settings icon
share icon
Ibeere

Kínni àwọn ọ̀run titun àti ayé titun?

Idahun


Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ló ní èròǹgbà òdì nípa bí ọ̀run ti rí lóòtítọ́. Ifihan orí 21-22 fún wa ní àlàyé àwòrán àwọn ọ̀run titun àti ayé titun. Lẹ́yìn àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ òpin ayé, àwọn ọ̀run àti ayé yìí yóò kọjá lọ a ó sì pààrọ̀ wọn pẹ̀lú àwọn ọ̀run àti ayé titun. Ibùgbé ayérayé fún àwọn onígbàgbọ́ yóò jẹ̀ẹ́ ayé titun. Ayé titun ní "ọ̀run" níbití a ó tì lo ayérayé. Ayé titun ni ibití Jerúsálẹ́mù titun, ìlú ọ̀run, yóò tẹ̀dó sí. Lórí ayé titun náà ni ẹnu-ọ̀nà píálì àti àwọn ọ̀nà ìgboro wúrà yóò wà.

Ọ̀run—ayé titun—jẹ́ ibi tí àwa yóò gbé pẹ̀lú ẹran ara tí a ṣe l'ógo (1 Kọrinti 15:35-58). Èròǹgbà wípé ọ̀run wà "nínú àwọsánmọ̀" kò bá Bíbélì mu. Èròǹgbà wípé àwa yóò jẹ́ "àwọn ẹ̀mí tí ńfò yíká ọ̀run" kò bá Bíbélì mu bákannáà. Ọ̀run tí àwọn onígbàgbọ́ yóò ní ìrírí rẹ̀ yóò jẹ́ ayé titun tí ó sì péye lórí èyí tí wọn yóò gbé. Ayé titun náà yóò bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀, ibi, àìsàn, ìyà, àti ikú. Ó ṣeé ṣe kí ó jọ ayé wa yìí, tàbí kí ó jẹ́ àtúndá ayé wa yìí, ṣùgbọ́n láìsí ipa ẹ̀ṣẹ̀.

Àwọn ọ̀run titun náà ńkọ́? Ó ṣe pàtàkì láti ráńti wípé ní èrò àtijọ́, "àwọn ọ̀run" èyítí à ńpè ní sáńmọ̀ àti òfurufú àti pẹ̀lú ibùgbé ti Ọlọ́run ńgbé. Fún ìdí èyìí, tí Ifihan 21:1 bá ńtọ́kasí ọ̀run titun, ó ṣeé ṣe kí ó máa ṣe àfihàn wípé a ó tún àgbáyé dá—ayé titun, sáńmọ̀ titun, òfurufú titun. Ó dàbi wípé a ó tún ọ̀run Ọlọ́run dá bákannáà, láti fún ohun gbogbo ní àgbáyé ní "ìbẹ̀ẹ̀rẹ̀ ọ̀tun," bóyá l'ára àbí l'ẹ́ẹ̀mí. Ṣé àwa yóò ní àǹfààní sí àwọn ọ̀run titun ní ayérayé? Ó ṣeé ṣe, ṣùgbọ́n àwa yóò nílò láti dúró láti mọ̀ọ́. Kí gbogbo wa gba Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run láàyé láti tún ìmọ̀ wa nípa ọ̀run ṣe.

English



Pada si oju ewe Yorùbá

Kínni àwọn ọ̀run titun àti ayé titun?
Pin oju-iwe yii: Facebook icon Twitter icon Pinterest icon Email icon
© Copyright Got Questions Ministries