settings icon
share icon
Ibeere

Kínni ìdí tí Ọlọ́run fi yan Isrẹli láti jẹ́ ènìyàn Rẹ̀?

Idahun


Ní sísọ̀rọ̀ nípa Isrẹli, Deutarọnọmi 7:7-9 sọ fún wa wípé, "OLÚWA kò fi ìfẹ́ rẹ̀ sí yin lara, bẹ́ẹ̀ni kò yàn yin, nitori ẹ̀yin pọ̀ ni iye ju àwọn ènìyàn kan lọ; nítorípé ẹ̀yin li o tilẹ̀ kéré jù nínú gbogbo ènìyàn. Ṣùgbọ́n nítorítí Olúwa fẹ́ yin, àti nítorití Òun fẹ́ pa ara ti Òun ti bú fún àwọn bàbá yin mọ́, ni OLÚWA ṣe fi ọwọ́ agbára mú yin jáde, o si rà yin padà kúrò li oko-ẹrú, kúrò lí ọwọ́ Farao ọba Íjíbítì. Nítorínáà ki ìwọ ki o mọ̀ pé, OLÚWA Ọlọ́run rẹ, Òun li Ọlọ́run olóòótọ́, ti ńpa májẹ̀mú mọ́ àti àánú fún àwọn ti o fẹ́ ẹ, ti wọn si pa òfin rẹ̀ mọ́ dé ẹgbẹ̀rún ìran."

Ọlọ́run yan orílẹ̀-èdè Isrẹli láti jẹ́ ènìyàn Rẹ̀ nípasẹ̀ àwọn ẹni tí a ó gbà bí Jésù Kristi—Olùgbàlà lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú (Johannu 3:16). Ọlọ́run kọ́kọ́ ṣe ìlérí Mesiah lẹ́yìn tí Ádámù àti Éfà ṣubú sínú ẹ̀ṣẹ̀ (Jẹnẹsisi orí 3). Nígbàtí ó yá Ọlọ́run jẹ́rì si wípé Mesiah yóò wá láti ọ̀dọ̀ Ábráhámù, Isaaki, àti Jakọbu (Jẹnẹsisi 12:1-3). Jésù Kristi ni ìdí tí Ọlọ́run fi yan Isrẹli láti jẹ́ ènìyàn Rẹ̀ ọ̀tọ̀ ní ìkẹhìn. Ọlọ́run kò ní láti yan ènìyàn kankan, ṣùgbọ́n Òun pinnu láti ṣeé bẹ́ yẹn. Jésù ńní láti wá láti orílẹ̀-èdè àwọn ènìyàn kan, tí Ọlọ́run si yan Isrẹli.

Ṣùgbọ́n, ìdí tí Ọlọ́run fi yan orílẹ̀-èdè Isrẹli kìí ṣe fún ètè pípèsè Mesiah nìkan. Ète Ọlọ́run fún Isrẹli ni wípé àwọn yóò lọ láti kọ́ àwọn ẹlòmíràn nípa Rẹ̀. Isrẹli ńní láti jẹ́ orílẹ̀-èdè àwọn alufa, wòlíì, àti ajíhìnrere sí ayé. Èròngbà Ọlọ́run ni fún Isrẹli láti jẹ́ ènìyàn ọ̀tọ̀, orílẹ̀-èdè tí yóò máa tọ́ka àwọn ẹlòmíràn sí Ọlọ́run àti ìlérí Rẹ̀ fún ìpèsè Olùràpadà, Mesiah, àti Olùgbàlà. Fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà, Isrẹli kùnà nínú ojúṣe yìí. Ṣùgbọ́n, ète Ọlọ́run ni ìkẹhìn fún Isrẹli—láti mú Mesiaah wá sínú ayé—ni a mú ṣẹ ní pípé nínú Ẹni Jésù Kristi.

English



Pada si oju ewe Yorùbá

Kínni ìdí tí Ọlọ́run fi yan Isrẹli láti jẹ́ ènìyàn Rẹ̀?
Pin oju-iwe yii: Facebook icon Twitter icon Pinterest icon Email icon
© Copyright Got Questions Ministries