settings icon
share icon
Ibeere

Kínni Bíbélì sọ nípa ẹlẹ́yàmẹyà?

Idahun


Nǹkan àkọ́kọ́ tí ó yẹ kí ó yé wa nípa ọ̀rọ̀ yí ni wípé ìran kan náà ló wà— Ìran ènìyàn. Ọmọ Kọkésíánì, Áfíríkà, Aṣíà, Íńdíà, Áráàbù àti Júù kì ṣe ẹ̀yà tó yàtọ̀. Dípò bẹ́ẹ̀, wọ́n jẹ́ ẹ̀yà ènìyàn tí ó ní àṣà ati èdè kańnáà tí ìran ènìyàn. Gbogbo ènìyàn ló ní àbùdá ara kańnáà (pẹ̀lú ìyàtọ̀ kékeré, tí ó dájú). Ní pàtákì jùlọ, a ṣẹ̀dá gbogbo ènìyàn ní àwòrán àti gẹ́gẹ́ bí ìrí Ọlọ́run (Jẹnẹsisi 1:26-27). Ọlọ́run fẹ́ aráyé tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ tí Ó fi rán Jésù láti fi ẹ̀mí Rẹ̀ lélẹ̀ fún wa (Johannu 3:16). Ọ̀rọ̀ tí ó ńjẹ́ "aráyé" kó gbogbo ẹ̀yà ènìyàn tí ó ní àṣà ati èdè kańnáà pọ̀.

Ọlọ́run kìí ṣe ojúṣáájú tàbí fẹ́ràn ẹnìkan ju ẹlòmíràn lọ (Deutarọnọmi 10:17; Iṣe awọn Apọsteli 10:34; Romu 2:11, Efesu 6:9), bẹ́ẹ̀ sì ni àwa náà kò gbọdọ̀ ṣe. Jakọbu 2:4 ṣe àpèjúwe àwọn tí ó ṣe ojúṣáájù bíi "onídájọ́ tí ó ní èrò búburú." Dípò bẹ́ẹ̀, a ní láti fẹ́ràn ọmọnìkejì wa gẹ́gẹ́ bíi ara wa (Jakọbu 2:8). Nínú Májẹ̀mú Láíláí, Ọlọ́run pín ènìyàn sí "ẹ̀yà" méjì: àwọn Júù àti Kèfèrí. Èròǹgbà Ọlọ́run fún àwọn Júù ni wípé kí wọn jẹ́ ìjọba àlùfáà, kí wọ́n máa jíṣẹ́ fún àwọn orílẹ̀-èdè Kèfèrí. Dípò bẹ́ẹ̀, fún ọ̀pọ̀ ìgbà, àwọn Júù gbéraga nítorí ipò wọn, wọ́n sì kẹ́gàn àwọn Kèfèrí. Jésù fi òpin sí èyí, nípa wíwó ògiri ìkélé tí ńbẹ láàrin palẹ̀ (Efesu 2:14). Gbogbo ẹlẹ́yàmẹyà, ìkórira, àti yíyanisọ́tọ̀ jẹ́ àfojúdi sí iṣẹ́ tí Kristi ṣe lórí àgbelèbú.

Jésù pàṣẹ fún wa wípé kí á fẹ́ràn ọmọnìkejì wa gẹ́gẹ́ bí Òun ṣe fẹ́ràn wa (Johannu 13:34). Bí Ọlọ́run kìí bá ṣe ojúṣàájú, tí ó sì fẹ́ràn wa láìṣe ojúṣàájú, nígbànáà àwa nílò láti fẹ́ràn pẹ̀lú òṣùwọ̀n kańnáà tí ó ga. Jésù kọ́ wa nínú ìwé Matteu 25 wípé ohunkóhun tí a bá ṣe fún ọ̀kan nínú àwọn arákùnrin Òun wọ̀nyìí tí ó kéré jùlọ, a ti ṣe é fún Òun. Bí a bá hùwà pẹ̀lù ẹ̀gàn, à ńhùwà ní ọ̀nà àìtọ́ sí ènìyàn tí a dá ní àwòrán Ọlọ́run; à ńṣe ìpalára fún ẹni tí Ọlọ́run fẹ́ràn, tí Jésù sì kú fún.

Ẹlẹ́yàmẹ̀yà, ní ọ̀nà yòówù tí ó le jẹ́, jẹ́ ìṣòro fún ìran ènìyàn fún ẹgbẹgbẹ̀rún ọdún. Arákùnrin àti arábìnrin ní ẹ̀yà gbogbo, kò yẹ kí ó rí bẹ́ẹ̀. Àwọn tí ó lùgbàdì ẹlẹ́yàmẹ̀yà, ìkórira àti yíyanisọ́tọ̀ nílò láti dáríjì. Ìwé Efesu 4:32 sọ wípé, "Ẹ máa ṣore fun ọmọnikeji yin, ẹ ni ìyọ́nú, ẹ máa dariji ara yin, gẹgẹ bi Ọlọ́run ninu Kristi ti dariji yin." Àwọn tí ó ńṣe ẹlẹ́yàmẹ̀yà lè má yẹ fún ìdáríjì wa, ṣùgbọ́n àwa náà kò yẹ fún ìdáríjì Ọlọ́run. Àwọn tí ó ńṣe ẹlẹ́yàmẹ̀yà, ìkórira àti yíyanisọ́tọ̀ nílò láti ronúpìwàdà. "Ẹ jọ̀wọ́ ara nyín lọ́wọ́ fún Ọlọ́run, bí alààyé kúrò nínú òkú, àti àwọn ẹ̀yà ara nyín bí ohun èlò òdodo fún Ọlọ́run" (Romu 6:13). Kí ìwé Galatia 3:28 wá sí ìmúṣẹ pátápátá, "kò lè sí Júù tàbí Héllénè, ẹrú tàbí òmìnira, ọkùnrin tàbí obìnrin, nítorípé ọ̀kan ni gbogbo yín jẹ́ nínú Kristi Jésù."

English



Pada si oju ewe Yorùbá

Kínni Bíbélì sọ nípa ẹlẹ́yàmẹyà?
Pin oju-iwe yii: Facebook icon Twitter icon Pinterest icon Email icon
© Copyright Got Questions Ministries