settings icon
share icon
Ibeere

Kínni Jésù ni ọmọ Ọlọ́run túmọ̀ sí?

Idahun


Jésù kìí ṣe ọmọ Ọlọ́run ní èrò bàbá àti ọmọ ni ti ara. Ọlọ́run kò ṣe ìgbeyàwó kí ó wá bí ọmọ ọkùnrin kan. Ọlọ́run kò ní àjọṣepọ̀ pẹ̀lú Màríà kí wọ́n sì jọ bí ọmọ ọkùnrin kan. Jésù ni ọmọ Ọlọ́run ní èrò wípé Óun jẹ́ Ọlọ́run tó f'arahàn ní ìran ènìyàn (Johannu 1:1, 14). Jésù ni ọmọ Ọlọ́run ní ti wípé Màríà l'óyún Rẹ̀ nípa Ẹ̀mí Mímọ́. Luku 1:35 wípé, "Áńgẹ́lì náà sí dáhùn ó sì wí fún un pé, Ẹ̀mí Mímọ́ yíò tọ̀ ọ́ wá, àti agbára Ọ̀gá ògo yíò síji bò ọ́. Nítorínà ohun mímọ́ tí a ó tinú rẹ bí, Ọmọ Ọlọ́run ni a ó ma pè é."

L'àkókò ìdánwò Rẹ̀ níwájú àwọn olóri Júù, Olórí Àlúfà bèère lọ́wọ́ Jésù, "Mo fi Ọlọ́run alààyè bẹ̀ ọ́ pé, Kí ìwọ kí ó sọ fún wa bí ìwọ bá ṣe Kristi ọmọ Ọlọ́run" (Matteu 26:63). "Jésù wí fún un pé, ìwọ́ wí. 'Ṣùgbọ́n mo wí fún yín: Lẹ́yín èyí ni ẹ̀yin ó rí ọmọ ènìyàn tí yíò jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún agbára, tí yíò sì máa ti inú àwọsánmà ọ̀run wá" (Matteu 26:64). Àwọn olórí Júù dáhùn nípa fífi ẹ̀sùn-un ọ̀rọ̀-ọ̀dì kan Jésù (Matteu 26:65-66). Lẹ́yìn náà, níwájú Pọ́ntù Pílátù, "Àwọn Júù dá a lóhùn wípé , àwa ní òfin kan, àti gẹ́gẹ́ bi òfin wa Ó yẹ láti kú, nítorítì Ó fi ara Rẹ̀ ṣe Ọmọ Ọlọ́run" (Johannu 19:7). Kí ló dé tí pípe ara Rẹ̀ ni Ọmọ Ọlọ́run ṣe jẹ́ ọ̀rọ̀-òdì tí ó sì fi tọ́ sí ìdájọ́ ikú? Àwọn olórí Júù l'òye ohun tí Jésù sọ ní pàtó nípa gbólóhùn kúkúrú "Ọmọ Ọlọ́run." Láti jẹ́ Ọmọ Ọlọ́run ni láti ní ìwà bíi Ọlọ́run. Ọmọ Ọlọ́run jẹ́ "ti Ọlọ́run."Jíjẹ́wọ́ wípé Òun ní àbùdá Ọlọ́run —kódà láti jẹ́ Ọlọ́run —jẹ́ ọ̀rọ̀-òdì sí àwọn olórí Júù; nítorínà, wọ́n bèère ikú Jésù, ní ìbámu pẹ̀lú Léfitíku 24:15. Heberu 1:3 fihàn kedere pé, ọmọ náà ni ìtànsán ògo Ọlọ́run àti àwòrán Òun tìkararẹ̀."

Àpẹẹrẹ mìírán ni a lè rí ní Johannu 17:12 níbití a ti ṣ'àpèjúwe Júdásì gẹ́gẹ́bíi "ọmọ ègbé." Johannu 6:71 sọ fún wa wípé Júdásì ni ọmọ Símónì. Kínni Johannu 17:12 túmọ̀ sí nípa ṣíṣàpèjúwe Júdásì gẹ́gẹ́bíi "ọmọ ègbé?" Ọ̀rọ̀ tí ó ńjẹ́ ègbé túmọ̀ sí "ìdibàjẹ́, ìparun, òfò." Orúkọ Júdásì kìí se ọmọ "ìdibàjẹ́, ìparun, òfò" ṣùgbọ́n àwọn nǹkan wọ̀nyìí jẹ́ ìdámọ̀ ayé Júdásì. Júdásì jẹ́ ìmúsẹ ègbé. Ní ọ̀nà yi bákannáà, Jésù ni ọmọ Ọlọ́run. Ọmọ Ọlọ́run ni Ọlọ́run. Jésù ni Ọlọ́run tí ó farahàn (Johannu 1:1, 14)

English



Pada si oju ewe Yorùbá

Kínni Jésù ni ọmọ Ọlọ́run túmọ̀ sí?
Pin oju-iwe yii: Facebook icon Twitter icon Pinterest icon Email icon
© Copyright Got Questions Ministries