Ibeere
Kínni ìfẹ́ ni Ọlọ́run túmọ̀ sí?
Idahun
Ẹ jẹ́ kí a wo bí Bíbélì ṣe ṣe àpèjúwe ìfẹ́, lẹ́yìn èyí àwa yóò rí àwọn ọ̀nà díẹ̀ bí Ọlọ́run ṣe jẹ́ gbòógì ìfẹ́. "Ìfẹ́ a máa mú sùúrù, a sì máa ṣeun. Kìí ṣe ìlara; ìfẹ́ kìí sọ̀rọ̀ ìgbé-raga, kìí fẹ̀. Kìí hùwà àìtọ́, kìí wa ohun ti ara rẹ, a kìí múu bínú, bẹ́ẹ̀ li kìí gbero ohun búburú. Ìfẹ́ kìí yọ̀ sí àìṣòdodo, ṣùgbọ́n a máa yọ̀ nínú òtítọ́. Òhun máa ńdáàbòbò ní ìgbà gbogbo, a máa gba ohun gbogbo gbọ̀, a máa retí ohun gbogbo, máa farada ohun gbogbo. Ìfẹ́ kìí yẹ̀ láé" (1 Kọrinti 13:4-8a). Èyí ni àpèjúwe ìfẹ́ ti Ọlọ́run, àti wípé nítorí Ọlọ́run jẹ́ Ifẹ́ (1Johannu 4:8), èyí ni Òun fẹ́.
Ìfẹ́ (Ọlọ́run) kìí fi tipátipá gbé ara Rẹ̀ lórí ẹnikẹ́ni. Àwọn tí wọn bá tọ Òun wá ńṣe bẹ́ẹ̀ ní ìdáhùn sí ìfẹ́ Rẹ̀. Ìfẹ́ (Ọlọ́run) ńfi inú rere hàn sí ènìyàn gbogbo. Ìfẹ́ (Jésù) ńlọ káàkiri tí ó ńṣe rere sí ènìyàn gbogbo láì ṣe ojúṣàájú. Ìfẹ́ (Jésù) kò jowú ohun tí elòmíìràn ní, tí Òun ńgbé ìgbé-ayé ìrẹ̀lẹ̀ láì ṣe àwáwí. Ìfẹ́ (Jésù) kìí gbéraga nípa ohun tí Òun jẹ́ nínú ara, bí ó tilẹ̀ jẹ́ wípé Òun lè borí ẹnikẹ́ni tí Òun bá bá pàdé. Ìfẹ́ kìí bèèrè fún ìgbọ́ràn. Ọlọ́run kò bèèrè fún ìgbọ́ràn láti ọ̀dọ̀ Ọmọ Rẹ̀, ṣùgbọ́n dípò bẹ́ẹ̀, Jésù tìkalára Rẹ̀ ló gbọ́ràn sí Baba Rẹ̀ tí ńbẹ ní ọ̀run. "Nítori kí aiye lè mọ̀ pé èmí fẹ́ràn Baba; gẹ́gẹ́ bí Baba si ti fi àṣẹ fún mi, bẹ́ẹ̀ni èmí ńṣe" (Johannu 14:31). Ìfẹ́ (Jésù) máa/ó sì ńwá àwọn ìfẹ́ ẹlòmíìràn.
Ìfẹ́ Ọlọ́run tí ó ga jùlọ ni a fihàn wá ní Johannu 3:16: "Nítorí Ọlọ́run fẹ́ aráyé tó bẹ́ẹ̀ gẹ́, tí ó fi Ọmọ bíbí Rẹ̀ kan soso fúnni, kí ẹnikẹ́ni tí ó ba gbàá gbọ́ má báa ṣègbé, ṣùgbọ́n kí ó lè ní ìyè àínìpẹkun." Ìwé Romu 5:8 tún ṣo ọ̀rọ̀ kannáà: "Ṣùgbọ́n Ọlọ́run fi ìfẹ́ Òun pàápàa sí wa hàn ní èyí pé, nígbàtí àwa jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀, Kristi kú fún wa." Àwa lè rí láti àwọn ẹsẹ wọ̀nyìí wípé ó jẹ́ èròngbà Ọlọ́run tí ó ga jùlọ kí a darapọ̀ mọ́ Òun ní ilé ayérayé Rẹ̀, ọ̀run. Òun ti jẹ́ kí ọ̀nà èyí ṣeéṣe nípa sísan owó fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa. Òun fẹ́ wa nítorí Òun yàn láti ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi ìṣe Rẹ̀. Ìfẹ́ máa ńdáríjí "Bí àwa bá jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wa, olóòtọ́ọ́ àti olódodo li Òun láti dárí ẹ́ṣẹ̀ wa jì wá, àti láti wẹ̀ wá nù kúrò nínú àìṣòdodo gbogbo" (1 Johannu 1:9).
Nitorinaa, "Kínni ìfẹ́ ni Ọlọ́run túmọ̀ sí?" Ìfẹ́ jẹ́ àbùdá Ọlọ́run kan. Ìfẹ́ jẹ́ ìwà Ọlọ́run, ti Èèyàn Rẹ̀. Ìfẹ́ Ọlọ́run kò fi nǹkan tako ìwà mímọ́ Rẹ̀, òdodo, ìdájọ́ òdodo, tàbí ìbúnù Rẹ̀. Gbogbo àbùdá Ọlọ́run ni o wà ni ìṣọ̀kan pípé. Ohun gbogbo ti Ọlọ́run ṣe ni ìfẹ́, gẹ́gẹ́ bí ohun gbogbo tí Òun bá ṣe ṣe jẹ́ òdodo àti èyítí ò tọ́. Ọlọ́run ni àpẹẹrẹ ìfẹ́ tí ó pé jùlọ ní tòótọ́. Ní ọ̀nà tí ó yani lẹ́nu, Ọlọ́run ti fún àwọn tí ó gba Ọmọ Rẹ̀ gbọ́ gẹ́gẹ́ bíi Olùgbàlà wọn ní agbára láti ní ìfẹ́ bíi Òun, nípasẹ̀ agbára Èmí Mímọ́ (Johannu 1:12; 1 Johannu 3:1, 23-24).
English
Kínni ìfẹ́ ni Ọlọ́run túmọ̀ sí?