settings icon
share icon
Ibeere

Kínni yóò ṣẹlẹ̀ gẹ̀gẹ̀ bíi àṣọtẹ́lẹ̀ òpin ayé?

Idahun


Bíbélì ní ohun púpọ̀ láti sọ nípa ìkẹyìn ayé. Gbogbo ìwé inú Bíbélì ló fẹ́ẹ̀ sọ àṣọtẹ́lẹ̀ nípa òpin ayé. Ó lè ṣòro láti to àwọn àṣọtẹ́lẹ̀ yí papọ̀ ní ìlànà tó tọ́. Wọ̀nyìí ni díẹ̀ ní ṣókí nínú àwọn ohun tí Bíbélì sọ wípé yóò ṣẹlẹ̀ ní ìkẹyìn ayé.

Kristi yóò gba gbogbo àwọn àtúnbí onígbàgbọ̀ kúrò ní ayé nínú ìṣẹ̀lẹ̀ tí a mọ̀ sí ìgbàsókè (1 Tẹssalonika 4:13-18; 1 Kọrinti 15:51-54). Ní ìtẹ́ ìdájọ́ Kristi, àwọn onígbàgbọ̀ yìí yóò gba èrè iṣẹ́ rere ati ìjọ́sìn tòtọ́ọ́ nígbà tí wọn wà láyé tàbí kí wọ́n sọ èrè wọn nù, ṣùgbọ́n wọn kò ní pàdánù ìyè àìnípẹ́kun, nítorí àìní iṣẹ́ ẹ̀sìn àti ìgbọràn (1 Kọrinti 3;11-15; 2 Kọrinti 5:10).

Aṣòdìsí Kristi náà (ẹranko náà) yóò gba agbára, yóò sì buwọ́ lu májẹ̀mú pẹ̀lú Isrẹli fún ọdún méje (Daniẹli 9:27). Àkókò ọdún méje yí ni à ńpè ní "ìpọ́njú". Ní ìgbà ìpọ́njú náà, ogun búburú, ìyàn, àjàkálẹ̀ àrùn ati àdánù ńlá yóò wáyé. Ọlọ́run yóò máa tú ìbínú rẹ̀ jáde lòdì sí ẹ̀ṣẹ̀, ibi, àti ìwà ìkà. Ìpọ́njú náà yóò ní nínú ìfarahàn ẹlẹ́ṣin mẹ́rin ti Àpókalíísì náà, àti èdìdí méje, fèrè àti abọ́ ìdájọ́.

Ní bíi ìdajì ọdún méje náà, Aṣòdìsí Kristi yóò ba májẹ̀mú àlááfìa pẹ̀lú Isrẹli jẹ́, yóò sì gbé ogun dìde síi. Aṣòdìsí Kristi náà yóò dá "ẹ̀gbin ìsọdaworo", yóò sì gbé àwòrán ara rẹ̀ ka Témpílì Jèrúsálẹ́mù, èyítí a ti tún kọ́, láti máa bọ (Daniẹli 9:27, 2 Tẹssalonika 2;3-10). Ìdajì kejì ìpọ́njú náà ni "ìpọ́njú ńlá náà" (Ifihan 7:14) àti " àkókò ìpọ́njú Jákọ́bù "(Jẹrimiah 30:7)

Ní òpin ìpọnjú ọdún méje yìí, Aṣòdìsí Kristi náa yóò kọjú ìjà ìkẹhìn si Jèrúsálẹ́mù, tí yóò já sí ìjà Àmágẹdọ̀. Jésù Kristi yóò padà, yóò pa Aṣòdìsí Kristi àti àwọ́n ọmọ ogun rẹ̀ run, yóò sì sọ wọ́n sínú adágún iná (Ifihan 19:11-21). Kristi yóò gbé Sátánì sí inú ìgbèkun fún ẹgbẹ̀rún ọdun, òun yóò sì darí ìjọba ayé fún àkókò ẹgbẹ̀rún ọdun (Ifihan 20:1-6).

Ní òpin ẹgbẹ̀rún ọdun yìí, a ó tún tú Sátánì sílẹ̀, yóò gba ìjákulẹ̀ lẹ́ẹ̀kan si, a ó sì sọọ́ sínú adágún iná (Ifihan 20:7-10) títí ayérayé. Kristi yóò wa ṣe ìdájọ́ gbogbo àwọn aláìgbàgbọ (Ifihan 20:10-15) ní orí ìtẹ́ ìdájọ́ funfun ńlá; yóò sì sọ wọ́n sínú adágún iná. Kristi yóò wàá lànà fún ọ̀run titun, ayé titun, àti Jèrúsálẹ́mù tuntun—ilé ayérayé fún àwọn onígbàgbọ́. Kò ní sí ẹ̀ṣẹ̀, ìbànújẹ̀ tàbí ikú mọ́ (Ifihan 21-22).

EnglishPada si oju ewe Yorùbá

Kínni yóò ṣẹlẹ̀ gẹ̀gẹ̀ bíi àṣọtẹ́lẹ̀ òpin ayé?
Pin oju-iwe yii: Facebook icon Twitter icon Pinterest icon Email icon
© Copyright Got Questions Ministries