settings icon
share icon
Ibeere

Kínni ìwò Kristiẹni nípa àwọn aríran?

Idahun


Bíbélì bu ẹnu àtẹ́ lu ìbẹmìílò, àbọ̀dè, ẹgbẹ́ òkùnkùn, àti ìríran (Lẹfitiku 20:27; Deutaronọmi 18:10-13). Awòràwọ̀, ìwoṣẹ́, iwòràwọ̀, awòràwọ̀, kíkà àtẹ́lẹwọ́, àti ibùdó ẹ̀mí òkùnkùn wà nínú ìṣọ̀rí yìí pẹ̀lú. Àwọn ìṣe wọ̀nyìí dá lórí ọ̀rọ̀ wípé àwọn ọlọ́run kékéèké, ẹ̀mí, tàbí àwọn olólùfẹ́ tí ó ti kú tí wọ́n lè gbani ní ìyànjú àti tọ́nisọ́nà. Àwọn "ọlọ́run kékéèké" tàbí "ẹ̀mí" jẹ́ ẹ̀mí èṣù (2 Kọrinti 11:14-15). Bíbélì kò fún wa ní ìdí kankan láti gbàgbọ́ wípé àwọn olólùfẹ́ tí ó ti kú le kànsí wa. Bí wọ́n bá jẹ́ onígbàgbọ́, wọ́n wà ní ọ̀run tí wọ́n ńgbádùn ibi tí ó dára jùlọ tí a lè rò fún ìpàdépọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run oníìfẹ́. Bí wọ́n kò bá jẹ́ onígbàgbọ́, wọ́n wà ní ọ̀run-àpáàdì, tí wọ́n ńjìyà oró àìlópin fún kíkọ ìfẹ́ Ọlọ́run tí wọ́n sì ńṣọ̀tẹ̀ sí I.

Nítorínàá, bí àwọn olólùfẹ́ wa kò bá lè kànsí wa, báwo ni àwọn alábọ̀dè, ẹlẹ́mìkẹ́ẹ̀mí, àti aríran ṣé ńrí ìran tí ó tọ́? Ọ̀pọ̀ àṣírí àwọn aríran jẹ́ èké. A ti fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ wípé àwọn aríran lè gba ọ̀pọ̀ àlàyé lórí ẹnìkan nípasẹ̀ ọ́nà lásán. Nígbà míìrán nípa lílo nọ́ńbà ìbáraẹnisọ̀rọ̀ nípa orúkọ olùpè àti ìwádìí orí ẹ̀rọ alátàagbà, aríran le mọ orúkọ, àdírẹ̀sì, ọjọ́ ìbí, ọjọ́ ìgbéyàwó, àwọn mọ̀lẹ́bí, abbl. Ṣùgbọ́n, a kò sàì mọ̀ wípé nígbà míìrán àwọn aríran lè mọ àwọn ohun tí kò ṣeé ṣe fún wọn láti mọ̀. Níbo ni àwọn aríran tí ńrí ìran yìí? Ìdáhùn náà wá láti ọ̀dọ Sátánì àti àwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀. "Kì sí íṣe ohun ìyanu; nítorí Sátání tìkararẹ̀ ńpa ara rẹ̀ dà ángẹ́lì ìmọ́lẹ̀. Nítorínà kì íṣe ohun ńlá bí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pẹ̀lú bá pa ara wọn dà bí àwọn ìránṣẹ́ òdodo. Ìgbẹ̀hìn àwọn ẹnití yíò ri gẹ́gẹ́ bí i iṣẹ́ wọn" (2 Kọrinti 11:14-15). Iṣe àwọn Apọsteli 16:16-18 ṣe àpèjúwe aláfọ̀ṣẹ kan ẹnití ó lè sọ nípa ọjọ́ iwájú kí apọsteli Pọ́ọ̀lù tó lé ẹ̀mí èṣù inú rẹ̀ jáde.

Sátánì ńdíbọ́n wípé òun dára àti wípé òun lè ṣe ìrànlọ́wọ́. Ó ńgbìyànjú láti farahàn gẹ́gẹ́ bíi ohun tí ó dára. Sátánì àti àwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ yóò fún àwọn aríran ní àlàyé nípa ẹnìkan kí wọ́n ba lè mú ẹni náà mọ́lẹ̀ sínú ẹ̀mí òkùnkùn, ohun tí Ọlọ́run lòdì sí. Ó farahàn bíi ohun tí kò lè pani lára l'ákọ̀ọ́kọ́, ṣùgbọ́n nígbà tí ó bá yá ìríran lè di bárakú fún àwọn ènìyàn tí wọ́n sì gba Sátánì láàyè láti darí ayé wọn kí ó sì bàájẹ́. Peteru kéde wípé, " Ẹ máa wà ní àìrékọjá, ẹ máa sọ́ra. Nítorí ẹ̀sù, ọ̀ta yín, bí i kìnìún tí ń ké ramúramù, ó ń rìn káàkiri, ó sì nwá ẹnití yíò pajẹ kiri" (1 Peteru 5:8). Ní àwọn àkókò míìrán, wọ́n máa ńtan àwọn aríran fúnra wọn jẹ, tí wọn kò ní mọ orísun tòótọ́ nípa àlàyé tí wọ́n gbà. Ohunkóhun tí ó jẹ́ ìṣẹ̀lẹ̀ náà àti ibikíbi tí ó jẹ́ orísun àlàyé náà, kò sí ohun tí ó sopọ̀mọ́ ìbẹmìílò, àjẹ́, tàbí ìwòràwọ̀ tí o jẹ́ ọ̀nà dáradára láti ṣe àwárí àlàyé. Báwo ni Ọlọ́run ṣe fẹ́ ká mọ ìfẹ́ Rẹ̀ fún ayé wa? Ètò Ọlọ́run rọrùn, síbẹ̀ ó l'ágbára ó sì yè kooro: ṣe àsàrò Bíbélì (2 Timoteu 3: 16-17) kí o sì gbàdúrà fún ọgbọ́n (Jakọbu 1:5).

English



Pada si oju ewe Yorùbá

Kínni ìwò Kristiẹni nípa àwọn aríran?
Pin oju-iwe yii: Facebook icon Twitter icon Pinterest icon Email icon
© Copyright Got Questions Ministries