settings icon
share icon
Ibeere

Kínni àwọn àmì òpin ayé?

Idahun


Ìwé Matteu 24:5-8 fún wa ní àwọn ìtanilólobó tí ó ṣe pàtàkì kan kí a ba lè dá sísúnmọ́ òpin ayé mọ̀, "Nitori ọpọlọpọ yóò wá li orúkọ mi, wípé, Emi ni Kristi; wọn o si tan ọpọlọpọ jẹ. Ẹyin o si gburo ogun ati idagiri-ogun: ẹ kiyesi i ki ẹyin ki o maṣe jáyà: Nitori gbogbo nkan wọnyii ko le ṣe ki o ma ṣe, ṣugbọn opin ki iṣe isisiyi. Nitoripe orilẹ-èdè yóò dide si orilẹ-èdè, ati ilẹ-ọba si ilẹ-ọba: Ìyàn, ati ajakalẹ-arun, ati iṣẹlẹ yóò si wa ni ibi pipọ." Àwọn Mesiah èké yóò pọ̀ si, ogun yóò pọ̀ si, àti ìyàn yóò pọ̀ si , àjàkálẹ́-àrùn àti ìsẹ́lẹ́ búburú—àwọn wọ̀nyìí jẹ́ àmì òpin ayé. Nínú àwọn àyọkà wọ̀nyìí, bí ó tilẹ̀ jẹ wípé a fún wa ní ìkìlọ̀: a kò gbdọ̀ jẹ́ kí ẹnikẹ́ni tàn wá jẹ, nítorí wípé ìbẹ̀rẹ̀ ìrora bíi ti ìrọbí ni àwọn ìṣẹ́lẹ̀ yìí, òpin ayé kò tíì dé.

Àwọn olùtúmọ̀ kan fihàn wípé gbogbo ilẹ̀ mímì, rúkèrúdò òṣèlú, àti gbogbo àtakò lórí Isrẹli jẹ́ àmì tí ó dájú wípé àwọn òpin/ìkẹyìn ayé ti ńsúnmọ́lé kíákíá. Nígbàtí, àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ yìí le tọ́ka sí sísúnmọ́ ìgbà ìkẹyìn, wọn kìí ṣe àmì tí ó gbọ́dọ̀ fi hàn wípé òpin ọjọ́ ti dé. Àpọ́stélì Pọ́lù kì wá nílọ̀ wípé òpin ọjọ́ yóò kún fún ẹ̀kọ́ òdì. "Ṣugbọn Ẹ̀mí ntẹnumọ ọ pé, ni igba ikẹhin awọn miran yio kuro ninu igbagbọ́, wọn o máa fiyesi awọn ẹmi ti ntan-ni-jẹ, ati ẹ̀kọ́ awọn ẹ̀mí èṣù" (1 Timoteu 4:1). A júwe ìgbà ìkẹyìn gẹ́gẹ́ bíi "ìgbà ewu" nítorí wípé ìwà búburú ènìyàn yóò máa pọ̀ si àti àwọn tí ń "kọ̀yìn sí òtítọ́" gidigidi (2 Timoteu 3:1-9; tún wo 2 Tẹssalonika 2:3).

Àwọn àmì míìrán tí ó ṣeéṣe ní títún tẹ́mpílì Júù ní Jèrúsalẹ́mù kọ́, ìkóríra àwọn Isrẹli yóò pọ̀si àti ìtiraka láti ní ìjọba kan ní gbogbo ayé. Ṣùgbọ́n, àmì òpin ayé tí ó farahàn jùlọ nííṣe pẹ̀lú orílẹ̀-èdè Isrẹli. Ní ọdún 1948, a dá Ísírẹ́lì mọ̀ gẹ́gẹ́ bí orílẹ̀-èdè olómìnira, fún ìgbà àkọ́kọ́ irú rẹ̀ láti ọdún 70 A. D (lẹ́yìn ikú Kristi). Ọlọ́run búra fún Ábráhámù wípé àtọmọdọ́mọ rẹ̀ yóò jogún Kénáánì gẹ́gẹ́ bíi "ìni rẹ̀ títí ayérayé" (Jẹnẹsisi 17:8), Esikiẹli sọtẹ́lẹ̀ wípé Isrẹli yóò sọjí ní ẹ̀mí àti lára (Esikiẹli orí 37). Níní Isrẹli gẹ́gẹ́ bíi orílẹ̀-èdè tí ó ní ilẹ̀ tirẹ̀ ṣe pàtàkì ní ìlànà pẹ̀lú àṣọtẹ́lẹ̀ òpin ayé nítorí àìfarasin Isrẹli nínu ẹ̀kọ́ òpin ayé (Daniẹli 10:14; 11:41; Ifihan 11:8)

Pẹ̀lú àwọn àmì wọ̀nyìí ní ọkàn wa, a lè ní òye àti ìmọ̀ nípa ìrèti àwọn àkókò òpin ayé. Ṣùgbọ́n àwa kò gbọ́dọ̀ dá ẹyọ kan àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ yìí túmọ̀ gẹ́gẹ́ bíi ìtọ́nà kedere wípé òpin ayé ti fẹ́rẹ̀ dé tán. Ọlọ́run ti fún wa lọ́yẹ̀ tí ó tó kí á le palẹ̀mọ́, èyí sì ni ohun tí a pè wá fún.

English



Pada si oju ewe Yorùbá

Kínni àwọn àmì òpin ayé?
Pin oju-iwe yii: Facebook icon Twitter icon Pinterest icon Email icon
© Copyright Got Questions Ministries