settings icon
share icon
Ibeere

Kínni ìdí ti Ọlọ́run fi ńgba nǹkan burúkú láàyè láti ṣẹlẹ̀ sí àwọn ènìyàn rere?

Idahun


À ńgbé nínú ayé ìrora àti ìjìyà. Kò sí ẹnìkan tí àwọn ohun ayé tí ó dájú tí ó nira kò kàn, àti wípé ìbéèrè "kínni ìdí tí nǹkan burúkú fi ńṣẹlẹ̀ sí àwọn ènìyàn rere?" jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìbéèrè ti o ṣòro jùlọ nínú gbogbo ẹ̀kọ̀ ìmọ̀ Ọlọ́run. Ọlọ́run ni o ga jùlọ, nítorínáà, ó kéré jù, ohun gbogbo tí ó ńṣẹlẹ̀ gbọ́dọ̀ jẹ́ èyí tí Òun gbà láàyè, bí kìí bá ṣe wípé Òun ló fàá ní tààrà. Ní ìbẹ̀ẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀, a gbọ́dọ̀ jẹ́wọ́ wípé ènìyàn, tí kìí ṣe ti títí láíláí, àílòpin, tàbi mọ ohun gbogbo, kò lè lérò láti mọ gbogbo ète àti àwọn ọ̀nà Ọlọ́run l'ẹ́kùnrẹ́rẹ́.

Ìwé Jobu sọ̀rọ̀ nípa ìdí ti Ọlọ́run fi ńgba nǹkan burúkú láàyè láti ṣẹlẹ̀ sí àwọn ènìyàn rere. Jobu jẹ́ ọkùnrin olódodo (Jobu 1:1), síbẹ̀ òun jìyà ní àwọn ọ̀nà ti ó fẹ́ẹ̀ kọjá ti ìgbàgbọ́. Ọlọ́run gba èṣù láàyè láti ṣe ohun gbogbo tí ó fẹ́ sí Jobu yàtọ̀ sí kí o paá, tí èṣù sì ṣe èyítí o burú jùlọ rẹ̀. Báwo ni Jobu ṣe ṣe sí èyí? "Bí Ó tilẹ̀ pa mí, síbẹ̀ èmi ó máa gbẹ́kẹ̀le E" (Jobu 13:15). "Olúwa fifúnni Olúwa sì gbà lọ; ìbùkún li orúkọ Olúwa" (Job 1:21). Kò yé Jobu ìdí tí Olúwa fi gba àwọn ohun tí Òun ṣe láàyè, ṣùgbọ́n òun mọ̀ wípé Ọlọ́run dára, fún ìdí èyí òun tẹ̀síwájú láti máa gbẹ́kẹ̀le E. Ní ìkẹhìn, èyí ni ó yẹ kí o jẹ́ bí àwa náà yóò ṣe se bákànnáà.

Kínni ìdí tí nǹkan burúkú fi ńṣẹlẹ̀ sí àwọn ènìyàn rere? Bí o ti nira tó láti jẹ́wọ́, a gbọ́dọ̀ rántí wípé kò sí ẹni "rere" kan, bí a bá wo ọ̀rọ̀ yìí fínífíní. Gbogbo wa ni o ní àbàwọ́n nípasẹ̀ ẹ̀ṣẹ̀ tí ò sí ni ìkọlù pẹ̀lú (Ìwé Oníwàásù; Romu 3:23; 1 Johannu 1:8) Bí Jésù ṣe sọ, "Ẹni rere kan kò sí—àfi Ọlọ́run nìkan" (Luku 18:19). Gbogbo wa ni ó ńní ìmọ̀lára àwọn ipa ẹ̀ṣẹ̀ ní ọ̀nà kan tàbí òmíràn. Ní ìgbà míìrán ó jẹ́ ẹ́ṣẹ́ ti ara wa; ní ìgbà míìrán, o jẹ́ ẹ̀sẹ̀ àwọn ẹlòmíràn. Àwa ńgbé nínú ayé ti o ti ṣubú, tí a si ńní ìrírí àwọn ipa ìṣubú náà. Lára àwọn ipa wọ̀nyìí ni àìṣòdodo àti ìjìyà ti kò jọ wípé ó mu ọgbọ́n dání.

Nígbàtí ó bá ńyà wà lẹ́nu ìdí tí Ọlọ́run fi gba àwọn nǹkan burúkú láàyè láti ṣẹlẹ̀ sí ẹni rere, yóò tún dára láti gbé àwọn nǹkan mẹ́rin wọ̀nyìí yẹ̀wò nípa àwọn nǹkan burúkú tí ó ṣẹlẹ̀:

1) Àwọn nǹkan burúkú lè ṣẹlẹ̀ sí àwọn ènìyàn rere nínú ayé yìí, ṣùgbọ́n ayé yìí kọ́ ni òpin. Àwọn kristiẹni ni ìwò ayérayé nípa nǹkan: "Nítorí èyí ni àárẹ̀ kò ṣe mú wa. Ṣùgbọ́n bí ọkùnrin òde wa bá ńparun, síbẹ̀ ọkùnrin ti inú wa ńdi titun li ójojúmọ́. Nítorí ìpọ́njú wa ti o fẹ́rẹ̀, ti íṣe fún ìṣẹ́jú kan, o ńṣiṣẹ́ ògo àìnípẹ̀kun tí ó pọ̀ rékọjá fún wa. Níwọ̀n bí a kò ti wo ohun ti a ńrí, bíkòṣe ohun tí a kò rí: nítorí ohun tí a ńrí ni ti ìgbà ìsìsìyí, ṣùgbọ́n ohun ti a kò rí ni ti aiyeraye" (2 Kọrinti 4:16-18). Àwa yóò gba èrè ní ọjọ́ kan, èyí yóò sì l'ógo.

2) Àwọn nǹkan burúkú máa ńṣẹlẹ̀ sí àwọn ẹni rere, ṣùgbọ́n Ọlọ́run ńlo àwọn nǹkan burúkú wọ̀nyìí fún rere, ní ìkẹhìn. "Àwá si mọ̀ pé ohun gbogbo li o ńṣiṣẹ́ pọ̀ sí rere fún àwọn tí o fẹ́ Ọlọ́run, àní fún àwọn ẹniti a pè gẹ́gẹ́ bí ìpinnu rẹ̀" (Romu 8:28). Nígbàtí Jósẹ́fù, ẹniti kò jẹ̀bi ẹ̀sùn kankan, la ìjìyà rẹ̀ kọjá, òun lè rí ètò rere Ọlọ́run nínú gbogbo rẹ (wo Jẹnẹsisi 50:19-21).

3) Àwọn nǹkan burúkú máa ńṣẹlẹ̀ sí àwọn ẹni rere ṣùgbọ́n àwọn nǹkan burúkú yẹn máa ńpèsè àwọn onígbàgbọ́ fún iṣẹ́ ìránṣẹ́ tí ó jinlẹ̀. "Olùbùkún li Ọlọ́run . . . Bàbá Jésù Kristi Olúwa, Bàbá ìyọ́nú àti Ọlọ́run ìtùnú gbogbo, Ẹnití ńtù wá nínú ní gbogbo wàhálà wa, nípa ìtùnú náà tí a fi ńtù àwa tìkarawa nínú láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá. Kí àwa kí ó lè máa tu àwọn ti o wà nínú wàhálà-kí-wàhálà nínú" (2 Kọrinti 1:3-5). Àwọn ti wọ́n ní àpá ogun lè ran àwọn tí ó ńla ogun kọjá lọ́wọ́ dáradára.

4) Àwọn nǹkan burúkú máa ńṣẹlẹ̀ sí àwọn ènìyàn rere, tí àwọn nǹkan tí o burú jùlọ si ńṣẹlẹ̀ sí Ẹni ti o dára jùlọ. Jésù nìkan ni Ẹni tí ó jẹ́ Olódodo nítòótọ́, síbẹ̀ Òun jìyà ju bí a ṣe lérò lọ. Àwa ńtọ àwọn ipasẹ̀ Rẹ̀: "Nítorí ògo kínni ó jẹ́ nígbàtí ẹ̀yin ba ṣẹ̀ tí a sì lù yín, bí ẹ bá fi sùúrù gbàá? Èyí li ìtẹ́wọ́gbà l'ọ́dọ̀ Ọlọ́run. Nítorí inú èyí li a pè yín sí: nítorí Kristi pẹ̀lú jìyà fún yin, ó fí àpẹẹrẹ sílẹ̀ fún yin, kí ẹ̀yin lè máa tọ ipasẹ̀ rẹ̀. 'Ẹnití kò dẹ́sẹ̀, bẹ́ẹ̀ li a kò sì rí àrékérekè lẹ́nu rẹ̀.' Ẹni, nígbàtí a kẹ́gàn rẹ, tí kò sí padà kẹ́gàn; nígbàtí ó jìyà tí kò sí kìlọ̀; ṣùgbọ́n ó fi ọ̀ràn rẹ̀ lé ẹniti ńṣe ìdájọ́ òdodo " (1 Peteru 2:20-23). Àwọn ìrora wa kìí ṣe àjèjì sí Jésù.

Romu 5:8 sọ wípé, "Ṣùgbọ́n Ọlọ́run fi ìfẹ́ Òun pàápàá sí wa hàn, nígbàtí àwá jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀, Kristi kú fún wa." Láìkàsì àbùdá ìwà ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ènìyàn nínú ayé yìí, Ọlọ́run ṣì ní ìfẹ́ wa. Jésù ní ìfẹ́ wa tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ láti kú láti gba ìjìyà fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa (Romu 6:23). Bí a gba Jésù Kristi bíi Olùgbàlà (Johanu 3:16; Romu 10:9), àwa yóò gba ìdáríjì tí àwa yóò gba ìlérí ilé ayérayé ní ọ̀run (Romu 8:1).

Ọlọ́run máa ńgba àwọn nǹkan láàyè láti ṣẹlẹ̀ fún ìdí kan. Bóyá àwọn ìdí Rẹ̀ yé wa tàbí kò yé wa, àwa ńiláti rántí wípé Ọlọ́run dára, jẹ́ olódodo, nífẹ̀ẹ́, tí ó sì ní àánú (Orin Dafidi 135:3). Nígbàmíì, àwọn nǹkan burúkú máa ńṣẹlẹ́ sí wa tí kò lè yé wa. Dípò kí a ṣe iyèméjì nípa dídára Ọlọ́run, ìhùwàsí gbọ́dọ̀ jẹ́ ti ẹni tí ó gbẹ́kẹ̀le E. "Fi gbogbo àyà rẹ gbẹ́kẹ̀le Olúwa ; má sì ṣe tẹ̀sí ìmọ̀ ara rẹ. Mọ̀ọ́ ní gbogbo ọ̀nà rẹ òun yóò si máa tọ́ ipa-ọ̀nà rẹ. " (Òwe 3:5–6). Àwá ńrìn nípa ìgbàgbọ́, kìí ṣe nípa rírí.

English



Pada si oju ewe Yorùbá

Kínni ìdí ti Ọlọ́run fi ńgba nǹkan burúkú láàyè láti ṣẹlẹ̀ sí àwọn ènìyàn rere?
Pin oju-iwe yii: Facebook icon Twitter icon Pinterest icon Email icon
© Copyright Got Questions Ministries