settings icon
share icon
Ibeere

Kini ebun ede miran soro? Nje ebun ede yi wa fun wa lode oni? Kini adura ede miran soro?

Idahun


Eyi akoko tie de miran soro sele ni ojo Pentikosti ninu Ise Awon Aposteli 2;1-4. Awon Aposteli si lo si ita lati kede iroyin ayo pelu awon enia ni ede won, ‘awa gbo nwon nsoro ise iyanu nla Olorun lie de wa!” (Ise Awon Aposteli 2:11). Oro naa ni Greki tumo si ‘ahan’ ti o je “ede.” Nitori naa ebun ahan je ede ti Olorun ti fun wa lati ba enia ti ko mo ede naa soro ni ede ti eni naa ko mon. Ni 1 Korinti ori 12-14, nibi ti Paulu soro lori ebu orisirisi, o wipe, “ Nisiyi, eyin ara mi, tie mi ba si odo yi pelu ede aimo, ere kili emi o je fun nyin, bikosepe mo ba mba nyin soro, yala nipa isipaya, tabi nipa imo, tabi nipa isotele, tabieko?” (1 Korinti 14:6). Bi Aposteli Paulu ti wi, pelu bi a ti se so ninu Ise Awon Aposteli, ede yi je ohun ti o dara fun eni ti o n gbo oro Olorun ni ede tire, sugbon ko wulo fun awon elomiran-yala tabi ti a ba tumo re.

Eni ti o ni ebun lati tumo (1 Korinti 12:30) ma mo itumo ohun ti eni naa n so, sugbon o le ma mon iru ede ti eni naa n so. Eni ti o n tumo re yio si so itumo re naa fun gbogbo ijo nkan ti Oluwa n so. “Fun idi eyi,eniti o ba fie de miran soro, ki o gba adura lati tumo re.”(1 Korinti 14:13). Ohun ti Paulu so nipa ede ti a letumo ni agbara, “sugbon mo fe kin g kuku fi oye mi so oro marun ni ijo, ki ng le ko awon elomiran pelu, ju egbarun oro lie de aimo” ( 1 korinti 14:19).

Nje ebun ede wa fun wa lode oni? 1 Korinti 13:8 wipe ebun ede ti ko si, sugbon o tun daruko ohun ti o “dara ju” eyi lo ni 1 Korinti 13:10. Awon kan fi han nipa iyato si ede isotele tabi “oye ti ko si mo” gege bi ede ahan ti ko si ki “eyi ti o dara” to de. Eyi ko ti ye wa daradara. Awon kan tun fi Isaiah 28:11 han ati Joeli 2:28-29 wipe ede je ohun ti Oluwa fun wa gege bi idajo Re. 1 Korinti 14:22 fihan wipe eyi je “ami fun awon alaigbagbo.” Gege bi oro yi, ebun ede yi je ikilo fun awon idajo ara Ireali nitoripe won ko Jesu Kristi ti Olugbala. Nitori naa, nigbati Olorun si dajo won (iparun Jerusalemu lati owo awon ara Romu leyin iku ), ebun ede ko si ni wulo mo. Ti eyi ba si je be, ohun ti ede naa wa fun ko si ni je be mon. Iwe mimo ko so fun wa wipe ebun ede ko si mon.

Ti ebun ede yi ba wa ni ijo loni, a ni lati se gege bi Bibeli se so. Yio si je gidi ati oye ni ona ti a fi se (1 Korinti 14:10). O ni lati je ona ti a o fib a Olorun soro pelu edemiran (Ise Awon Aposteli 2:6-12). Yio si je bi ase ti Olorun fun wa lati owo Aposteli Paulu, “Bi enikni ba fi ede fo, ki o je enia meji, tabi bi o potan, ki o je meta, ati eyini li okokan; si je ki enikeni gbufo. Sugbon bi ko ba si ogbufo, ki o pa enu re mo ninu ijo; si je ki o ma ba ara re ati Oluwa soro” (1 korinti 14:27-28). Yi o si je iteriba ni 1 Korinti 14:33, “Nitoripe Olorun ki ise Olorun ohun rudurudu, sugbon ti alafia, gege bi o ti je ninu gbogbo ijo enia mimo.”

Olorun lefun enia ni ebun ede lati eni na soro ni ede miran. Emi Mimo naa ni on fun enia ni orisirisi ebun (1 Korinti 12:11). Ti a ba si wo bi ise Olorun se le gboro to ti a ko ba lo si ile eko, ki a si le baa won enia soro ni ede won. Sugbon Olorun ko se eyi. Ede siso ni igba Majemu Titun ko si mo loni bi o ti le je wipe iwulo re dara gan. Awon onigbagbo ode oni ti won nipe won huwa lati ma so ede, won kotele bi Bibeli ti ni ka se. Eyi fi han wipe ebun ede ko si mon tabi ko si ninu ohun ti Oluwa fe ka ma se ni ijo toni.

Awon ti o gbagbo ninu ebun ede fun “ede adura” fun ifese ara mule, mon nipa re ni 1 Korinti 14:4 tabi 14:28, “ Eniti nsoro li ede aimo nfi ese ara re mule; sugbon eniti nsotele nfi ese ijo mule.” Ni ori 14, Paulu soro nipa itumo ede, wo 14:5-12. Ohun ti Paulu n so ni ese kerin niwipe, “Ti iwo ba fi ede fo lai ni tumo re, ko si ohun ti o n se afi pe o n fie se ara re mule, o fi han wipe iwo ni emi Olorun ju elomiran. Ti o ba fi ede fo ti won si tumo re, iwo si ti fie se won mule. Majemu Titun o si dauko nipa wipe ki a fi “ede gba adura.” Won ko so ninu iwe Mimo naa. Nje ti ede naa ba je wipe ki a fi ara wa mule, se o si dara ki awon kan ma le fi ara won naa mule? 1 Korinti 12:29-30 wipe ki se gbogbo enia ni o ni ebun lati so ede miran.

English



Pada si oju ewe Yorùbá

Kini ebun ede miran soro? Nje ebun ede yi wa fun wa lode oni? Kini adura ede miran soro?
Pin oju-iwe yii: Facebook icon Twitter icon Pinterest icon Email icon
© Copyright Got Questions Ministries