settings icon
share icon
Ibeere

Kínni Bíbélì sọ nípa wípé kí Kristiẹni máa lo ìfètò sọ́mọ bíbí? Ṣé ó tọ̀nà rárá láti máa lo ìfètò sọ́mọ bíbí?

Idahun


Ọlọ́run paá láṣẹ fún ènìyàn láti "máa bí síi, kí wọ́n sì máa rẹ̀ si" (Jẹnẹsisi 1:28). Ọlọ́run gbé ìgbéyàwó kalẹ̀ gẹ̀gẹ̀ bí àyíká tí ó fẹsẹ́ múlẹ́ láti máa bí àwọn ọmọ àti láti máa tọ́ wọn. Ó ṣeni láàánú wípé, lónìí a rí ọmọ nígbà míìrán gẹ́gẹ́ bí ìyọnu àti ìnira. Wọ́n ńdènà iṣẹ́ àyò àwọn ènìyàn àtí ìlépa ètò ìṣúná, wọ́n sì "rún àṣà wa" l'áwùjọ. Lọ́pọ̀ ìgbà, irú ìmọtaraẹni nìkan báyìí ni gbòǹgbò ògùn ìdènà oyún.

Lòdì sí ìmọtaraẹni nìkan tí ó wà lẹ́yìn lílo ìfètò sọ́mọ bíbí, Bíbélì pe ọmọ ní ẹ̀bùn láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run (Jẹnẹsisi 4:1, Jẹnẹsisi 33:5). Àwọn ọmọ ni ìní Olúwa (Orin Dafidi 127:3-5). Àwọn ọmọ jẹ́ ìbùkún láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run (Luku 1:42). Àwọn ọmọ ni adé arúgbó (Òwe 17:6). Ọlọ́run bùkún àwọn àgàn obìnrin pẹ̀lú àwọn ọmọ (Orin Dafidi 113:9; Jẹnẹsisi 21:1-3; 25:21-22; 30:1-2, 1 Samuẹli 1:6-8; Luku 1:7, 24-25). Ọlọ́run dá àwọn ọmọ nínú ìyá wọn (Orin Dafidi 139:13-16). Ọlọ́run mọ àwọn ọmọ kí wọ́n tó bí wọn (Jẹrimiah 1:5; Galatia 1:15).

Èyi tí ó súnmọ́ Ìwé Mímọ́ jùlọ tí ó lòdì sí ìfètò sọ́mọ bíbí ni ó wà nínú ìwe Jẹnẹsisi 38, nípa àkọsílẹ̀ àwọn ọmọkùnrin Júdà, Ẹ́rì àti Ọ́nánì. Ẹ́rì fẹ́ obìnrin kan tí à ńpé ni Támárì, ṣùgbọ́n ó ṣe ènìyàn búburú, Olúwa sì paá, tí ó sì fi Támárì sílẹ̀ láì lọ́kọ tàbí ọmọ. Wọ́n fa Támárì ní ìgbeyàwó fún arákùnrin Ẹ́rì, tíí ṣe Ọ́nánì, ní ìbámu pẹ̀lú òfin ìgbeyàwó ìṣúpó tí ó wà nínú Deutarọnọmi 25:5-6. Ọ́nánì kò fẹ́ pín ogún rẹ̀ pẹ̀lú ọmọ kankan tí yóo bí sí ipò arákùnrin rẹ̀, nítorí nà, ó ṣe ìfètò sọ́mọ bíbí tí ó pẹ́ jù, tíí ṣe fífàáyọ. Ìwe Jẹnẹsisi 38:10 sọ wípé, "ohun tí ó ṣe burú lójú Olúwa, nítorí nà ni Olúwa pa á pẹ̀lú." Èròǹgbà Ọ́nánì jẹ̀ ti ìmọtaraẹni nìkan: ó lo Támárì fún ìgbádùn ara rẹ̀, ṣùgbọ́n kò fẹ́ ṣe ojúṣe rẹ̀ tí ó tọ̀nà nípa fífi irù-ọmọ fún arákùnrin rẹ̀ tí ó kú. Àyọkà yìí ni a máa ńlò ní ọ̀pọ̀ ìgbà bí ẹ̀rí wípé Ọlọ́run kò fọwọ́ sí ìfètò sọ́mọ bíbí. Ṣùgbọ́n, kìí ṣe ìdènà oyún níní ni ó jẹ́ kí Olúwa pa Ọ́nánì, bíkòṣe ìwà ìmọtaraẹni nìkan tí ó wà lẹ́yìn ìṣe rẹ̀.

Ó ṣe pàtàkì láti máa wo àwọn ọmọ gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run ṣe rí wọn, kìí ṣe bí ayé ti sọ wípé a gbọ́dọ̀ rí wọn. Nígbà tí a ti sọ bẹ́ẹ̀, kò túmọ̀ sí wípé, Bíbélì kò gba ìdènà oyún níní láyè. Ìtumọ̀ ìdènà oyún níní, jẹ́ ìdàkejì níní oyún lásán. Kìí ṣe ìṣe ìdènà oyún níní tìkalára rẹ̀ ni ó ńsọ bóyá ó tọ̀nà tàbí kò tọ̀nà. Bí a ti kọ́ lára Ónánì, èrò ọkàn tí ó wà lẹ́hìn ìdènà oyún níní ni yóò sọ bóyá ó tọ́ tàbí kò tọ́. Kò tọ́ tí àwọn tọkọtayà bá ń lo ìdènà oyún níní láti ní ọ̀pọ̀ ìgbádùn fún ara wọn. Bí tọkọtayà bá ńlo ìdènà oyún níní láti lè dá ọmọ dúró fún ìgbà díẹ̀ títí tí wọn yóò fi dàgbà, tí wọn yóò fi palẹ̀mọ́ dáradára nípa ètò iṣúná owó àti ẹ̀mí wọn, ó lè ṣe ìtẹ́wọ́gbà láti lo ìdènà oyún níní. Lẹ́kàn síi, gbogbo rẹ̀ dálé lórí èròǹgbà ọkàn.

Bíbélì máa ńpe àwọn ọmọ ní ohun dídára nígbà gbogbo. Bíbélì ní "ìrètí" wípé ọkọ àti ìyàwó yóò ní àwọn ọmọ. Àìlè bí ọmọ jẹ́ ohun búburú nínú Ìwé Mímọ́. Kò sí ẹnikẹ́ni nínú Bíbélì ti kò fẹ́ láti bímọ. Nígbà kan náà, a kò lè jiyàn láti inú Ìwé Mímọ́ wípé kò dára láti lo ìfètò sọ́mọ bíbí fún àkókò díẹ̀. Gbogbo àwọn tọkọtayà gbọ́dọ̀ wá ìfẹ́ Olúwa nípa ìgbà tí wọ́n gbọ́dọ̀ gbìyànjú láti bí ọmọ àti iye ọmọ tí wọ́n yóò wá láti bí.

English



Pada si oju ewe Yorùbá

Kínni Bíbélì sọ nípa wípé kí Kristiẹni máa lo ìfètò sọ́mọ bíbí? Ṣé ó tọ̀nà rárá láti máa lo ìfètò sọ́mọ bíbí?
Pin oju-iwe yii: Facebook icon Twitter icon Pinterest icon Email icon
© Copyright Got Questions Ministries