settings icon
share icon
Ibeere

Ṣé Bíbélì ní àwọn àṣìṣe, àwọn ohun tí ó takò ra wọn, tàbí àwọn ohun tí ó yàtọ̀ sí ra wọn?

Idahun


Bí a bá ka Bíbélì ní ọkàn kan, láì níi l'ọ́kàn tẹ́lẹ̀ láti wá àwọn àṣìṣe, àwa yóò rìi bíi ìwé tí ó jẹ́ òtítọ́, ṣe déédé, tí ó sì rọrùn láti kà. Bẹ́ẹ̀ni, àwọn àyọkà kan wà tí ó nira. Bẹ́ẹ̀ni, àwọn ẹsẹ́ kan wà tí ó dàbi wípé wọ́n tako ara wọn. Àwa gbọ́dọ̀ ránti wípé oríṣi òǹkọ̀wé tí ó tó ogójì (40) ló kọ Bíbélì fún àkókò bíi ẹgbẹ̀rùn ọdún ó lé ni ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (1500). Ọ̀ǹkọ̀wé kọ̀ọ̀kan kọọ́ pẹ̀lú àrà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, láti àfojúsùn ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, sí àwọn ènìyàn ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, fún ìdí ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. A gbọ́dọ̀ retí àwọn ìyàtọ̀ kékèèké. Ṣùgbọ́n, ìyàtọ̀ kan kìí ṣe àtakò. Yóò jẹ́ àṣìṣe kan nìkan bí kò bá sí ọ̀nà kankan tí a le gbèrò bí àwọn ẹsẹ̀ tàbí àyọkà náà kò bá ṣeé yanjú. Kódà bí kò bà sí ìdáhùn kan báyìí, ìyẹn kò túmọ̀ sí wípé kò sí ìdáhùn rárá. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni o ti rí àṣìṣẹ tí wọ́n ní ó wà nínú Bíbélì ní ìbámu pẹ̀lú ìtàn tàbí ẹ̀kọ́ nípa ilẹ̀-ayé kí á tó wá ríi wípé Bíbélì tọ́ ní kété tí a ṣe àwárí ẹ̀rí àwọn ẹ̀kọ́ ìgbà àtijọ síwájú síi.

À máa ńgba ìbéèrè lórèkóòrè ní ọ̀nà bíi "Ṣ'àlàyé bí àwọn ẹsẹ̀ yìí kò ṣé tako ara wọn" tàbí "Wòó, àṣìṣe kan rèé nínú Bíbélì!" Lóòtọ́, díẹ̀ nínú àwọn ohun tí àwọn ènìyàn ńfàyọ nira láti dáhùn. Ṣùgbọ́n, àríyànjiyàn wa ni wípé ìdahùn tó yanjú tí ó sì mú ọpọlọ dání wá fún gbogbo àtakò àti àṣìṣe tí wọ́n ní ó wà nínú Bíbélì. Àwọn ìwé àti ojú-ìwé lórí ayélujára wà tí wọn ṣe àkójọ "gbogbo àṣìṣe inú Bíbélì" wà. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn máa ńrí ohun ìjà wọn ní àwọn ibi wọ̀nyìí; àwọn kìí rí àṣìṣe tí wọ́n ní ó wà nínú Bíbélì fúnra wọn. Àwọn ìwé àti ojú-ìwé lórí ayélujára tún wà tí ó tako gbogbo àwọn àṣìṣe tí a lérò wọ̀nyìí náà. Ohun tó bani nínú jẹ́ jùlọ ni wípé ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn tí ó ńtako Bíbélì kò n'ìfẹ́ sí ìdáhùn kankan ní òtítọ́. Kódà ọ̀pọ̀ "àwọn alátakò Bíbélì" mọ ìdáhùn wọ̀nyìí, ṣùgbọ́n wọ́n ńtẹ̀síwájú láti máa lo ìtakò àtijọ́ tí ko gbéwọ̀n síwájú àti síwájú síi.

Nítorínáà, kínni ó yẹ kí á ṣe bí ẹnìkan bá gbé ẹ̀sùn àṣìṣe Bíbélì tọ̀ wá wá? Kọ́ ẹ̀kọ́ ọ̀rọ̀ ìwé Mímọ́ pẹ̀lú àdúrà kí ó sì wòó bí ọ̀nà àbáyọ tí ó rọrùn bá wà. 2) Ṣé àwọn ìwádìí kan pẹ̀lú lílo àwọn àsọyé Bíbélì tí ó dára, àwọn ìwé "olùgbèjà Bíbélì", àti àwọn ojú-ìwé ayélujára fún ìwádìí Bíbélì. 3) Bèèrè lọ̀wọ̀ àwọn àlúfà/aládarí ìjọ láti rí bí wọ́n bá le wá ọ̀nà àbáyọ kan. 4) Bí kò bà sí ìdáhùn tí ó já geere lẹ́yìn tí a ti tẹ̀lé àwọn ìgbésẹ̀ 1), 2) àti 3), a gba Ọlọ́run gbọ́ wípé òótọ́ ni ọ̀rọ̀ rẹ̀ àti wípé ọ̀nà àbáyọ kan wà tí a kò tíì rí rí (2 Timoteu 2:15, 3:16-17).

English



Pada si oju ewe Yorùbá

Ṣé Bíbélì ní àwọn àṣìṣe, àwọn ohun tí ó takò ra wọn, tàbí àwọn ohun tí ó yàtọ̀ sí ra wọn?
Pin oju-iwe yii: Facebook icon Twitter icon Pinterest icon Email icon
© Copyright Got Questions Ministries