí Bíbélì kò bá tíì sọ̀rọ̀ nípa ohun kan, àwa ní ìlànà gbogbogbò nínú Ọ̀rọ̀ Rẹ̀ láti tọ́ wa.

Àkọ́kọ́, tí kò bá sí ìtọ́kàa ẹsẹ̀ Bíbélì ní pàtó, yóò dára làti bèèrè kìí ṣe nígbàtí nǹkan kìí bá yẹ, ṣùgbọ́n, tí ó bá dára bákannáà. Bíbélì sọ, fún àpẹẹrẹ, wípé a ní láti "máa ṣe ìràpadà ìgbà" (Kolosse 4:5). Ìwọ̀nba ọjọ́ wa ní ayé kéré ó sì ní iye lórí ní ìbáámu pẹ̀lú ayérayé wípé a kò nílò làti fi àkókò wa ṣòfò lórí àwọn nǹkan ara, ṣùgbọ́n kí á lòó lórí "ohun tí ó dára fún ẹ̀kọ́ kí ó le máa fi ore-ọ̀fẹ́ fún àwọn tí ń gbọ́" nìkan (Efesu 4:29).

Àyẹ̀wò dídára ni láti mọ̀ bóyá l'óòtítọ́, pẹ̀lú ẹ̀rí ọkàn, a lè bèèrè wípé kí Ọlọ́run bùkún kí Òun sì lo ìṣẹ̀lẹ̀ kan ní pàtó fún ète dídára Rẹ̀. "Nítorínà bí ẹ̀yin bá ń jẹ, tábí bí ẹ̀yin bá ń mu, tàbí ohunkóhun tí ẹ̀yín bá ń se, ẹ máa se gbogbo wọn fún ògo Ọlọ́run" (1 Kọrinti 10:31). Bí àyè fún iyèméjì bá wà wípé bóyá inú Ọlọ́run dùn sii, ohun tí ó dára jù ni kí á gba kámú. "Ohunkóhun tí kò ti inú ìgbàgbọ́ wá, ẹ̀ṣẹ̀ ni" (Romu 14:23). A nílò láti ráńtí wípé ara wa, àti ọkàn wa, ti di ìràpadà ó sì jẹ́ ti Ọlọ́run. "Tàbí, ẹ̀yin kò mọ̀ pé ara yín ni tẹ́mpìlì Ẹ̀mí Mímọ́, tí ńbẹ nínú yín, tí ẹ̀yin ti gbà lọ́wọ́ Ọlọ́run? Ẹ̀yin kì sí ì ṣe ti ara yín; nítorí a ti rà yín ní iye kan. Nítorínà ẹ yin Ọlọ́run lógo nínú ara yín" (1 Kọrinti 6:19-20). Òtítọ́ ńlá yìí ni àtìlẹyìn gidi lórí ohun tí a ṣe àti ibi tí a lọ.

Ní àfikún, a gbọ́dọ̀ ṣe àgbéyẹ̀wò àwọn ìṣe wa kìí ṣe ní ìbáamu pẹ̀lú Ọlọ́run nìkan, ṣùgbọ́n ní ìbáamu pẹ̀lú ipa wọn lórí ìdílé wa, àwọn ọ̀rẹ́ wa, àti àwọn ènìyàn lápapọ̀ pẹ̀lú. Kódà tí ohun kan pàtó kò bá pa wá lára, tí ó bà sì fa ìpalára fún ẹlòmíràn, ẹ̀ṣẹ̀ ni. "Ó dára kí á má tilẹ̀ jẹ ẹran, kí á má mu wáìnì, àti ohun kan nípa èyí tí arákùnrin rẹ̀ yóò kọsẹ̀....Àwa tí ó lera ìbá máa ru ẹrù àìlera àwọn aláìlera, kí a mà sì se ohun tí ó wu ara wa" (Romu 14:21; 15:1).

Ní àkótán, ráńtí wípé Jésù Kristi ni Olúwa àti Olùgbàlà wa, àti wípé a kò ní gba nǹkan míìrán láàyè láti borí ìtẹ̀lé àṣẹ Rẹ̀. A kò lè gba ìwà tàbi èrè tàbi àfojúsùn kankan láàyè láti ní àṣẹ àìtọ́ lórí ayé wa; Kristi nìkan ló ní àṣẹ yẹn. "Ohun gbogbo ni ó yẹ fún mi—ṣùgbọ́n kìí ṣe ohun gbogbo ni ó ní èrè. Ohun gbogbo ni ó yẹ fún mi—ṣùgbọ́n èmi kì yóò jẹ́ kí á fi mí sábẹ́ agbára ohunkóhun" (1 Kọrinti 6:12). "Ohunkóhun tí ẹ̀yin bá sì ńse ní ọ̀rọ̀ tàbí ní ìse, ẹ máa se gbogbo wọn ní orúkọ Jésù Olúwa, ẹ máa fi ọpẹ́ fún Ọlọ́run Bàba nípasẹ̀ ẹ rẹ̀" (Kolosse 3:17).

EnglishPada si oju ewe Yorùbá

Báwo ni mo ṣe lè mọ̀ bí nǹkan bá jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀?
Pin oju-iwe yii: Facebook icon Twitter icon Pinterest icon Email icon
© Copyright Got Questions Ministries