settings icon
share icon
Ibeere

Ǹjẹ́ ohun kan wà tí ó ńjẹ́ àjèjì tàbí UFOs?

Idahun


Àkọ́kọ́, ẹjẹ́ kí á túmọ̀ "àjèjì" gẹ́gẹ́ bíi "ẹ̀dá tí ó ní agbára láti yan ìwà, tí ó ní ọpọlọ pípé, ìmọ̀lára, àti ìfẹ́." Ní ìtẹ̀síwájú, òtítọ́ sáyẹ́nsì:

1. Àwọn ènìyàn ti rán bàlúù sí gbogbo pílánẹ́tìì nínú ètò sólà. Lẹ́yìn tí wọ́n wo gbogbo àgbáyé yìí, wọ́n ri wípé, Másìì àti òṣùpá Júpítà nìkan ni o ṣeé ṣe láti fi ààyè gba nǹkan tí ó ní ẹ̀mí.

2. Ní ọdún 1976, orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà rán ikọ̀ méjì lọ sí Másìì. Ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ní ohun-èlò tí ó le wa ilẹ̀, kí ó sì ṣe àyẹ̀wò nǹkan fún bóyá ó ní àmì wípé ó fi ààyè gba nǹkan tí ó ní ẹ̀mí. Wọn kò rí nǹkankan. Ní àtakò, bí a bá ṣe àyẹ̀wò erùpẹ̀ ní asálẹ̀ tí ó gbẹ jùlọ láyé tàbí ibi tí ó kún fún yìnyín jù ní Àǹtátíkà, ìwọ yóò rìí wípé ó kún fún àwọn ohun ẹlẹ́mìí tí kò ṣeé fojú rí. Ní ọdún 1997, orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà rán Patifáńdà lọ sí òfurufú Másìì. Àwọn ikọ̀ yí gba síwájú si àwọn ohun díẹ̀ fún àyẹ̀wò láti ṣe ìwádìí síwájú si. Bákan náà, wọn kò rí àmì ẹlẹ́mìí kankan. Láti ìgbà náà, ati fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn amí ráńṣẹ́ lọ sí Másìì. Àbájáde kannáà ni ó ńyọrísí.

3. Àwọn awòràwọ̀ kò sinmi láti máa wá pílánẹ́tìì titun síi nínú ètò sólà tí ó jìnà. Àwọn kan gbèrò wípé ìwàláàyè àwọn pílánẹ́tìì púpọ̀ fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ wípé àwọn nǹkan ẹlẹ́mìí gbọ́dọ̀ wà ní ibòmíràn ní àgbáyé. Òtítọ́ náà ni wípé, a kò tíì fìdíi rẹ̀ múlẹ̀ wípé àwọn pílánẹ́tìì fi ààyè gba nǹkan tí ó ní ẹ̀mí. Ọ̀nà jíjìn púpọ̀ láàrin ayé àti àwọn pílánẹ́tìì yìí jẹ́ kí ó máa ṣeé ṣe láti fẹnu kò wípé wọ́n ní agbára láti fi ààyè gba nǹkan tí ó ní ẹ̀mí. Mí mọ̀ wípé Ayé nìkan ló lè fi ààyè gba nǹkan tí ó ní ẹ̀mí nínú àwọn ètò sólà, àwọn ẹlẹ́kọ̀ọ́ ẹfolúsàn ńwá pílánẹ́tìì míìrán lọ́nàkọnà nínú ètò sólà míìrán láti fi kín àbá wípé ayé wù jáde ni lẹ́hìn. Àwọn pílánẹ́tìì míìrán wà lóde, ṣùgbọn a kò ní ìmọ̀ lẹ́kúnrẹ́rẹ́ láti fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ wípé wọ́n lè fi ààyè gba nǹkan tí ó ní ẹ̀mí.

Nítorí náà, kínni Bíbélì ṣọ? Ayé àti ìran-ènìyàn dádúró gedegbe nínú ìṣẹ̀dá Ọlọ́run. Ìwé Jẹ́nẹ́sìsì 1 kọ́ wa wípé Ọlọ́run dá ayé ṣaájú kí ó tó dá òrùn, òṣùpá tàbi àwọn ìràwọ̀. Ìṣe àwọn Apọsteli 17:24, 26 sọ wípé "Ọlọ́run náà tí ó dá ayé ati gbogbo nǹkan tí ó wà ninu rẹ̀, ò n náà tí ṣe Oluwa ọ̀run ati ayé, kì í gbé ilé tí a fi ọwọ́ kọ́... Òun ni ó dá gbogbo orílẹ̀-èdè láti inú ẹnìkan ṣoṣo láti máa gbé gbogbo ilẹ̀ ayé. Kí ó tó dá wọn, ó ti ṣe ìpinnu tẹ́lẹ̀ nípa ìgbà tí wọn yóo gbé ní ayé ati ààlà ibi tí wọn yóo máa gbé."

Ní àtètèkọ́ṣe, a dá ènìyàn láìlẹ́ṣẹ̀, ohun gbogbo ní ayé sì wà "dáradára" (Jẹnẹsisi 1:31) Nígbàtí ọkùnrin àkọ́kọ́ dẹ́ṣẹ̀ (Jẹnẹsisi 3), àyọrísí rẹ̀ jẹ́ oríṣiríṣi ìṣòro bíi àìsàn àti ikú. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wípé, àwọn ẹranko kò ní ẹ̀ṣẹ̀ kankan níwájú Ọlọ́run (wọn kò ní ìrònú), síbẹ̀ wọn a máa jìyà, kí wọ́n sì kú. (Romu 8:19-22) Jésù Kristi kú láti lè mú ìjìyà tí ó tọ́ fún ẹ̀ṣẹ̀ wa kúrò. Nígbàtí ó bá padà, yóò mú gbogbo ègún kúrò láti ìgbà Ádámù (Ifihan 21–22). Ṣe àkíyèsí wípé ìwé Romu 8:19-22 sọ wípé gbogbo ìṣẹ̀dá ńretí àsìkò yìí gidigidi. Ó tún ṣe pàtàkì wípé kí á ṣe àkíyèsí wípé Kristi wá láti kú fún ìran-ènìyàn àti wípé ó kú lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo (Heberu 7:27; 9:26-28; 10:10).

Bí gbogbo ìṣẹ̀dá bá wà lábẹ́ egún yìí, gbogbo nǹkan ẹlẹ́mìí ní ayé yìí ni yóò jìyà rẹ̀ pẹ̀lú. Bí ó bá wá jẹ́ wípé, nítorí àríyànjiyàn, àwọn ìṣẹ̀dá tí ó dára ṣì wà ní pílánẹ́tìì míìrán, nígbà náà àwọn náà yóo jíyà, àtí wípé tí kò bá jẹ́ nísinsìnyí, nígbà náà lọ̀jọ̀ kan wọn yóò jìyà dájúdájú, nígbàtí ohun gbogbo bá kọjá lọ ti àwọn ti ariwo ńlá, àti àwọn ìmọ́lẹ̀ ojú ọ̀run yóò sì ti inú oru gbígbóná gidigidi di yíyọ́ (2 Peteru 3:10). Bí wọn kò bá dẹ́ṣẹ̀ rí, Ọlọ́run kò ní jẹ́ olódodo ní fífi ìyà jẹ wọ́n. Ṣùgbọ́n bí wọn bá ti ṣẹ̀, tí ó sì jẹ́ wípé Kristi lè kú ní ẹ̀kan ṣoṣo péré (tí Òun sì ṣeé ní orílẹ̀ ayé), nígbà náà a fi wọ́n sílẹ́ nínú ẹ̀ṣẹ̀ wọn, èyítí yóò sì ṣe lòdì sí ìwà Ọlọ́run (2 Peteru 3:9). Èyí sì fi wá sílẹ́ pẹ̀lú adìtú tí a kò lè yanjú — àyààfi bí kò bá sí àwọn ìṣẹ̀dá tí ó dára ní òdì kejì ayé.

Báwo ni ti àwọn ìṣẹ̀dá tí kò dára àti tí kò jípépé ní àwọn pílánẹ́tìì míìrán? Ṣé àwọn álgàe tàbí àwọn ajá àti ológbò lè wà ní pílánẹ́tìì tí a kò mọ̀? Bí ó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, àti wípé kò ní ṣe ibi kankan fún ẹsẹ Bíbélì kankan. Ṣùgbọ́n dájúdájú yóò jẹ́ ìṣòro nígbàtí a bá ńgbìyànjú láti dáhùn ìbéèrè bíi "Níwọ̀n ìgbà tí gbogbo ìṣẹ̀dá bá ńjìyà, kínni èrèdí tí Ọlọ́run ní tí ó fi dá àwọn ìṣẹ̀dá tí kò dára àti tí kò jípépé láti jìyà ní pílánẹ́tìì tí ó jìnà?"

Ní àkótán, Bíbélì kò fún wa ní ìdí láti gbàgbọ́ wípé ayé wà ní ibòmíràn ní àgbáyé. Ní òdodo, Bíbélì fún wa ní ìdí gbòógí púpọ̀ tí kò fi lè sí. Bẹ́ẹ̀ni, àwọn nǹkan àjòjì àti tí a kò lè ṣe àlàyé pọ̀ tí ó ńṣẹlẹ̀. Síbẹ̀, kò sí ìdí kankan láti so àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ wọ̀nyìí mọ́ àjèji tàbí àwọn UFO. Bí ìdí kan tí a dámọ̀ báwà fún àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí a lérò wọ̀nyìí, ó lè jẹ́ ti ẹ̀mí, àti ní pàtó, ó lè jẹ́ ti ẹ̀mí àìmọ́, ní ti orísun.

EnglishPada si oju ewe Yorùbá

Ǹjẹ́ ohun kan wà tí ó ńjẹ́ àjèjì tàbí UFOs?
Pin oju-iwe yii: Facebook icon Twitter icon Pinterest icon Email icon
© Copyright Got Questions Ministries