settings icon
share icon
Ibeere

Nje Bibeli je oro Olorun ni toto?

Idahun


Idahun fun ibere wa ko ni je bi a se le mo nipa iwe mimo ati bi o se se pataki si igbesi aye wa, sugbon yi o si ni ikoni fun iye ainipekun lori wa. Nje ti Bibeli ba je oro Olorun ni toto, a ni lati gbagbo, ko ni pa re, tele ofin re, ki a si ni ireti ninu re. Ti Bibeli ba je oro Olorun, ti a ko ba gbagbo, a ko gba olorun gbo naa ni yen.

Fun wipe Olorun fun wa ni iwe mimo re fihan wipe o fi ife re han si wa wipe Oluwa ba awon omo enia soro bi o se je ati bi a se le gbe igbesi aye wa po pelu re. Ohun eyi je awon ohun ti a ko le mon ti Oluwa ko ba fi han wa ninu iwe Bibeli. Sugbon Oluwa fi ara re han ninu Bibeli di e di e fun odun die, gbogbo ohun ti omo enia ni lati mo nipa Olorun lati le gbe igbesi aye dardara wa ni be. Nje ti Bibeli yi ba je oro Olorun, eyi je ohun gbogbo fun igbagbo, esin imule, ati Ibere ti a ni lati bere ni wipe, ba wo ni a se le mo n wipe, Bibeli je oro Olorun lai se iwe lasan? Ba wo ni Bibeli se yato patapata si awon iwe esin miran? Nje ohun kan wa ti a ni lati le fi mon wipe Bibeli wa lati odo Olorun? Eyi je awon ohun pataki ti ani lati wo ti a be fe mo n nipa Bibeli wipe o wa lati odo Olorun, lati orun wa, ti o si je gbogbo iranlowo fun igbagbo ati ise.

A ko le ni ohun igbagbo miran wipe Bibeli ko wa lati odo Olorun. Eyi so fun wa yekeyeke ni 2 timoteu 3:15-17, wipe, “……..lati igba omode ni iwo ti mo iwe-mimo, ti o le so di ologbon si igbala nipase igbagbo ninu Kristi Jesu. Gbogbo iwe-mimo ti o ni imisi Olorun li o si ni ere fun eko, fun ibani-wi, fun itoni, fun ikoni ti o wa ninu ododo: ki enia Olorun ki o le pe, ti a ti mura sile patapata fun ise rere gbogbo.

Ki a le dahun ibere yi, a ni lati wo inu ati ita lati fi le mo wipe Bibeli je oro Olorun ni toto. Ti inu ni wipe, a ni lati mo ohun ti Bibeli so nipa ibere. Ikan lara ohun ti Bibeli fi je oro Olorun ni okan. Sugbon bi iwe na se je orisirisi iwe, ni orile ede meta, ni ede meta, fun odun die, pelu ogoji akowe ni o ko, (won si je awon enia ise orisirisi), Bibeli je iwe-mimo ti a ko le jiyan re lati ibere de opin ti ko si mu wa sina. Ipapo yi je ohun iyato si awon iwe miran, eyi si je ibere oro, bi Oluwa se gbe awon enia dide fun ise re ti won si ko sile ninu oro re.

Eyi ohun inu miran ti a fi le fi mon wipe Bibeli je otito oro Olorun ni a o ri ninu iwe awon woli. Bibeli ni ogorun ohun ti yio sele si orile ede pelu isreali, pelu ohun ojo iwaju awon ohun ti yio sele si orile ede miran, ola omo enia, ati ipadawa messiah, olugbala wa ati ti isreali, sugbon gbogbo awon bi o ba gbagbo ninu re. ko da bi awon oro woli ti o wa ninu iwe esin miran tabi eyi ti Nostradamusi so, oro awon woli ti Bibeli ko ye. Bi awon oro woli ni a so nipa Jesu Kristi ninu Majemu lailai nikan. A so ni pa ibi ti a o bi si, awon obi re, ati papa, iku re ati ajinde ni ojo keta. Ko si ona miran ti a fi le oro woli naa han ninu Bibeli bi kose nipa ise Oluwa. Ko si iwe esin miran tabi nipa oro woli bi kose eyi ti Bibeli wi.

Ona inu keta fun ibere Bibeli ni a o ri nipa ase ati agbara. Nitori pe eyi je iteleyin ju awon meji ti a so ro nipa, ki se nipa agbara mimo ibere Bibeli. Bibeli ni ase gidi yato si awon iwe miran ti awon elomiran ti ko. Ase ati agbara yi ti fi han bi opolopo igbese aye awon enia se yipada ni kika Bibeli naa. Awon ologun oloro yipada, awon oni se ku se di atunbi, awon ti ko ni ile tabi awon ole naa si ti yipada, awon o ni jamba si di eni gidi, elese di oni ronu, awon to korin ra si ni ife ara won nigba ti won ka iwe naa. Bebeli ni agbara ati ase nitoripe otito oro Olorun ni.

Yato si inu otito Bibeli wipe otito oro Olorun ni, ohun ti a le ri ni ayika wa naa wa nibe ti a fi le mo wipe Bibeli ni oro Olorun. Ikan ninu re ni Ibere Bibeli. Nitoripe Bibeli soro nipa otito ati igba ti awon ohun sele, o je gege bi iwe a ko si le. Sugbon awon ohun ti won ri tabi iwe ako si le, je ki a mo wipe gbogbo ohun ti o sele ninu Bibeli lati igba si igba je otito. Nitori naa, awon ohun ti won ri tabi iwe ako sile fun Bibeli je iwe iko sile lati ibere aye. Nitori pe Bibeli ko nipa ohun ti o sele, ti o si fihan wipe otito ni, nipa esin, ko je ka jiyan re naa wipe oro Olorun ni.

Yato si eyi ti a ti so, ohun miran ti o le fi han wa ninu Bibeli nipa otito oro Olorun naa ni bi awon to ko se fi igbagbo sinu re. Bi ati so tele, Oluwa ma n lo awa omo eniyan ni bi kibi lati le ko oro re. Ti a ba wo igbesi awon enia yi, ko si ohun daradara kan lati gbagbo pe won ki se oloto enia. Ti a ba wo aye won, ti won si je eniti won setan lati ku (iku irora) fun ti won gbagbo, o ye wa wipe awon enia yi gbagbo wipe Oluwa ba won soro. Awon ti o ko iwe majemu ati ogorun awon onigbagbo (1 Korinti 15;6) mo otito iroyin naa. Nitoripe won ti ri won si ti wa pelu Jesu Kristi leyin ajinde iku re. Nitoripe won ri won si gbagbo gidi. Lati inu ibi ti won n beru, won si setan lati ku fun oro Olorun ti o fi han won. Igbesi aye won fi han wa wipe Bibeli ni otito oro Olorun.

Ni ipapo, eyi ti a ma fi mo wipe Bibeli ni otito oro Olorun ni aibaje oro Bibeli. Nitori pataki oro naa ati bi oro Olorun se je, orisirisi ohun ibaje ni won ti se si Bibeli ju iwe miran ni ile aye yi. Lati igba aye awon ara oba Romu Diocletiani, awon oba buburu titi di ile aye awon ti ko gbagbo, Bibeli si ti duro gidi o si yo ju gbogbo awon ti ko feran re nitori pe iwe naa ni o po ju ti a le ni gbogbo agbeye titi doni.

Lati ayedaye, awon alaigbagbo wipe Bibeli ko je gidi, sugbon awon enia miran ti fi han. Awon alaigbagbo so wipe, iwe naa ko je otito wipe ko ba ile aye yi mu, sugbon oro re, ati otito re ti fi ona fun awa omo enia nipa iwa wa, nipa igbesi aye wa. Awon orisirisi enia ni won ti so wipe otito ko si ni iwe naa sugbon titi di oni, oro naa ko si ye lati igba ti Oluwa si ti fi le le. Iwe naa si ti yi opolopo igbesi aye pada fun. ko si bi awon eni buburu naa se le fe yi pada, Bibeli ni agbara otito ni lati igbati awon omo enia ti fe yipada. Gbogbo ohun ti awon ota ti n se lati ibere ki won le je ki Bibeli ma mule, fi han wipe Bibeli ni oro Olorun. Ko ye ki o je iyalenu wipe ti won ba yi Bibeli naa, ko le yipada, be naa ni ko si ohun ti o le se. Fun eyi, Jesu wipe, “orun on aiye yio rekoja; sugbon oro mi ki yio rekoja” (Marku 13;13). Leyin igba ti a ti wo gbogbo re, eyi fi han si wa wipe, “Nitoto bibeli ni oro Olorun.”

EnglishPada si oju ewe Yorùbá

Nje Bibeli je oro Olorun ni toto?
Pin oju-iwe yii: Facebook icon Twitter icon Pinterest icon Email icon
© Copyright Got Questions Ministries