settings icon
share icon
Ibeere

Ńjẹ́ Bíbélì fi ààyè gba níní ẹrú?

Idahun


Ó ṣeé ṣe kí á wo níní ẹrú bíi ohun àtijọ́. Ṣugbọ́n, lónìí, ó lé ní ọ̀tà dínlọ́gbọ̀n mílíọ́nù ènìyàn ní àgbáyé tí a fi ńṣe ẹrú: ìfipámúnisìn, ẹrú ìbálòpọ̀, dúkìá tí a jogún, àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ. Gẹ́gẹ́ bíi àwọn ẹni tí a ti ràpadà kúrò nínú okòwò ẹrú ẹ̀ṣẹ̀, àwọn ọmọ lẹ́hìn Jésù Kristi gbọ́dọ̀ jẹ́ aṣíwájú nínú fífi òpin sí níní ẹrú ní àgbáyé lónìí. Ìbéèrè ni wípé, Kílódé tí Bíbélì kò ṣe bu ẹnu àtẹ́ lu níní ẹrú pátápátá? Kílódé tí ó fi dàbí wípé Bíbélì faramọ́ ìṣe níní ẹrú láàrin àwọn ènìyàn?

Bíbélì náà kò bu ẹnu àtẹ́ lu ìṣe níní ẹrú ní pàtó. Ó fún wa ní ìlànà lóri bí a ṣe lè mójútó àwọn ẹrú (Deutarọnọmì 15:12-15; Efesu 6:9; Kolosse 4:1), ṣùgbọ́n kò bu ẹnu àtẹ́ lu ìṣe níní ẹrú ní pàtó. Àwọn míìrán rí bíi wípé Bíbélì fi ààyè gba níní ẹrú lónà yóòwù tí ó jẹ́. Ohun tí kò yé wọn ni wípé, ìyàtọ̀ wà láàrin níní ẹrú ní àsìkò Bíbélì àti èyí tí a rí ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ agbègbè ní àgbáyé fún ọdún díẹ̀ sẹ́yìn. Níní ẹrú nínú Bíbélì kò níí fi ṣe pẹ̀lú ẹ̀yà. A kò kó àwọn ènìyàn lẹ́rú nítorí orílẹ̀ tàbí àwọ̀ ara wọn. Ní àsìkò Bíbélì, ọrọ̀-ajé ni okùnfà níní ẹrú; ó nííṣe pẹ̀lú ipò ní àwùjọ. Àwọn ènìyàn má ńta ara wọn bíi ẹrú bí wọn kò bá lè san gbèsè wọn tàbí pèsè fún ìdílé wọn. Nínú Májẹ̀mu Titun, nígbà míìrán àwọn dókítà, àwọn agbẹjọ́rò, àti àwọn olóṣèlú ma ńjẹ́ ẹrú elòmíràn. Àwọn ènìyàn kan gbà láti jẹ́ ẹrú kí olówó wọn lè máa gbọ́ gbogbo bùkátà wọn.

Níní ẹrú ní ọdún díẹ̀ sẹ́yìn nííṣe pẹ̀lú àwọ̀ ara nìkan. Ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, a rí àwọn ènìyàn aláwọ̀ dúdú gẹ́gẹ́ bíi ẹrú nítorí orílẹ̀-èdè wọn; ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn amúnisìn gbàgbọ́ lóòtọ́ wípé ó kù díẹ̀ káàtó fún àwọn ènìyàn aláwọ̀ dúdú. Bíbélì náà bu ẹnu àtẹ́ lu níní ẹrú nípa ẹ̀yà nítorí ó kọ́ wípé Ọlọ́run ni ó dá gbogbo àwọn ènìyàn ní àwòrán Ara Rẹ̀ (Jẹnẹsisi 1:27). Nígbà kannáà, Májẹ̀mu Láíláí fi ààyè gba níní ẹrú nítorí okòwò, ó sì ṣeé ní ìwọ̀ntuwọnsì. Ohun tí ó ṣe kókó níbẹ̀ ni wípè, níní ẹrú tí Bíbélì fi ààyè gba jọ mọ́ níní ẹrú ẹ̀yà tí ó jẹ́ ìṣòro fún wa ní ọdún díẹ̀ sẹ́yìn.

Ní àfikún, Májẹ̀mu Láíláí àti Titun bu ẹnu àtẹ́ lu iṣẹ́ "ajínigbé," tí ó wọ́pọ̀ ní Ilẹ̀ Adúláwọ̀ ní sẹ́ńtúrì kọkàndínlógún (19th). Àwọn ọmọ Ilẹ̀ Adúláwọ̀ ni àwọn olùwá ẹrú kó, tí wọ́n sì tà wọ́n fún àwọn olókòwò ẹrú, tí wọ́n sì kó wọn lọ sí ilẹ̀ àjèjì fún iṣẹ́ oko. Inú Ọlọ́run kò dùn sí ìṣe yìí. Kódà, ìjìyà fún irú ọ̀ràn bẹ́ẹ̀ ni ikú lábẹ́ Òfin Mòósè: "Ẹniti o ba si ji enia, ti o si tà a, tabi ti a ri i li ọwọ́ rẹ̀, pipa li a o pa a" (Ẹksodu 21:16). Bákan náà, nínú Májẹ̀mu Titun, a ka àwọn olókòwò ẹrú mọ́ àwọn "alaiwa-bi-Ọlọrun ati awọn ẹlẹṣẹ" wọ́n wà ní ìṣọ̀rí kannáà pẹ̀lú awọn apa-baba ati awọn apa-iya, awọn apaniyàn, awọn àgbere, awọn ti nfi ọkunrin ba ara wọn jẹ́, awọn èké àti awọn abura èké (1 Timoteu 1:8-10).

Kókó míìrán tí ó ṣe pàtàkì ni wípé èrèdí Bíbélì ni láti júwe ọ̀nà ìgbàlà, kìí ṣe láti tún àwùjọ ṣe. Bíbélì náà má ńwa ọ̀rọ̀ jinlẹ̀. Bí ènìyàn bá ní ìrírí ìfẹ́ náà, àánú, àti ore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run nípa gbígba ìgbàlà, Ọlọ́run yóò tún ọkàn rẹ̀ ṣe, yóò yí èrò àti ìṣe rẹ̀ padà. Ẹni tí ó bá ti ní ìrírí ẹ̀bun Ọlọ́run nípa ìgbàlà àti òmìnira kúrò lọ́wọ́ ẹrú ẹ̀ṣẹ̀, gẹ́gẹ́ bíi Ọlọ́run ti ńtún ọkàn rẹ̀ ṣe, yóò ri wípé kò dára kí á kó àwọn ẹlòmíràn ní ẹrú. Òun yóò rí, pẹ̀lú Pọ́ọ̀lù, wípé ẹrú lè jẹ́ "arakùnrin nínú Olúwa" (Filimọni 1:16). Ẹni tí ó bá ti ní ìrírí ore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run nítòótọ́ yóò ní ojú àánú sí àwọn ẹlòmíràn. Èyí ni yóò jẹ́ ọ̀nà àbáyọ Bíbélì láti fi òpin sí níní ẹrú.

English



Pada si oju ewe Yorùbá

Ńjẹ́ Bíbélì fi ààyè gba níní ẹrú?
Pin oju-iwe yii: Facebook icon Twitter icon Pinterest icon Email icon
© Copyright Got Questions Ministries