settings icon
share icon
Ibeere

Kínni Bíbélì sọ nípa ìjìyà ikú/ìjìyà nípa pípàyàn?

Idahun


Òfin Májẹ̀mú Láíláí pàṣẹ ìjìyàà ikú fún onírúurú ìṣe: ìpànìyàn (Ẹ́ksódù 21:12), jíjí ọmọ gbé (Ẹksodu 21:16), bíbá ẹranko dàpọ̀ (Ẹ́ksódù 21:19), panságà; (Léfítíkù 20:10), ìbálòpọ̀ ọkùnrin sí ọkùnrin (Lẹfitiku 20:13), jíjẹ́ wòlí èké (Deutarọnọmi 13:5), aṣẹ́wó àti ìfípábáẹnilòpọ̀ (Deutarọnọmi 22:4), àti onírúurú ọ̀ràn míìrán. Ṣùgbọ́n, Ọlọ́run máa ńfi àánú hàn lọ́pọ̀ ìgbà tí ìjìyà ikú bá yẹ. Dáfídì dá ẹ̀ṣẹ̀ panságà àti ìpànìyàn, síbẹ̀ Ọlọ́run kò bèrè wípé kí á mú ẹ̀mí rẹ̀ kúrò (2 Samuẹli 11:1-5, 14-17; 2 Samuẹli 12:13). Ní ìkẹhìn, gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ tí a bá dá yẹ kó jásí ìjìyà ikú nítorí wípé ikú ni èrè ẹ̀ṣẹ̀ (Romu 6:23). Ní ìmore, Ọlọ́run fi ìfẹ́ Rẹ̀ hàn sí wa nípa wípé kò dáwa lẹ́bí (Romu 5:8).

Nígbà tí àwọn Farisí mú obìnrin tí wọ́n gbámú nínú ìṣe àgbèrè lọ sí ọ̀dọ̀ Jésù, tí wọ́n sì bi Í lérè bóyá àwọn lè sọọ́ ní òkúta pa, Jésù sì dáhùn wípé, "ẹnití ó bá ṣe àìlẹ́ṣẹ̀ nínú nyín, jẹ́ kí o kọ́ sọ òkúta lù ú"(Johannu 8:7). A kò gbọ́dọ̀ lo èyí láti fi tùmọ̀ wípé Jésù tako ìjìyà ikú nínú gbogbo ìṣẹ̀lẹ̀. Jésù kàn ńfi àgàbàgebè àwọn Farisí han ni. Àwọn Farisí fẹ́ fi ẹ̀tàn mú Jésù rú òfin Májẹ̀mú Láíláí; wọn kò tilẹ̀ bìkítà bí a bá sọ obìnrin náà ní òkúta pa ní tòótọ́ (níbo ni ọkùnrin tí wọ́n gbámú lẹ́nu àgbèrè náà wà?) Ọlọ́run fún ra Rẹ̀ ni ó pilẹ̀ ìjìyà ikú: "Ẹnikẹ́ni tí ó bá ta ẹ̀jẹ̀ ènìyàn sílẹ̀, láti ọwọ́ ènìyàn li a ó sì ti ta ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ sílẹ̀: nítori pé ní àwòrán Ọlọ́run ni a dá ènìyàn (Jẹnẹsisi 9:6). Jésù lè fàyè gba ìjìyà ikú nínú àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ kan. Jésù tún fi ore-ọ̀fẹ́ hàn nígbà tí ó yẹ kí ìjìyà ikú wà (Johannu 8:1-11). Ó dájú wípé Àpọ́stélì Pọ́ọ̀lù mọ̀ agbára ìjọba láti pilẹ̀ ìjìyà ikú nígbà tí ó bá yẹ (Romu 13:1-7).

Báwo ni ó yẹ kí Kristiẹni wo ìjìyà ikú? Àkọ́kọ́, a gbọ́dọ̀ rántí wípé Ọlọ́run ló dá ìjìyà ikú sílẹ̀ nínú ọ̀rọ̀ Rẹ̀; nítorínáà, yóò jẹ́ àìronújilẹ̀ fún wa láti rò wípé a lè gbé òṣùwọ̀n tí ó gajù kalẹ̀. Ọlọ́run ló ní òṣùwọ̀n tí ó gajù lọ nínú gbogbo ẹ̀dá; Òun pé. Òṣùwọ̀n yìí kò wà fún wa nìkan, ṣùgbọ́n ó wà fún Òun tìkalára Rẹ̀. Nítorí náà, àìlópin ni ìfẹ́ Rẹ̀, bẹ́ẹ̀ni àánú Rẹ̀ kò nípẹ̀kun. Àwa sì tún ri wípé, àìlópin ní ìbínú Rẹ̀, a sì pa gbogbo rẹ̀ mọ́ ní pípé.

Ẹ̀kejì, a gbọ́dọ̀ mọ̀ wípé Ọlọ́run ti fún ìjọba ní àṣẹ láti sọ ìgbà tí ìjìyà ikú bá yẹ ((Jẹnẹsisi 9:6; Romu 13:1-7). Kò bá ìlànà Bíbélì mu láti sọ wípé Ọlọ́run tako ìjìyà ikú nínú gbogbo ìṣẹ̀lẹ̀. Àwọn Kristiẹni kò gbọ́dọ̀ yọ̀ nígbà tí wọ́n bá lo ìjìyà ikú, ṣùgbọ́n nígbà kan náà, Kristiẹni kò gbọ́dọ̀ tako ẹ̀tọ̀ ìjọba láti pa àwọn olùṣe ọ̀pọ̀ iṣẹ́ ibi tó burú jù.

EnglishPada si oju ewe Yorùbá

Kínni Bíbélì sọ nípa ìjìyà ikú/ìjìyà nípa pípàyàn?
Pin oju-iwe yii: Facebook icon Twitter icon Pinterest icon Email icon
© Copyright Got Questions Ministries