settings icon
share icon
Ibeere

Báwo ni àwọn Kristiẹni ṣe lè bá àwọn ọmọ wọn wí? Kínni Bíbélì sọ?

Idahun


Ọ̀nà tí ó dára jùlọ láti bá àwọn ọmọ wi lè jẹ́ iṣẹ́ tí ó le láti kọ́, ṣùgbọ́n ó ṣe pàtàkì púpọ̀. Àwọn kan gbà wípé ìbáwí ara (ìjìyà ara) bíi fífún ni lẹ́gba ni ọ̀nà kan ṣoṣo tí Bíbélì fọwọ́ sí. Àwọn kán sì dúró ṣinṣin wípé "fífú ni ní ìsínmi" àti àwọn ìjìyà tí kò la nínà lọ múnádóko jù. Kínni Bíbélì sọ? Bíbélì kọ́ wa wípé ìbáwí nípa nínà tọ́, ó wúlò, ó sì ṣe pàtàkì.

Ẹ má ṣìí gbọ́—àwa kò fọwọ́ si àṣìlò ọmọ lọ́nà kankan. A kò gbọ́dọ̀ bá ọmọ wí nípa nínà dé bi wípé yóo fa jàmbá sí ara ọmọ. Síbẹ̀, gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ Bíbélì ìbáwí nípa nínà tọ́ àti wípé ìbáwí nípa nínà pẹ̀lú ìkóraẹni ní ìjánu jẹ́ nǹkan tí ó dára, tí ó sì fikún ìlera ara àti ìtọ́ni tó pé fún ọmọ.

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹsẹ Ìwé Mímọ́ fọwọ́ sí ìbáwí nípa nínà. "Máṣe fa ọwọ́ ìbáwí kúrò sẹ́yìn kúrò lára ọmọdé, nítorí bí ìwọ bá fi pàṣán nàá, ò n kì yóo kú ìwọ fi pàṣán nà á," ìwọ ó sì gba ọkàn rẹ̀ là kúrò ní ọ̀run-àpáàdì" (Òwe 23:13-14; tún wo 13:24; 22:15; 20:30). Bíbélì ṣe ìtẹnumọ́ púpọ̀ lórí ìwúlò ìkóraẹni ní ìjánu; ó jẹ́ ohun tí gbógbo wa gbọ́dọ̀ ní láti jẹ́ ènìyàn tó ńso èso, ó sì dùn láti kọ́ nígbà èwe. Àwọn ọmọ tí a kò kọ́ lọ́pọ̀ ìgbà, ma ńdi aláìgbọràn, wọn kò ní ọ̀wọ̀ fún àṣẹ, àti wípé nípasẹ̀ èyí, yóo nira fún wọn láti gbọ́ràn àti tẹ̀lé Ọlọ́run tọkàntọkàn. Ọlọ́run fúnrarẹ̀, máa ńlo ìjìyà láti tọ́ wa sọ́nà, àti láti darí wa sí ipa ọ̀nà tí ó tọ́, àti láti faramọ́ ìrònúpíwàdà kúrò nínú àwọn ìwà búburú wa (Orin Dafidi 94:12; Òwe 1:7; 6:23; 12:1; 13:1; 15:5; Isaiah 38:16; Heberu 12:9).

Láti lè ṣe ìbáwí lọ́nà tí ó tọ́ àti gẹ́gẹ́ bí àwọn ìlànà Bíbélì, àwọn òbí ní láti mọ àmọ̀ràn tí ó wà nínú ìwé mímọ́ nípa ìbáwí. Ìwé Òwe ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọgbọ́n nípa ìtọ́ni àwọn ọmọ, fún àpẹẹrẹ, "pàṣán àti ìbáwí fún ni ní ọgbọ́n: ṣùgbọ́n ọmọ tí a bá jọ̀wọ́ rẹ̀ fún ara rẹ̀, á dójúti ìya rẹ̀" (Òwe 29:15). Ẹsẹ yìí sọ àtubọ̀tán àìbá ọmọ wí—ojú yóo ti àwọn òbí náà. Ní tòótọ́, àtubọ̀tán ìbáwí gbọ́dọ̀ jẹ́ fún rere ọmọ, kò sì gbọdọ̀ jẹ́ ìdáláre láti ṣe àṣìlò àti ìlòkulò àwọn ọmọ. A kò gbọ́dọ̀ lòó láti fi rọ́ ìbínú tàbí ìpòruúru ọkàn.

À ńlo ìbáwí láti tọ́ àti láti kọ́ àwọn ènìyàn sí ọ̀nà tí ó tọ́. "Gbogbo ìbáwí kò dàbí ohun ayọ̀ nísisìyí, bíkòṣe ìbànújẹ́; ṣùgbọ́n ní ìkẹyìn a só èso àlàáfíà fún àwọn tí a ti tọ́ nípa rẹ̀, àní èso òdodo" (Heberu 12:11). Ìbáwí Ọlọ́run ní ìfẹ́ nínú, bẹ́ẹ̀ ni ó yẹ kí ó rí láàrin òbí àti ọmọ. Ìbáwí nípa nínà kò gbọ́dọ̀ jẹ́ èyí tí yóo fa ewu tàbí ìnira pípẹ́ sára. Ìdánilójú wípé a ní ìfẹ̀ ọmọ gbọ́dọ̀ tẹ̀lé ìbáwí lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ tí a bá báwọn wí nípa nínà. Àwọn ìgbà báyìí jẹ́ àkòkò tí ó yẹ láti fi kọ́ ọmọ wípé Ọlọ́run a máa báwa wí nítorí ó fẹ́ràn wa, àti wípe, à ńṣe èyí fún àwọn ọmọ wa pẹ̀lú gẹ́gẹ́ bí òbí.

Ṣe a lè lo ọ̀nà míìrán bíi "fífún ni ní ìsínmi" dípò ìbáwí nípa nínà? Àwọn òbí kan ríi wípé Ìbáwí nípa nínà kò ran àwọn ọmọ kan. Àwọn òbí kan ríi wípé "fífún ni ní ìsínmi", jíjókò sójúkan, àti/tàbí mímú nǹkan kúrò lọ́dọ̀ àwọn ọmọ múnádóko ju ìbáwí nípa nínà lọ nínú ríran ìyípadà ìwà lọ́wọ́. Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀ ní tòótọ́, òbí gbọ́dọ̀ ríi wípé, ní gbogbo ọ̀nà, ó ńlo ọ̀nà tí ó so èso ìyípadà ìwà tí a nílò jùlọ. Nígbàtí Bíbélì gba níyànjú ìbáwí nípa nínà dájúdájú, Bíbélì ní íṣe pẹ̀lú èrèdí láti kọ́ ìwà bí Ọlọ́run ju ọ̀nà tí a lò ní pàtó láti mú èrèdí yìí ṣẹ lọ.

Ìjọba mú kí ọ̀rọ̀ yìí tún nira nípa bí wọ́n ṣe bẹ̀rẹ̀ sí ní pín gbogbo ọ̀nà ìbáwí nípa nínà sí àṣìlò ọmọ. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ òbí kò fi pàṣán na ọmọ nítorí wọ́n bẹ̀rù wípé wọ́n lè fi ẹjọ́ wọn sun ìjọba, wọn kò sì lè fi ara wọn sínú ewu gbígba ọmọ wọn kúrò lọ́wọ́ wọn. Kínni kí òbí ṣe nígbà tí ìjọba bá ṣe òfin wípé ìbáwí nípa nínà kò bá òfin mu? Gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ ti ìwé Romu 13:1-7, òbí gbọ́dọ̀ tẹríba fún ìjọba. Ìjọba kò gbọdọ̀ tako ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, torí ìbáwí nípa nínà wà fún èrè àwọn ọmọ, gẹ̀gẹ̀ bíi ìlànà Bíbélì. Ṣùgbn, pípa àwọn ọmọ mọ́ nínú àwọn ìdílé tí wọ́n ti lè rí ìbáwí díẹ̀ gbà dára ju kí á sọ wọ́n nù sí "ìtọ́jú" Ìjọba lọ.

Nínú ìwé Efesu 6:4, a sọ fún àwọn bàbá wípé ki wọ́n má ṣe mú àwọn ọmọ wọn bínú. Dípò bẹ́ẹ̀, ki wọ́n máa tọ́ wọn nínú ọ̀nà Ọlọ́run. Títọ́ ọmọ nínú "ẹ̀kọ́ àti ìtọ́ni Olúwa" ní íṣe pẹ̀lú ìbáwí nípa nínà tí ó ni ìkóraẹni ní ìjánu, tí ó ranni lọ́wọ́, tí ó sì jẹ́ pẹ̀lú ìfẹ́.

EnglishPada si oju ewe Yorùbá

Báwo ni àwọn Kristiẹni ṣe lè bá àwọn ọmọ wọn wí? Kínni Bíbélì sọ?
Pin oju-iwe yii: Facebook icon Twitter icon Pinterest icon Email icon
© Copyright Got Questions Ministries