settings icon
share icon
Ibeere

Ǹjẹ́ Àjíǹde Jésù Kristi jẹ́ òtítọ́?

Idahun


Ìwé Mímọ́ fi àrídájú ẹ̀rí hàn wípé l'òtítọ́ ni Jésù Kristi jí dìde kúrò nínú òkú. Àkọsílẹ̀ Àjíńde Kristi wà nínú Matteu 28:1-20; Marku 16:1-20; Luku 24:1-53; àti Johannu 20:1-21:25. Kristi tí ó jí dìde farahàn nínú Ìwé Ìṣe àwọn Àpọ́stélì pẹ̀lú (Iṣe awọn Apọsteli 1:1-11). Nínú àwọn ẹṣẹ̀ wọ̀nyìí o lè rí àwọn "ẹ̀rí" púpọ̀ nípa àjíǹde Kristi. Àkọ́kọ́ ni àyípadà ìyanu nínú àwọn ọmọ-ẹ̀hìn. Wọ́n kúrò l'ààrin àwọn ẹgbẹ́ ọkùnrin oníbẹ̀rù tí ó ńsápamọ́, tí wọ́n di ẹlẹ́rìí tí wọ́n ńṣe àjọpín ìhìnrere jákèjádò ayé pẹ̀lú ìgboyà. Kínni o tún lè ṣ'àlàyé àyípadà ìyanu yìí yàtọ̀ sí Kristi tó jí dìde tó yọ sí wọn?

Ẹ̀kejì ni ìgbé-ayé Pọ́ọ̀lù Àpọ́stélì. Kíló yíi padà kúrò ní jíjẹ́ onínúnibíni sí ìjọ di àpọ́stélì fún ìjọ? Ìgbà tí Kristi tí ó jí dìde yọ síi ní ọ̀nà Damáskù (Iṣe awọn Apọsteli 9:1-6). Ẹ̀rí ẹ̀kẹẹ̀ta tí ó dájú ni ibojì tí ó ṣófo. Bí Kristi kò bá jí dìde, níbo wá ni ara Rẹ̀ wà? Àwọn ọmọ-ẹ̀hìn àti àwọn ìyókù rí ibojì níbi tí wọ́n sín sí. Nígbà tí wọ́n padà, ara Rẹ̀ kò sí níbẹ̀. Àwọn Áńgẹ́lì kéde wípé ó ti jí dìde kúrò nínú òkú gẹ́gẹ́ bí ó ṣe ṣ'èlérí (Matteu 28:5-7). Ẹ̀kẹrin, àfikún ẹ̀rí àjíǹde Rẹ̀ ni gbogbo àwọn ènìyàn tí ó yọ sí (Matteu 28:5, 9, 16-17; Marku 16:9; Luku 24:13-35; Johannu 20:19, 24, 26-29, 21:1-14; Iṣe awọn Apọsteli 1:6-8; 1 Kọrinti 15:5-7).

Ẹ̀rí àjíǹde Jésù míìrán ni iye òṣùnwọ̀n ńlá tí àwọn àpọ́stélì fún àjíǹde Jésù. Kókó ẹsẹ̀ bíbélì lórí àjíǹde Jésù ni Kọrinti kínní, orí kẹẹ̀ẹ́dógún (15). Nínú orí yìí, Pọ́ọ̀lù Àpọ́stélì ṣ'àlàyé ìdí tí ó fi ṣe pàtàkì láti ní òye àti ìgbàgbọ́ nínú àjíǹde Kristi. Àjíǹde ṣe pàtàkì fún àwọn ìdí wọ̀nyìí: 1) Bí Kristi kò bá jí dìde nínú òkú, àwọn onígbàgbọ́ kò le jí pẹ̀lú (1 Kọrinti 15:12-15). 2) Bí Kristi kò bá jí dìde nínú òkú, Ìrúbọ Rẹ̀ fún ẹ̀ṣẹ̀ kò tó (1 Kọrinti 15:16-19). Àjíǹde Jésù ṣ'àfihàn wípé ikú rẹ̀ jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà lọ́dọ̀ Ọlọ́run fún àwòtán ẹ̀sẹ̀ wa. Bí ó ba tí kú tí ó sì kú síbẹ̀, ìyẹn tọ́kasi wípé ìrúbọ Rẹ̀ kò tó. Ní àyọrísí èyí, kò sí ìdáríjìn ẹ̀sẹ̀ fún àwọn onígbàgbọ́, àti wípé wọn o di òkú síbẹ̀ lẹ̀yìn tí wọ́n bá kú (1 Kọrinti 15:16-19). Kò ní sí nǹkan tí ó ńjẹ́ ìyè ayérayé (Johannu 3:16). "Ṣùgbọ́n nísisìnyí Jésù ti jíǹde kúrò nínú òkú, àkọ́bí nínú àwọn tó sùn" (1 Kọrinti 15:20).

Ní ìparí, Ìwé Mímọ́ fihàn kedere wípé gbogbo àwọn tí ó gbàgbọ́ nínú Jésù Kristi ni yóò ní ìyè ayérayé gẹ́gẹ́bí òun ṣe wà (1 Kọrinti 15:20-23). Kọrinti kínní, orí kẹẹ̀ẹ́dógún (15) ńtẹ̀síwájú láti ṣ'àlàyé bí àjíǹde Kristi ṣe fi ìṣẹ́gun Rẹ̀ lóri ẹ̀ṣẹ̀ hàn ó sì pèsè agbára láti gbé ìgbé-ayé aṣẹ́gun lóri ẹ̀ṣẹ̀ fún wa (1 Kọrinti 15:24-34). Ó nṣe àpèjúwe ìṣẹ̀dá ológo ti ara àjíǹde tí a o fifún wa (1 Kọrinti 15:35-49). Ó kéde wípé, ní àyọrísí àjíǹde Kristi, gbogbo àwọn tí ó gbàgbọ́ nínú Rẹ̀ ní ìṣẹ́gun ńlá lórí ikú (1 Kọrinti 15:50-58).

Irú òtítọ́ ológo wo ni àjíǹde Kristi jẹ́! "Nítorínà, ẹ̀yin ará mi olùfẹ́, ẹ má a dúró sinsin. Láìyẹsẹ̀. Kí ẹ máa pọ̀ sii ní iṣẹ́ Olúwa nígbàgbogbo, níwọ̀n bí ẹ̀yín ti mọ̀ pé iṣẹ̀ yín kì íṣe asán nínú Olúwa" (1 Kọrinti 15:58). Ní ìbámu pẹ̀lú Bíbélì, àjíǹde Kristi jẹ́ òtítọ́ gan. Bíbélì ṣe àkọsílẹ̀ àjíǹde Kristi, tí ó ṣe àkọsílẹ̀ pé àwọn ènìyàn tí ó lé ní irinwó (400) ló ṣe ẹlẹ́rìí rẹ̀, àwọn ènìyàn sí tẹ̀sìwájú láti kọ́ ẹ̀kọ́ Kristiẹni tí ó ṣe pàtàkì lórí ìtàn àjíǹde Kristi tí o jẹ́ òtítọ́.

English



Pada si oju ewe Yorùbá

Ǹjẹ́ Àjíǹde Jésù Kristi jẹ́ òtítọ́?
Pin oju-iwe yii: Facebook icon Twitter icon Pinterest icon Email icon
© Copyright Got Questions Ministries