settings icon
share icon
Ibeere

Ǹjẹ́ o ṣe ìtẹ́wọ́gbà láti tún àdúrà gbà fún nǹkan kańnáà?

Idahun


Ní Luku 18:1-7, Jésù lo òwe kan láti ṣe àpèjúwe ṣíṣe pàtàkì àìṣe-àárẹ̀ nínú àdúrà. Òun sọ ìtàn obìrin opó kan tí ó tọ onídàájọ aláìsododo tí ó ńwá ìdájọ́ òdodo lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá rẹ̀. Nítorí àìṣe-àárẹ̀ rẹ̀ nínú àdúrà, onídàájọ náà ronúpìwàdà. Kókó ọ̀rọ̀ Jésù ni wípé bí onídàájọ aláìsododo yóò bá dáhùn ẹ̀bẹ̀ ẹnikan nítorí ìpamọ́ra lórí ìbéèrè fún ìdájọ́ òdodo, mélomélo ni Ọlọ́run tí ó nífẹ̀ẹ wa—"àyànfẹ́ rẹ̀" (v. 7)—Dáhùn àdúrà wa nígbàtí a bá ńtẹ̀síwájú láti gbàdúrà? Òwe náà kò kọ́ wa, ní bí a ṣe lérò pẹ̀lú àṣìṣe, wípé bí àwa bá bèrè ohun kan léraléra, ó pọn dandan kí Ọlọ́run fi fún wa. Dípò bẹ́ẹ̀, Ọlọ́run ṣe ìlérí láti gbẹ̀san àwọn tí Òun, dá wọn láre, sọ àítọ́ wọn di títọ́, ṣe ìdájọ́ òdodo fún wọn, kí ó sì gbà wọn lọ́wọ́ àwọn ọ̀ta wọn. Òun ńṣe èyí nítorí òdodo Rẹ̀, ìwà mímọ́ Rẹ̀, àti ìkórira Rẹ̀ fún ẹ̀ṣẹ̀; ní dídáhùn àdúrà, Òun ńpa àwọn ìlérí Rẹ̀ mọ́ tí ó sì ńfi agbára Rẹ̀ hàn.

Jésù tún ṣe àpèjúwe míìrán nípa àdúrà ní Luku 11:5-12. Ní ìbáramu pẹ̀lú òwe onídàájọ aláìsododo náà, iṣẹ́ ìráńṣẹ́ Jésù nínú àyọkà yìí ni wípé bí ènìyàn bá jẹ́ ara ni ara rẹ̀ lára láti pèsè fún àìní ọ̀rẹ́ rẹ̀, Ọlọ́run yóò pèsè fún àwọn àìní wa jù bẹ́ẹ̀ lọ, nígbàtí ó jẹ́ wípé kò sí ìbéèrè wa kan tí yóò ni Òun lára. Ní ibi yìí lẹ́ẹ̀kansi, ìlérí náà kìí ṣe wípé àwa yóò gba ohunkóhun tí àwa bá bèèrè bí àwa bá ńbèèrè léraléra. Ìlérí Ọlọ́run fún àwọn ọmọ Rẹ̀ jẹ́ ìlérí láti bá àìní wa pàdé kìí ṣe àwọn ohun tí a fẹ́. Òun si mọ àwọn àìní wa jù wá lọ. Ìlérí kańnáà ni atún sọ ni Matteu 7:7-11 àti ní Luku 11:13, níbi tí a ti ṣe àlàyé síwájú síi wípé Ẹ̀mí Mímọ́ ni "ẹ̀bùn rere" náà.

Àwọn àyọkà méèjèjì wọ̀nyìí gbà wá níyànjú láti gbàdúrà kí á sì tẹ̀síwájú láti máa gbàdúrà. Kò sí ohun tí kò tọ́ pẹ̀lú bíbèérè fún ohun kańnáà léraléra. Ní ìwọ̀n ìgbà tí ohun tí a ńgbàdúrà fún bá wà nínú ìfẹ́ Ọlọ́run (1 Johannu 5:14-15), tẹ̀síwájú láti máa bèèrè títí tí Ọlọ́run yóò fi dá ọ lóhùn tàbí yọ èròngbà náà kúrò ní ọkàn rẹ. Nígbàmíìràn Ọlọ́run ńfi ipa mú wa dúró fún ìdáhùn sí àwọn àdúrà wa láti kọ́ wa ní sùúrù àti ìpamọ́ra. Nígbàmíìràn àwa yóò bèèrè fún nǹkankan nígbàtí fífún wa kò tìí tó àkókò nínú àkókò Ọlọ́run fún ayé wa. Nígbàmíìràn àwa yóò bèèrè fún nǹkankan tí kìí ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run fún wa, tí Òun yóò sí wípé "rárá." Àdúrà kìí ṣe fífi àwọn ìbéèrè wa sílẹ̀ níwájú Ọlọ́run; ó túmọ̀ sí kí Òun fi ìfẹ́ Rẹ̀ sínú ọkàn wa. Tẹ̀síwájú láti máa bèèrè, tẹ̀síwájú láti máa kanlẹ̀kùn, kí o sì tẹ̀síwájú láti máa wá Olúwa títí tí Ọlọ́run yóò fi dáhùn ìbéèrè rẹ tàbí múu dá ọ lójú wípé kìí ṣe ìfẹ́ Òun fún ọ.

EnglishPada si oju ewe Yorùbá

Ǹjẹ́ o ṣe ìtẹ́wọ́gbà láti tún àdúrà gbà fún nǹkan kańnáà?
Pin oju-iwe yii: Facebook icon Twitter icon Pinterest icon Email icon
© Copyright Got Questions Ministries