settings icon
share icon
Ibeere

Kínni Jésù ńgbàlà túmọ̀ sí?

Idahun


"Jésù ń gbàlà" jẹ́ orí-ọ̀rọ̀ tí a ńlẹ̀ mọ́ ara ọkọ̀ tí ó gbajúgbajà, àwọn àmìn ni àwọn ibùdó eré ìje, àti àsìá pàápàá tí àwọn ọkọ̀ òfurufú kékeré ńfà kọjá lójú ọ̀run. Ó bani nínú jẹ́ wípé, díẹ̀ nínú àwọn tí ó rí gbólóhùn kúkurú náà "Jésù ńgbàlà" ló ní òye ìtumọ̀ rẹ̀ l'ótìtọ́ọ́ àti l'ẹ́kùnrẹ́rẹ́. Àwọn ìwọ̀n agbára àti òtítọ́ ńlá la kójọ sínú àwọn ọ̀rọ̀ méjì yìí.

Jésù ńgbàlà, ṣùgbọ́n tani Jésù?
Ó yé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn wípé Jésù jẹ́ ọkùnrin tí ó gbé ní orílẹ̀-èdè Isrẹli ní nǹkan bíi ẹgbẹ̀rún (2000) ọdún sẹ́yìn. Ó fẹ́rẹ̀ jẹ́ wípé gbogbo ẹ̀sìn ní àgbáyé wo Jésù gẹ́gẹ́ bíi olùkọ́ rere àti/tàbí wòólì. Àti bí àwọn nǹkan wọ̀n yẹn ti jẹ́ òtítọ́ nípa Jésù tó, wọn kò sọ ẹni tí Jésù jẹ́ ní tòótọ́, bẹ́ẹ̀ni wọn kò ṣe àlàyé bí àti tàbí ìdí ti Jésù fí ńgbàlà. Jésù ni Ọlọ́run tí ó farahàn (Johannu 1:1, 14). Jésù ni Ọlọ́run, Òun wá sí ayé, gẹ́gẹ́ bí ènìyàn tòótọ́ (1 Johannu 4:2). Ọlọ́run wá di ènìyàn ẹni tíí ṣe Jésù Kristi kí Òun lè gbà wá là. Èyí mú wa lọ sí ìbéèrè tí ó kàn: kínni ìdí tí a fi nílò láti di ẹni ìgbàlà?

Jésù ńgbàlà, ṣùgbọ́n kínni ìdí tí a fi nílò láti di ẹni ìgbàlà?
Bíbélì sọ wípé gbogbo ènìyàn tí ó ti gbé ilé ayé rí ti ṣẹ̀ (Oniwaasu 7:20; Romu 3:23). Láti d'ẹ́ṣẹ̀ ni láti ṣe nǹkan, bóyá ní èrò, ọ̀rọ̀, tàbí ìṣe, tí ó tako ìwa pípé àti mímọ́ ti Ọlọ́run. Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wa, gbogbo wa la l'ẹ́tọ̀ọ́ sí ìdájọ́ l'ọ́dọ̀ Ọlọ́run (Johanu 3:18, 36). Ọlọ́run jẹ́ olódodo, nítorínáà kò lè gbà kí ẹ̀ṣẹ̀ àti ibi lọ láì jìyà. Níwọ̀n bí Ọlọ́run ṣe jẹ́ àìlópin àti ayérayé, àti níwọ̀n tí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ ti lòdì sí Ọlọ́run (Orin Dafidi 51:4), ìjìyà àìlópin àti ayérayé nìkan ló pé. Ikú ayérayé nìkan ni ìjìyà pípé fún ẹ̀ṣẹ̀. Ìdí nìyẹn tí a fi nílò láti di ẹni ìgbàlà?

Jésù ńgbàlà, ṣùgbọ́n báwo ni Òun ṣe ńgbàlà?
Nítorí a ti ṣẹ̀ sí Ọlọ́run àìlópin, bóyá ẹni tí kò l'ópin (àwa) gbọ́dọ̀ san gbèsè ẹ̀ṣẹ̀ wa fún iye àkókò àìlópin, tàbí Ẹni àìlópin (Jésù) gbọ́dọ̀ san gbèsè ẹ̀ṣẹ̀ wa ni ẹ̀ẹ̀kan. Kò sí ọ̀nà míìrán mọ́. Jésù gbà wá là nípa kíkú ní ipò wa. Nínu ẹni tí Jésù Kristi íṣe, Ọlọ́run fi ara Rẹ̀ rúbọ nítorí tiwa, tí Òun ńsan gbèsè ìjìyà àìlópin àti ayérayé tí Òun lè san nìkan (2 Kọrinti 5:21; Johannu 2:2). Jésù gba ìjìyà tí ó tọ́ sí wa kí Òun lè gbà wá là kúrò lọ́wọ́ àyànmọ́ ìparun ayérayé, ìjìya pípé fún àtunbọ̀tán ẹ̀ṣẹ̀ wa. Nítorí ìfẹ̀ ńlá Rẹ̀ fún wa, Jésù jọ̀wọ́ ayé Rẹ̀ sílẹ̀ (Johannu 15:13), ńsan gbèsè ìjìyà tí a ti ní, ṣùgbọ́n tí a kò lè san. Jésù wá jíǹde, ń ṣe àfi hàn pé ikú Rẹ̀ tó láti san gbèsè ẹ̀ṣẹ̀ wa ni tòótọ́ (1 Kọrinti 15).

Jésù ńgbàlà, ṣùgbọ́n tani Òun ńgbàlà?
Jésù ńgba gbogbo ẹni tí yóò gba ẹ̀bùn ìgbàlà Rẹ̀ là. Jésù ńgba gbogbo àwọn tí ó gbàgbọ́ l'ẹ́kùnrẹ́rẹ́ nínú ìrúbọ Rẹ̀ nìkan gẹ́gẹ́ bí ìsan gbèsè fún ẹ̀ṣẹ̀ là (Johannu 3:16; Iṣe àwọn Apọsteli 16:31). Níwọ̀n bí ìrúbọ Jésù ti pé l'ẹ́kùnrẹ́rẹ́ láti san gbèsè ẹ̀ṣẹ̀ gbogbo ìran ènìyàn, Jésù ńgba àwọn tí o gba ẹ̀bun iyebíye Rẹ̀ tìkara wọn là (Johannu 1:12).

Bí òye ìtumọ̀ Jésù ńgbàlà bá yé ọ báyìí, tí o sì fẹ́ gbàgbọ́ nínú rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Olùgbàlà rẹ, ríi wípé o ní òye àti gbàgbọ́ nǹkan wọ̀nyìí, àti gẹ́gẹ́ bíi ìṣe ìgbàgbọ́, sọ àwọn nǹkan wọ̀nyìí sí Ọlọ́run. "Ọlọ́run, mo mọ̀ wípé ẹlẹ́ṣẹ́ ni mí, mo sì mọ̀ wípé nítorí ẹ̀ṣẹ̀ mi mo l'ẹ́tọ̀ọ́ sí ìyapa ayérayé kúrò lọ́dọ̀ Rẹ. Kódà tí nkò bá l'ẹ́tọ̀ọ́ síi, O ṣeun tí o fẹ́ràn mi àti ìpèsè ìrúbọ fún ẹ̀ṣẹ̀ mi nípa ikú àti àjíǹde Jésù Kristi. Mo gbàgbọ́ wípé Jésù kú fún ẹ̀ṣẹ̀ mi mo sì gbàgbọ́ nínú Rẹ̀ nìkan láti gbà mí là. Lati ìgbà yìí lọ, ràn mí lọ́wọ́ láti gbé ìgbe-ayé mi fún Ọ dípò fún ẹ̀ṣẹ̀. Ràn mí lọ́wọ́ láti gbé ìyóóku ayé mi nínú ọpẹ́ fún ìyanu ìgbàlà tí Ìwọ ti pèsè. O ṣeun, Jésù, fún gbígbà mí là!"

Ti o ba fe gba jesu Kristi gbo gege bi olugbala re nikan, so awon oro won yi si Oluwa. Ranti wipe, gbigba adura yi tabi adura mi ran ko le gba o o la. O ni lati ni ireti ninu Jesu Kristi wipe o le dariji ese re ji o. Adura yi je eyi ti o file so fun Oluwa nipa igbagbo re ninu re, ki o si dupe fun idariji re.“ Oluwa, mo wipe elese ni mi. mo si mo wipe iya ayeraye to si mi fun ese mi.” Sugbon, mo ni ireti ninu Jesu Kristi gege bi olugbala. Mo mo n wipe iku ati ajinde re lo fun mi ni idariji ese. Mo ni ireti ninu Jesu, Jesu ni kan gege bi Olorun ni nikan ati olugbala mi. E se fun ore- ofe ati idariji ese mi- ebun ayeraye! Ami!

Nje o ti se ipinu fun Kristi nitoripe ohun ti o ti ka ninu oju ewe yi. To ba jebe, jowo te “Mo ti gba Kristi ni oni” ni abe.EnglishPada si oju ewe Yorùbá

Kínni Jésù ńgbàlà túmọ̀ sí?
Pin oju-iwe yii: Facebook icon Twitter icon Pinterest icon Email icon
© Copyright Got Questions Ministries