settings icon
share icon
Ibeere

Ǹjẹ́ àdúrà àjùmọ̀gbàpọ̀ ṣe pàtàkì? Ǹjẹ́ àdúrà àjùmọ̀gbàpọ̀ àdúrà lágbára ju àdúrà àdáníkangbà lọ?

Idahun


Àdúrà àjùmọ̀gbàpọ̀ jẹ́ ìpín pàtàkì nínú ayé ìjọ, pẹ̀lú ìjọ́sìn, ẹ̀kọ́ tí ó yè koro, ìdàpọ̀ àti ìbáṣepọ̀. Àwọn ìjọ àkọ́kọ́ ńpàdé déédé láti kọ́ ẹ̀kọ́ àwọn àpọ́stélì, bu àkàrà àti jíjùmọ̀ gbàdúrà papọ̀ (Iṣe awọn Apọsteli 2:42). Nígbàtí a bá jùmọ̀ gbàdúrà papọ̀ pẹ̀lú àwọn onígbàgbọ́ míìrán, àtúnbọ̀tan rẹ̀ lè jẹ́ rere jùlọ. Àjùmọ̀gbàpọ̀ àdúrà á máa ṣàtúnṣe àti sowápọ̀ gẹ́gẹ́ bíi a ti ńpín ìgbàgbọ́ wa tí o wọ́pọ̀. Ẹ̀mí Mímọ́ kań náà tí ó ńgbé inú olúkùlùkù onígbàgbọ̀ mú kí ọkàn wa kí ó yọ̀ gẹ́gẹ́ bí a ti gbọ́ ìyìn sí Olúwa àti Olùgbàlà, tí ńso wá papọ̀ ní ọ̀nà ìdìpọ̀ ìbáṣepọ̀ tí ó dá yàtọ̀ èyítí a kò rí níbikíbi nínú ayé.

Sí àwọn tí ó lè dá nìkan wà àti làkàkà pẹ̀lù ẹrù ayé yìí, gbígbọ́ ẹlòmíràn ńgbé wọ́n sókè sí orí ìtẹ́ ore-ọ̀fẹ́ èyí tí ó lè jẹ́ ìgbaníníyànjú nlá. Á sì tún 'ú wa dàgbà nínú ìfẹ́ àti bíbìkítà fún àwọn ẹ̀lòmíràn gẹ́gẹ́ bí a tí ńṣìpẹ̀ fún wọn. Bákannáà, àdúrà àjùmọ̀gbàpọ̀ yóò tún jẹ́ ìfarahàn ọkàn olúkùlùkù tí ó kópa nńú rẹ̀. A gbọ́dọ̀ wá sí ọ̀dọ Ọlọ́rún pẹ̀lú ìrẹ̀lẹ̀ (Jakọbu 4:10), òtítọ́ (Orin Dafidi 145:18), ìgbọràn (Johannu 3:21-22) pẹ̀lú ìdúpẹ́ (Filippi 4:6) àti ìdánilójú (Heberu 4:16). Pẹ̀lú ìbànújẹ́, àdúrà àjùmọ̀gbàpọ̀ tún lè jẹ́ àtẹ̀gùn fún àwọn tí ọ̀rọ̀ wọn kò darí lọ sí ọ̀dọ̀ Ọlọ́rún, ṣùgbọ́n sí àwọn olùgbọ́ wọn. Jésù ṣe ìkìlọ̀ lòdì sí irú ìwà báyìí, ní Matteu 6:5-8 níbi tí ó ti gbà wá níyànjú láti má ṣe jẹ́ aláṣehàn, ọlọ́rọ̀-púpọ̀ tàbí alágàbàgebè nínú àwọn àdúrà wa, ṣùgbọ́n láti gbàdúrà ní ìkọ̀kọ̀ ní inú àwọn yàra wa nítorí à ti déènà ìdánwò à ti lo àdúrà lọ́nà èké.

Kò sí ohunkóhun ní inú Ìwé Mímọ́ tí o lè dábàá wípé àdúrà àjùmọ̀gbàpọ̀ jẹ́ "alágbára jú" ju àdúrà àdáníkangbà nínú ìmòye mímì ọwọ́ Ọlọ́run. Ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà ọ̀pọ̀lọpọ̀ Kristiẹni a ma fi àdúrà dọ́gba pẹ̀lú "rírí nǹkan gbà lọ́wọ́ Ọlọ́run", ti àdúrà ẹlẹ́gbẹ́jẹgbẹ́ di ayẹyẹ pàtàkì láti ka àkójọ àwọn ohun tí à ńfẹ́. Ṣùgbọ́n, àwọn àdúrà tí ó bá bíbélì mu, ti lẹ̀, jẹ́ olójú-púpọ̀, tí ó dá dúro ní wíwọ́ inú ìmọ̀lára àti ìbáṣepọ̀ tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Ọlọ́run mímọ́, pípé àti olódodo. Wípé irú Ọlọ́run báyìí yóò t'ẹ́tí sí àwọn ẹ̀da Rẹ̀ á máa mú ìyìn àti ìjúbà tú jáde lọ́pọ̀lọpọ̀ (Orin Dafidi 27:4; 63:1-8) mú ìrónúpìwàdà àti ìjẹ́wọ́ láti ọkàn wá (Orin Dafidi 51; Luku 18:9-14), ńṣe ìpìlẹ̀ ìtújáde ọpẹ́ atí ìdúpẹ́ (Filippi 4:6), tí ó sì ńṣẹ̀dá ìṣìpè tòótọ́ ní orúkọ àwọn ẹlòmíràn (2 Tẹssalonika 1:11;2:16).

Àdúrà, sì jẹ́, sísowọ́pọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run láti mú ètò Rẹ̀ jáde, kìí ṣe láti yí Òun sí ìfẹ́ tìkalara wá. Bí a ṣe ńkọ àwọn ìfẹ́ ti ara wa sílẹ̀ ní ìtẹríba fún Ẹni náà tí ó mọ ipò wa jú bí a tilẹ̀ lè mọọ̀ lọ àti ẹni "ohun tí ẹyin ṣe alaini, kí ẹ to bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀"(Matteu 6:8), àwọn àdúrà wa si ńdé ipele tí ó ga jùlọ. Àdúrà tí a bá gbà ní ìtẹ́riba sí ìfẹ́ àtòkèwá, nítorínà, ni o máa ńní ìdáhùn rere nígbàgbogbo, yálà ẹnìkan tàbí ẹgbẹ̀rún ní ó gbàá.

Èrò wípé àwọn àdúrá àjùmọ̀gbàpọ̀ jẹ́ èyíti o máa ńfẹ́ mi ọwọ́ Ọlọ́run wá lọ́pọ̀lọ́pọ̀ látàri àṣìtúmọ̀ Matteu 18:19-20, "Mo wi fun yin ẹ̀wẹ̀ pe, bi ẹni meji ninu yin ba fi ohùn sọkan li aye niti ohunkohun ti wọn o bere; a o ṣe e fun wọn lati ọdọ Baba mi ti nbẹ li ọrun wá. Nítorí níbi tí ẹni meji tabi mẹta bá ko ara wọn jọ li orúkọ mi, níbẹ̀ li emi o wà li àárín wọn." Àwọn ẹsẹ̀ wọ̀nyìí wá láti inú ẹsẹ̀ tí ó sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìlànà láti tẹ̀lé nínú ọ̀ràn ìbáwí nínú ìjọ fún ọmọ ìjọ tí ó ńdẹ́ṣẹ̀. Láti ṣe ìtúmọ̀ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìlérí èyítí o fún àwọn onígbágbọ̀ ní ìwe sọ̀wédówó fún ohunkóhun tí wọn bá fi ìṣọ̀kan bèrè lọ́wọ́ Ọlọ́rún, láìkàsí bí o bá ṣe jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ sí tàbí ìwà òmùgọ̀, kìí ṣe wípé èyí kò wà ní ìbámu pẹ̀lú ìbáwí ti ìjọ, ṣùgbọ́n ó kọ yìn sí àwọn Ìwé Mímọ́ yòókù, pàápàá jùlọ ti títóbi jùlọ Ọlọ́run.

Ní àfikún, láti ìgbàgbọ́ wípé nígbàtí "ẹni méjì tàbí mẹ́ta bá kórajọpọ̀" láti gbàdúrà, àwọn irú agbára idán ńṣe àgbélárugẹ àdúrà wa ní wéréwéré tí ní kò ní àtìlẹ́hìn láti inú bíbélì. Òtítọ́ ní Jésù ńwà níbẹ̀ nígbàtí ẹni méjì tàbì mẹta bá ńgbàdúrà, ṣùgbọ́n Òun náà ṣí ńbẹ níbẹ̀ nígbàtí onígbàgbọ́ kan bá ńdá gbàdúrà, kódà bí ẹni náà bá yapa kúrò lọ́dọ̀ àwọn yóókù pẹ̀lú ẹ́gbẹ̀rún máílì. Àdúrà àjùmọ̀gbàpọ̀ ṣe pàtàkì nítorí o máa ńṣẹ̀dá ìṣọ̀kan (Johannu 17:22-23), ó sì jẹ́ kókó pàtàkì nínú kí onígbàgbọ́ gba ara wọn níyànjú (1 Tẹssalonika 5:11) àti ríru ara wọn sókè sí ìfẹ́ àti iṣẹ́ rere (Heberu 10:24).

English



Pada si oju ewe Yorùbá

Ǹjẹ́ àdúrà àjùmọ̀gbàpọ̀ ṣe pàtàkì? Ǹjẹ́ àdúrà àjùmọ̀gbàpọ̀ àdúrà lágbára ju àdúrà àdáníkangbà lọ?
Pin oju-iwe yii: Facebook icon Twitter icon Pinterest icon Email icon
© Copyright Got Questions Ministries