settings icon
share icon
Ibeere

Kínni àdúrà Olúwa àti wípé ṣe ó yẹ kí a gbàá?

Idahun


Àdúrà Olúwa ni àdúrà ti Jésù Olúwa kọ́ àwọn ọmọ-ẹ̀hìn Rẹ̀ ní Matteu 6:9-13 àti Luku 11:2-4. Matteu 6:9-13 sọ wípé, "Nitorina bayi ni ki ẹyin máa gbadura: Baba wa ti nbẹ li ọrun; Ki a bọ̀wọ̀ fun orukọ rẹ. Ki ijọba rẹ de; ifẹ tirẹ ni ki a ṣe, bi ti ọrun, bẹ́ẹ̀ li aye. Fun wa li oúnjẹ òòjọ wa loni. Dari gbese wa ji wa, bi awa ti ndariji awọn onigbese wa. Má si fà wá sinu idẹwo, ṣugbọn gbà wa lọwọ bilisi." Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ṣi Àdúrà Olúwa túmọ̀ láti jẹ́ àdúrà tí ó yẹ kí a máa tún kà ní ọ̀rọ̀ fún ọ̀rọ̀. Àwọn kan ńlo Àdúrà Olúwa bíi ajẹ́ bíi idán kan, bí ẹni wípé àwọn ọ̀rọ̀ náà ní àwọn agbára kan ní pàtó nínú ara wọn tàbí wípé ó ní ipa lórí Ọlọ́run.

Bíbélì kọ́ ni ní ìdàkejì èyí. Ọlọ́run ní inú dídùn sí ọkàn wa nígbàtí a bá ńgbàdúrà ju bí Òun ti ní inú dídùn nínú àwọn ọ̀rọ̀ wa. "Ṣugbọn nigbati iwọ ba ngbadura, wọ iyẹwu rẹ lọ, nigbati iwọ ba si sé ilẹkun rẹ tan, gbadura si Baba rẹ ti nbẹ ni ikọkọ; Baba rẹ ti o si riran ni ikọkọ yoo san a fun ọ ni gbangban. Ṣugbọn nigbati ẹyin ba ngbadura, ẹ maṣe atunwi asan bi awọn keferi; wọn ṣebi a o ti itori ọrọ pipọ gbọ́ ti wọn" (Matteu 6:6-7). Nínú àdúrà, àwa ńláti tú ọkàn jáde sí Ọlọ́run (Filippi 4:6-7), kìí ṣe kí a ka àwọn ọ̀rọ̀ tí a ti kọ́sórí sí Ọlọ́run.

Àdúrà Olúwa ni a gbọ́dọ̀ ní òye rẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi àpẹẹrẹ, àwòṣe, láti gbàdúrà. Ó fún wa ni "àwọn èròjà" tí ó yẹ kí ó lọ sínú àdúrà. Èyí ni àtúpalẹ̀ rẹ. "Baba wa ti nbẹ li ọrun" ńkọ́ wa ẹni tí ó yẹ kí a darí àwọn àdúrà wa sí—Baba. "Ki a bọ̀wọ̀ fun orukọ rẹ" ńsọ fún wa láti jọ́sìn fún Ọlọ́run, àti láti yìn-ín fún Ẹni ti Òun jẹ́. Gbólóhùn kúrurú "ki ijọba rẹ de; ifẹ tirẹ ni ki a ṣe, bi ti ọrun, bẹ́ẹ̀ li aye" jẹ́ ìránnilétí fún wa wípé a gbọ́dọ̀ gbàdúrà fún ètò ti Ọlọ́run nínú ayé wa àti àgbáyé, kìí ṣe fún ètò ti ara wa. Àwa ní láti gbàdúrà kí ìfẹ́ ti Ọlọ́run kó ṣẹ, kìí ṣe àwọn èròngbà ti wa. A gbà wá níyànjú láti bèèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run fún ohun tí a nílò "fun wa li oúnjẹ òòjọ wa loni." "Dari gbese wa ji wa, bi awa ti ndariji awọn onigbese wa" rán wa létí láti jẹ́wọ́ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa fún Ọlọ́run àti láti yípadà kúrò nínú wọn, kí a si dáríji àwọn ẹlòmíràn bíi Ọlọ́run ti ṣe dáríjì wá. Àkótán Àdúrà Olúwa, "Má si fà wá sinu idẹwo, ṣugbọn gbà wa lọwọ bilisi" jẹ́ ẹ̀bẹ̀ fún ìrànlọ́wọ́ láti ní ìṣẹ́gun lórí ẹ̀ṣẹ̀ àti ìbéèrè fún ìdáàbòbò lọ́wọ́ àwọn ìkọlù èṣù.

Nítorí náà, lẹ́ẹ̀kansi, Àdúrà ti Olúwa kìí ṣe àdúrà tí ó yẹ kí a kọ́sórí kí á wá tún kà fún Ọlọ́run. Ó kan jẹ́ àpẹẹrẹ kan ní bí a ṣe gbọ́dọ̀ máa gbàdúrà. Ǹjẹ́ ohunkóhun wá burú pẹ̀lú kíkọ́ Àdúrà Olúwa sórí? Rárá o, kò rí bẹ̀ẹ! Ǹjẹ́ ohunkóhun wá burú pẹ̀lú gbígba Àdúrà Olúwa padà sí Ọlọ́runí? Kò rí bẹ̀ẹ bí ọkàn wa bá wà nínú rẹ̀, tí àwọn ọ̀rọ̀ náà si ti ọkàn wa wá. Rántí, nínú àdúrà, Ọlọ́run ni inú dídùn sí bíbá Òun sọ̀rọ̀ àti kí a sọ̀rọ̀ láti ọkàn wa ju nínú àwọn ọ̀rọ̀ tí a lò ní pàtó. Filipi 4:6-7 sọ wípé, "Ẹ máṣe àníyàn ohunkóhun, ṣùgbọ́n nínú ohun gbogbo, nípa àdúrà àti ẹ̀bẹ̀ pẹ̀lú ìdúpẹ́, ẹ máa fi ìbéèrè yín hàn fún Ọlọ́run. Àti àlàáfíà Ọlọ́run, tí ó ju ìmọ̀ràn gbogbo lọ, yóò sọ ọkàn àtì èrò yín nínú Kristi Jésù."

EnglishPada si oju ewe Yorùbá

Kínni àdúrà Olúwa àti wípé ṣe ó yẹ kí a gbàá?
Pin oju-iwe yii: Facebook icon Twitter icon Pinterest icon Email icon
© Copyright Got Questions Ministries